ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/1 ojú ìwé 28-31
  • Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Jèhófà Ní Nǹkan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Jèhófà Ní Nǹkan?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apá Pàtàkì Nínú Ìjọsìn Tòótọ́
  • Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Un Ní Nǹkan
  • Ìbùkún Ń Wá Láti Inú Fífi Ẹ̀mí Fífúnni Hàn
  • Bí Àwọn kan Ṣe Ń Ṣe Ìtọrẹ Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Fi Àwọn Ohun Ìní Rẹ Tí Ó Níye Lórí Bọlá fún Jèhófà”—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Olùfúnni ní “Gbogbo Ẹ̀bùn Rere”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ibo Ni Owó Náà Ti Ń Wá?”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/1 ojú ìwé 28-31

Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Jèhófà Ní Nǹkan?

BÍ OÒRÙN ṣe ń ta yẹ́ẹ́ sórí ìlú kékeré àwọn ará Sídónì ti Sáréfátì, opó kan bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti ṣa igi jọ. Ó fẹ́ẹ́ dáná, kí ó baà lè gbọ́únjẹ kékeré—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ oúnjẹ àjẹkẹ́yìn tí òun àti ọmọdékùnrin rẹ̀ yóò jẹ. Ó ti làkàkà láti mú kí òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ wà láàyè la àkókò ọ̀dá àti ìyàn tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ kọjá, gbogbo rẹ̀ sì ti wá parí sí ipò tí ń bani nínú jẹ́ yìí. Ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa wọ́n kú.

Ọkùnrin kan tọ̀ wọ́n wá. Èlíjà ni orúkọ rẹ̀, kò sì pẹ́ tí opó náà fi mọ̀ pé wòlíì Jèhófà ni. Ó dà bí ẹni pé ó ti gbọ́ nípa Ọlọ́run yìí. Jèhófà yàtọ̀ sí Báálì, ẹni tí ìjọsìn rẹ̀ tí a gbé gbòdì, tí ó kún fún ìwà òǹrorò gbalé gbòde ní ilẹ̀ Sídónì. Nítorí náà, nígbà tí Èlíjà tọrọ omi mímu lọ́wọ́ rẹ̀, ó hára gàgà láti ṣèrànwọ́. Bóyá ó rò pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí òun rí ojú rere Jèhófà gbà. (Mátíù 10:41, 42) Ṣùgbọ́n Èlíjà tún tọrọ ohun mìíràn—oúnjẹ díẹ̀. Ó ṣàlàyé pé, kìkì ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó jẹ́ oúnjẹ àjẹkẹ́yìn ni òun ní. Síbẹ̀, Èlíjà tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ní mímú un dá a lójú pé, Jèhófà yóò pèsè oúnjẹ fún un lọ́nà ìyanu títí di ìgbà tí ọ̀dá náà yóò fi kọjá. Kí ni ó ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó sì lọ, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíjà.” (Àwọn Ọba Kìíní 17:10-15) Àwọn ọ̀rọ̀ kékeré wọ̀nyí ṣàpèjúwe ìṣe ìgbàgbọ́ ńláǹlà—ní tòótọ́, ó ga lọ́lá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jésù Kristi fi yin opó náà ní ohun tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà!—Lúùkù 4:25, 26.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó lè dà bí ohun tí ó ṣàjèjì pé, Jèhófà yóò béèrè ohun tí ó pọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ obìnrin kan tí ó tòṣì tó bẹ́ẹ̀. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì, nígbà tí a bá ronú lórí àdúrà tí ọkùnrin olókìkí kan gbà nígbà kan. Ọ̀nà tí Ọba Dáfídì gbà kó ọrẹ jọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sólómọ́nì láti lò ní kíkọ́ tẹ́ḿpìlì ru ìwà ọ̀làwọ́ ńláǹlà sókè. Bí a bá ní kí a sọ ọ́ lóde òní, ọrẹ tí a dá tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là! Ṣùgbọ́n, Dáfídì sọ nínú àdúrà sí Jèhófà pé: “Ta ni èmi, àti kí ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? nítorí ohun gbogbo ọ̀dọ̀ rẹ ni ti í wá, àti nínú ohun ọwọ́ rẹ ni àwa ti fi fún ọ.” (Kíróníkà Kìíní 29:14) Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti sọ, Jèhófà ni ó ni ohun gbogbo. Nítorí náà, nígbàkigbà tí a bá fún un ní ohun kan láti mú ìjọsìn mímọ́ gaara tẹ̀ síwájú, a wulẹ̀ ń fún Jèhófà ni ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni. (Orin Dáfídì 50:10) Nípa báyìí, ìbéèrè náà dìde pé, Èé ṣe gan-an tí Jèhófà fi fẹ́ kí a fún òun ní nǹkan?

