Múra Ìgbékalẹ̀ Tìrẹ fún Ìfilọni Ìwé Ìròyìn
1 A mọrírì ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọn tí ó bá àkókò mu, tí ó sì kún fún ẹ̀kọ́, tí ń kárí àwọn kókó ẹ̀kọ́ láti orí ọ̀ràn inú ayé sí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọr. 2:10) Gbogbo wa ni ó rántí ọ̀pọ̀ ohun tuntun, tí ń gbéni ró, tí a ti kà nínú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí, tí Jèhófà ń lò láti ṣí òtítọ́ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. (Òwe 4:18) A fẹ́ hára gàgà láti ṣèpínkiri wọn kálẹ̀ dé ibi tí a bá lè dé.
2 Ṣàyẹ̀wò Ìpínlẹ̀ Rẹ Fínnífínní: Irú àwọn ènìyàn wo ní ń gbé ní agbègbè rẹ? Bí wọ́n bá jẹ́ àwọn ẹni tí ojú máa ń kán ní gbogbo ìgbà, ó lè ṣe pàtàkì pé kí o múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ṣe ṣókí, tí ó sì ṣe tààràtà sílẹ̀. Bí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ kì í báá ṣe àwọn ènìyàn tí ojú máa ń kán, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti mú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ gùn díẹ̀ sí i. Bí ó bá jẹ́ iṣẹ́ àárọ̀ ni èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn onílé máa ń ṣe, o lè túbọ̀ ṣàṣeyọrí bí o bá bẹ̀ wọ́n wò ní ìrọ̀lẹ́. O lè kàn sí àwọn kan ní òwúrọ̀ nípa ṣíṣe ìjẹ́rìí òpópónà tàbí ṣíṣiṣẹ́ láti ìsọ̀ dé ìsọ̀. Àwọn akéde kan máa ń rí àbájáde rere nípa títọ àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibùdókọ̀ àti ilé epo lọ.
3 Mọ Àwọn Ìwé Ìròyìn Náà Dáradára: Ka ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan gbàrà tí ó bá ti tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́. Yan àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o ronú pé yóò fa àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ mọ́ra. Àwọn kókó ẹ̀kọ́ wo ni ó kàn wọ́n? Wá kókó kan tí o lè fà yọ láti inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o wéwèé láti lò. Ronú ìbéèrè kan tí o lè gbé dìde láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè. Yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá àkókò mu, tí ìwọ yóò kà fún onílé, tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀. Ronú bí o ṣe máa fi ìpìlẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò lélẹ̀.
4 Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Sílẹ̀: Fara balẹ̀ yan àwọn ọ̀rọ̀ tí o wéwèé láti lò láti fi sọ ẹni tí o jẹ́, àti láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Àwọn kan ti ṣàṣeyọrí nínú lílo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí: “Mo ti ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó fani lọ́kàn mọ́ra nínú ìwé ìròyìn yìí, mo sì fẹ́ ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” Ọ̀pọ̀ ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn pẹ̀lú ìbéèrè tí ń darí ẹni sí kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí wọ́n wéwèé láti lò. Fún àpẹẹrẹ:
5 Bí o bá ń pe àfiyèsí sórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lórí ìtànkálẹ̀ ìwà ọ̀daràn, o lè béèrè pé:
◼ “Kí ni yóò gbà láti mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti sùn lóru, láìbẹ̀rù pé a óò jà wá lólè tàbí pa wá lára?” Ṣàlàyé pé o ní ìsọfúnni nípa ojútùú sí ìṣòro yìí. Ojútùú náà yóò tún mú onírúurú ìdàrúdàpọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kúrò, láìpẹ́. Tọ́ka sí ohun kan nínú ìwé ìròyìn náà, tí ó gbé irú ìrètí bẹ́ẹ̀ kalẹ̀, kí o sì rọ onítọ̀hún láti gba àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn náà, fún ọdún kan, ní iye tí a ń gbà á. Nígbà tí o bá padà lọ, o lè pé àfiyèsí onílé sí orí 1 ìwé Ìmọ̀.
