Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 4
Orin 29
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ, fún oṣù July.
15 min: “Ìwọ Ha Ń Fi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé lórí “Reasons for considering the Bible” (Ìdí tí a ní fún gbígbé Bíbélì yẹ̀ wò), láti inú ìwé Reasoning, ojú ìwé 58 sí 60, kún un.
20 min: “Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 5) Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìpínrọ̀ 1, jẹ́ kí àwọn akéde dídángájíá méjì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìpínrọ̀ 2 sí 5. Tẹnu mọ́ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orin 128 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 11
Orin 40
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ ètò tí a ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀.
20 min: Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Jèhófà Ní Nǹkan? Ìjíròrò láàárín àwọn alàgbà méjì, tí ń tẹnu mọ́ kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1996, ojú ìwé 28 sí 31. Tàbí kí alàgbà kan gbé ìsọfúnni náà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àsọyé kan.
15 min: “Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 8) Jíròrò àǹfààní tí lílo ìyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní. Jẹ́ kí àwọn akéde onírìírí ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìpínrọ̀ 6 àti 7. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn àpẹẹrẹ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́. Nígbà tí a fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́ ní tààràtà, ọkùnrin kan fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ wọlé wá. Èmi yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́.” A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ìdílé rẹ̀ jókòó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, kò pẹ́ kò jìnnà tí gbogbo wọ́n fi ń lọ sí àwọn ìpàdé, tí wọ́n sì ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí. Rọ gbogbo àwùjọ láti mú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti June 1996, lọ́wọ́ wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tí ń bọ̀.
Orin 129 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 18
Orin 140
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “A Ní Iṣẹ́ Àṣẹ Kan.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ṣókí lórí Ilé Ìṣọ́nà, January 1, 1988, ojú ìwé 28 àti 29, ìpínrọ̀ 13 sí 16.
20 min: Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Tẹ̀ Síwájú. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. A ti ń lo ìwé Ìmọ̀ nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, fún nǹkan bí ọdún kan báyìí. Ó ṣeé ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ti parí rẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn sì ti lọ jìnnà nínú ìwé náà. A rọ̀ wá láti pọkàn pọ̀ sórí dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a pète láti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti tètè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí wọ́n lò ó nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì di ara ìjọ. Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti June 1996, pèsè ìdámọ̀ràn dídára láti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùkọ́ tí ó gbéṣẹ́. Ní ṣókí, ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí a lè ṣe láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà jíjáfáfá, gẹ́gẹ́ bí ìpínrọ̀ 3 sí 13 inú àkìbọnú náà ti kárí rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, pọkàn pọ̀ sórí ohun tí a ní láti ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìdúró rere, gẹ́gẹ́ bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú ìpínrọ̀ 14 sí 22. Ka ìpínrọ̀ 15, 17, 20 àti 21. Sọ àwọn ìròyìn díẹ̀ tí ń gbéni ró, tí ń fi bí àwọn akéde àdúgbò ti rí àbájáde dídára hàn. Rọ púpọ̀ sí i láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orin 85 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 25
Orin 46
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ.
18 min: “Polongo Ìhìn Rere Láìṣojo.” Kí á kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka àwọn ìpínrọ̀ tí àkókò gbà ọ́ láti kà.
12 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní December. Fi Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lọni. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, fi Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí lọni. Ní fífi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ lọni, ṣí i sí orí 35, lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Awọn Wo Ni Aláyọ̀ Nitootọ?” Fa òtítọ́ náà yọ pé, lónìí, gbogbo ènìyàn ní ń fẹ́ láti láyọ̀. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò fi láyọ̀? Kí ní ṣẹlẹ̀? Ní lílo èrò tí ń bẹ nínú orí yìí, fi hàn pé ayọ̀ tòótọ́ sinmi lórí (1) jíjẹ́ kí àìní ẹni nípa tẹ̀mí jẹni lọ́kàn, (2) jíjẹ́ onínú tútù àti ẹni tí ó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àti (3) gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì di olùṣe ọ̀rọ̀ náà. Tẹnu mọ́ ìrètí ọjọ́ ọ̀la aláàbò kan fún àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn ní tòótọ́. Ṣí i sí orí 133, kí o sì ka Lúùkù 23:43, ní fífi hàn pé, láìpẹ́, àwọn olódodo yóò gbé títí láé nínú párádísè kan tí a mú padà bọ̀ sípò. Gbé àṣefihàn kúkúrú kan kalẹ̀, ní lílo èrò tí a là sílẹ̀ níhìn-ín. Ṣe àdéhùn ṣíṣe gúnmọ́ fún ìpadàbẹ̀wò, níbi tí a bá ti fi ìfẹ́ hàn.
Orin 180 àti àdúrà ìparí.