Ìwọ Ha Ń Fi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Bí?
1 Jésù Kristi ni olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí. Ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kan tí ó wọ àwọn ènìyàn lọ́kàn ṣinṣin, tí ó ru wọ́n lọ́kàn sókè, tí ó sì sún wọn láti ṣe iṣẹ́ rere. (Mat. 7:28, 29) Gbogbo ìgbà ni ó máa ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Luk. 24:44, 45) Jèhófà Ọlọ́run ni ó darí ìyìn sí fún gbogbo ohun tí ó mọ̀, tí ó sì ṣeé ṣe fún un láti fi kọ́ni. (Joh. 7:16) Jésù fi àpẹẹrẹ pípegedé lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa fífi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Tim. 2:15.
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá nípa fífi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà gbígbéṣẹ́. Ó ṣe ju kíka Ìwé Mímọ́ fún àwọn ẹlòmíràn lọ; ó ṣàlàyé, ó sì fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí ohun tí ó kà, ní gbígbé ẹ̀rí ìdánilójú kalẹ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé Jèsú ni Kristi náà. (Ìṣe 17:2-4) Bákan náà, ọmọ ẹ̀yìn náà, Àpólò, tí ó lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ, jẹ́ “ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́,” ó sì fi ọwọ́ títọ̀nà mú wọn, ní gbígbé òtítọ́ kalẹ̀ lọ́nà lílágbára.—Ìṣe 18:24, 28.
3 Jẹ́ Olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Àwọn olùpòkìkí Ìjọba lónìí ti gbádùn àṣeyọrí títayọ lọ́lá ní kíkọ́ àwọn aláìlábòsí ọkàn, nípa títọ́ka sí Bíbélì àti fífọ̀rọ̀ wérọ̀ láti inú rẹ̀. Nínú ọ̀ràn kan, ó ṣeé ṣe fún arákùnrin kan láti lo Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4 àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó fara jọ ọ́, láti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn olódodo. Nítorí èyí, àwọn kan lára àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ọ̀kan nínú wọ́n sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nínú ọ̀ràn míràn, a sọ fún arábìnrin kan láti sọ ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ṣayẹyẹ Kérésìmesì àti ọjọ́ ìbí, fún ọkọ obìnrin olùfìfẹ́hàn kan, tí ń ṣàtakò. Bí arábìnrin náà ti ń ka ìdáhùn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu jáde ní tààràtà láti inú ìwé Reasoning, ọkùnrin náà fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Inú ìyàwó rẹ̀ dùn jọjọ sí títẹ́wọ́ tí ó tẹ́wọ́ gba àwọn ìdáhùn náà, débi pé, ó sọ pé: “A ń bọ̀ ní àwọn ìpàdé yín.” Ọkọ rẹ̀ sì fohùn ṣọ̀kan!
4 Lo Àwọn Ìrànwọ́ Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ń pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà àtàtà láti ràn wá lọ́wọ́ ní fífi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ akéde ti sọ ìmọrírì wọn jáde fún onírúurú ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn, tí a tẹ̀ jáde, tí a sì ṣàṣefihàn wọn fún àǹfààní wa, tí ẹ̀rí sì fi hàn pé wọ́n bá àkókò mu, wọ́n sì gbéṣẹ́. Reasoning From the Scriptures kún fún onírúurú èrò lórí bí a ṣe lè ṣàlàyé àwọn kókó ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó lé ní 70, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lé lórí, lọ́nà títọ̀nà. Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pèsè àkópọ̀ ṣókí lórí gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì, tí ó yẹ kí àwọn ẹni tuntun lóye. Ìkẹ́kọ̀ọ́ 24 àti 25 inú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun, fi bí àwọn olùkọ́ jíjáfáfá ṣe ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́, bí wọ́n ṣe ń kà á, àti bí wọ́n ṣe ń so ó mọ́ ọ̀rọ̀ wọn, lọ́nà yíyẹ hàn wá. Ó yẹ kí a lo gbogbo àrànṣe yìí, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, dáradára.
5 Nígbà tí a bá fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò rí i pé, ó “wà láàyè ó sì ń sa agbára . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà” àwọn tí a ń wàásù fún. (Heb. 4:12) Àṣeyọrí tí a ń gbádùn ní lílò ó, yóò sún wa láti fi àìṣojo sọ òtítọ́ ju ti ìgbàkigbà rí lọ!—Ìṣe 4:31.