Apá Pàtàkì Nínú Ìjọsìn Tòótọ́

Ìdáhùn tí ó rọrùn jù lọ ni pé, láti ìgbà ìjímìjí, Jèhófà ti mú kí fífún òun ní nǹkan jẹ́ apá pàtàkì ìjọsìn mímọ́ gaara. Ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà, Ébẹ́lì, fi díẹ̀ nínú àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ ṣíṣeyebíye rúbọ sí Jèhófà. Àwọn babańlá, Nóà, Ábúráhámù, Aísíìkì, Jékọ́bù, àti Jóòbù, rú irú ẹbọ bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:4; 8:20; 12:7; 26:25; 31:54; Jóòbù 1:5.

Òfin Mósè fàṣẹ sí fífún Jèhófà ní ọrẹ, ó sì darí bí a óò ṣe máa fún un pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, a pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti san ìdámẹ́wàá, tàbí láti dá ìdá kan nínú mẹ́wàá èso ilẹ̀ àti ìbísí nínú ohun ọ̀sìn wọn. (Númérì 18:25-28) A kò rin kinkin mọ́ dídarí àwọn ọrẹ yòó kù lọ́nà bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, a béèrè pé kí olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì fún Jèhófà ní àkọ́bí ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àkọ́so èso rẹ̀. (Ẹ́kísódù 22:29, 30; 23:19) Síbẹ̀, Òfin náà yọ̀ọ̀da fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti pinnu iye àkọ́so èso tí òun yóò fún un, kìkì kí ó ṣáà ti fún un ní èyí tí ó dára jù lọ. Òfin náà tún ṣètò fún ẹbọ ìdúpẹ́ àti ọrẹ ẹbọ, tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àtinúwá. (Léfítíkù 7:15, 16) Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìṣírí láti fún òun ní nǹkan bí òun bá ṣe bù kún wọn tó. (Diutarónómì 16:17) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà kíkọ́ àgọ́ àjọ àti lẹ́yìn náà nígbà kíkọ́ tẹ́ḿpìlì, olúkúlùkù fún un ní ohun tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un láti fún un. (Ẹ́kísódù 35:21; Kíróníkà Kìíní 29:9) Dájúdájú, irú ọrẹ àtinúwá bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí ó dùn mọ́ Jèhófà nínú jù lọ!

Lábẹ́ “òfin Kristi,” gbogbo ohun fífúnni gbọ́dọ̀ jẹ́ àtinúwá. (Gálátíà 6:2; Kọ́ríńtì Kejì 9:7) Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi dẹ́kun fífúnni tàbí pé kí wọ́n fúnni ní ohun tí kò tó nǹkan. Rárá o! Bí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe ń wàásù ní Ísírẹ́lì, àwùjọ àwọn obìnrin kan tẹ́ lè wọn, wọ́n sì ṣèránṣẹ́ fún wọn láti inú àwọn nǹkan ìní wọn. (Lúùkù 8:1-3) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ẹ̀bùn gbà tí ó ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀, òun náà sì fún àwọn ìjọ níṣìírí láti fún àwọn ẹlòmíràn ní owó, tí àìní bá yọjú. (Kọ́ríńtì Kejì 8:14; Fílípì 1:3-5) Ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù yan àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti rí i dájú pé, a pín àwọn ohun èèlò tí a dá fún àwọn aláìní. (Ìṣe 6:2-4) Ó ṣe kedere pé, àwọn Kristẹni ìjímìjí rí ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́ gaara lọ́nà yìí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan.

