A Ní Iṣẹ́ Àṣẹ Kan
1 Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mat. 28:19) Ní 232 ilẹ̀ àti àgbájọ erékùṣù káàkiri ayé, àwọn olùyin Jèhófà Ọlọ́run, tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún, ń pèsè ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro sí ìmúṣẹ àṣẹ Jésù. Ṣùgbọ́n, àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? A ha ń fọwọ́ pàtàkì mú àṣẹ tí a fún wa láti wàásù?
2 Ojúṣe Ní Ti Ìwà Rere: Iṣẹ́ àṣẹ jẹ́ “àṣẹ kan láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fúnni.” Kristi pàṣẹ fún wa láti wàásù. (Ìṣe 10:42) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé, èyí gbé àìgbọdọ̀máṣe kan, tàbí ojúṣe kan ní ti ìwà rere, ka òun lórí, láti polongo ìhìn rere. (1 Kọr. 9:16) Láti ṣàpèjúwe: Ronú ná, pé o jẹ́ òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rì. Ọ̀gákọ̀ pàṣẹ fún ọ láti kìlọ̀ fún àwọn èrò inú ọkọ̀, kí o sì darí wọn sínú ọkọ̀ ìgbàlà. Ìwọ yóò ha gbójú fo àṣẹ yẹn, kí o sì pọkàn pọ̀ sórí gbígba ẹ̀mí ara rẹ nìkan là bí? Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn sinmi lórí ìgbésẹ̀ tí o bá gbé. Ẹ̀mí wọn ń bẹ nínú ewu. Ojúṣe rẹ ní ti ìwà rere mú kí ó pọn dandan fún ọ láti mú iṣẹ́ àṣẹ rẹ, ti ríran wọ́n lọ́wọ́ ṣẹ.
3 A ti pàṣẹ fún wa látọ̀runwá láti ṣèkìlọ̀. Jèhófà yóò mú òpin dé bá gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí, láìpẹ́. Ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn wà nínú ewu. Yóò ha tọ̀nà fún wa láti gbójú fo ewu tí ń bọ̀ lórí àwọn ẹlòmíràn, kí ó sì jẹ́ gbígba ẹ̀mí ara wa là nìkan ni yóò jẹ wá lógún? Kò ní tọ̀nà rárá. Ojúṣe wa ní ti ìwà rere mú kí ó pọn dandan fún wa láti ṣèrànwọ́ láti gba ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn là.—1 Tim. 4:16.
4 Àwọn Àpẹẹrẹ Àtàtà Láti Tẹ̀ Lé: Wòlíì Ìsíkẹ́ẹ̀lì nímọ̀lára pé òún jẹ gbèsè pípolongo ìhìn iṣẹ́ oníkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòtítọ́. Jèhófà kìlọ̀ fún un láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀, nípa àbájáde tí yóò tìdí rẹ̀ wá, bí ó bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ tí a yàn fún un: “Nígbà tí èmi wí fún ènìyàn búburú pé, Ìwọ yóò kú ní tòótọ́; tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún un . . . , ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò bèrè ní ọwọ́ rẹ.” (Isk. 3:18) Ìsíkẹ́ẹ̀lì fi pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ṣe iṣẹ́ àṣẹ rẹ̀, àní lójú àtakò líle pàápàá. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe fún un láti yọ̀, nígbà tí a mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ.
5 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti wàásù. Ó polongo pé: “Ọrùn mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo, nítorí pé èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ gbogbo ìmọ̀ràn Ọlọ́run fún yín.” Pọ́ọ̀lù wàásù ní gbangba àti láti ilé dé ilé, nítorí ó mọ̀ pé, kíkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí òún jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ níwájú Ọlọ́run.—Ìṣe 20:20, 26, 27.
6 A ha ní ìtara bíi ti Ìsíkẹ́ẹ̀lì bí? A ha nímọ̀lára pé ó di dandan gbọ̀n fún wa láti wàásù, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe bí? Iṣẹ́ àṣẹ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn. A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ wa, láti kìlọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, láìka ìdágunlá, àìbìkítà, tàbí àtakò wọn sí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún sí i lè dáhùn padà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, kí wọ́n sì polongo pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwá ti gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.” (Sek. 8:23) Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa sún wa láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀. A ní iṣẹ́ àṣẹ láti wàásù!