6 Nígbà tí o bá ń fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ìdílé lọni, o lè sọ èyí:
◼ “Ọ̀pọ̀ òbí ń rí i pé ó jẹ́ ìpèníjà ńlá láti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà lónìí. Ọ̀pọ̀ ìwé ni a ti kọ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, ṣùgbọ́n, àwọn ògbógi pàápàá kò fohùn ṣọ̀kan. Ẹnikẹ́ni ha wà tí ó lè pèsè ìtọ́sọ́nà tí a lè gbára lé bí?” Ṣàjọpín àlàyé láti inú ìwé ìròyìn náà, tí ó fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí ń bẹ nínú Bíbélì hàn. Fi àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́. Bí kò bá gba àsansílẹ̀ owó náà, fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn lọ̀ ọ́, ní iye tí a ń fi síta. Nígbà tí o bá ṣe ìpadàbẹ̀wò, jíròrò àwọn èròǹgbà Ìwé Mímọ́ lórí bí a ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, tí a kárí nínú ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 145 sí 148.
7 Ní gbígbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà jáde, o lè sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ nítorí àwọn àkókò másùnmáwo tí à ń gbé nínú rẹ̀. O ha rò pé ọ̀nà tí Ọlọ́run pète pé kí a máa gbé nìyí bí?” Tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan, tí ó fi bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro òde òní hàn tàbí èyí tí ó fún wa ní ìdí láti wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú, tí yóò bọ́ lọ́wọ́ àníyàn. Lẹ́yìn náà, fi àsansílẹ̀ owó lórí ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́. Bí kò bá gba àsansílẹ̀ owó náà, fi àwọn ìwé ìròyìn lọ̀ ọ́ ní iye tí à ń fi síta. Nígbà ìbẹ̀wò rẹ tí ó tẹ̀ lé e, jíròrò àwòrán àti àkọlé àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 4 sí 5 ìwé Ìmọ̀, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ní tààràtà.
8 Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Onílé Mu: Ìwọ yóò ṣalábàápàdé àwọn ènìyàn tí ó ní ìdàníyàn àti ìpìlẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o lè mú bá onílé kọ̀ọ̀kan mu sílẹ̀. Múra sílẹ̀ láti mú ọ̀rọ̀ rẹ bá ọkùnrin, obìnrin, àgbàlagbà, tàbí èwe mu. A kò kàn án nípá fún ọ láti sọ ohun kan. Lo ohunkóhun tí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, tí ó sì ń méso wá. Bí ó ti wù kí ó rí, jẹ́ onítara, sọ̀rọ̀ láti ọkàn wá, kí o sì jẹ́ ẹni tí ń fetí sílẹ̀ dáradára. Àwọn tí wọ́n ní “ìtẹ̀sí ọkàn títọ́” yóò rí òtítọ́ inú rẹ, wọn yóò sì dáhùn padà lọ́nà rere.—Ìṣe 13:48.
9 Ẹ Ran Ara Yín Lọ́wọ́: Nípa ṣíṣàjọpín èrò, a ń kọ́ àwọn ọ̀nà tuntun láti ṣàlàyé ara wa. Ṣíṣèdánrawò ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa pa pọ̀, ń fún wa nírìírí àti ìgboyà. (Òwe 27:17) Bí o bá ṣèdánrawò ohun tí ìwọ yóò sọ, ọkàn rẹ yóò túbọ̀ balẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí lo àkókò láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀, kí wọ́n fetí sílẹ̀ bí àwọn ọmọ wọ́n ṣe ń ṣe ìdánrawò ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe dáradára sí i fún wọn. Àwọn ẹni tuntun lè jàǹfààní nípa bíbá àwọn akéde onírìírí ṣiṣẹ́.
10 Kò yẹ kí mímúra ìgbékalẹ̀ tìrẹ fún ìfilọni ìwé ìròyìn nira fún ọ. Ohun tí ó béèrè kò ju níní ohun kan pàtó lọ́kàn láti sọ, kí o sì sọ ọ́ ní ọ̀nà tí ń fani lọ́kàn mọ́ra. Pẹ̀lú àtinúdá àti ìrònúṣáájú, o lè ronú kan ìgbékalẹ̀ àtàtà kan tí yóò mú àbájáde tí ó dára wá.
11 Pípín ìwé ìròyìn kiri jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tí a gbà ń tan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba kálẹ̀ kárí ayé. Bí o bá lè jẹ́ kí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tẹ àwọn ènìyàn olótìítọ́ inú lọ́wọ́, àwọn ìwé ìròyìn náà lè fúnra wọn sọ̀rọ̀. Máa rántí ìníyelórí wọn àti bí ìhìn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú wọ́n ṣe lè gba ẹ̀mí là. Irú “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn” bí èyí, ń dùn mọ́ Jèhófà nínú jọjọ.—Heb. 13:16.