Síbẹ̀síbẹ̀, a lè ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Jèhófà tilẹ̀ fi mú kí fífún òun ní nǹkan jẹ́ apá kan ìjọsìn rẹ̀. Gbé ìdí mẹ́rin yẹ̀ wò.

Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Un Ní Nǹkan

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà mú kí fífún òun ní nǹkan jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́ nítorí pé, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ dára fún wa. Ó fi hàn pé a mọrírì ìwà rere Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, bí ọmọ kan bá ra ẹ̀bùn kan fún òbí rẹ̀ tàbí tí ó bá ṣe é fún un, èé ṣe tí inú òbí náà yóò fi dùn jọjọ? Ẹ̀bùn náà ha di àwọn àìní kan tí kì bá má ti ṣeé ṣe fún òbí náà láti kúnjú bí? Ó lè máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú òbí náà ń dùn láti rí i pé ọmọ náà ń mú ẹ̀mí ìmọrírì àti fífúnni dàgbà. Fún ìdí kan náà, Jèhófà fún wa níṣìírí láti fún òun ní nǹkan, inú rẹ̀ sì ń dùn nígbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà yìí ni a ń gbà fi hàn án pé ní tòótọ́, a mọrírì inú rere rẹ̀ tí kò láàlà àti ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ sí wa. Òun ni olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé,” nítorí náà a kò lè ṣàìní ìdí láé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Jákọ́bù 1:17) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà fún wa ní Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ní yíyọ̀ọ̀da fún un láti kú kí a baà lè wà láàyè títí láé. (Jòhánù 3:16) Ọpẹ́ wa ha lè tó láé bí?

Ìkejì ni pé, bí a bá sọ fífún un ní nǹkan dàṣà, à ń tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ láti ṣàfarawé Jèhófà àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jèsú Kristi, lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. Jèhófà máa ń fúnni ní nǹkan nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọ̀làwọ́ nígbà gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ó fi “ìyè àti èémí àti ohun gbogbo,” jíǹkí wa. (Ìṣe 17:25) Ó tọ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún gbogbo èémí tí a ń mí, gbogbo oúnjẹ jíjẹ tí a ń gbádùn, gbogbo sáà ayọ̀ àti sáà tí ó gbádùn mọ́ wa nínú ìgbésí ayé. (Ìṣe 14:17) Jésù, gẹ́gẹ́ bí Bàbá rẹ̀, fi ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan hàn. Ó fi ara rẹ̀ fúnni láìṣìrègún. Ìwọ ha mọ̀ pé nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó ná an ní àwọn ohun kan? Ó ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ tí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé, nígbà tí ó wo àwọn aláìsàn sàn, agbára “jáde lọ láti ara rẹ̀.” (Lúùkù 6:19; 8:45, 46) Jésù jẹ́ ọ̀làwọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi tú ọkàn rẹ̀, ìwàláàyè rẹ̀ fúnra rẹ̀, jáde sí ikú gan-an.—Aísáyà 53:12.

Nítorí náà nígbà tí a bá fún un ní nǹkan, yálà àkókò wa, tàbí okun wa, tàbí dúkìá wa, a ń ṣàfarawé Jèhófà, a sì ń mú kí inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11; Éfésù 5:1) A tún ń tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe pípé fún ìwà ẹ̀dá ènìyàn tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ fún wa.—Pétérù Kìíní 2:21.

Ẹ̀kẹta ni pé, fífún un ní nǹkan ń kúnjú àwọn àìní gidi, tí ó sì ṣe pàtàkì. Lóòótọ́, Jèhófà lè fi tìrọ̀rùntìrọ̀rùn kúnjú àwọn àìní ire Ìjọba láìsí ìrànlọ́wọ́ wa, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti lè ṣètò kí àwọn òkúta ké jáde dípò lílò wá láti wàásù ọ̀rọ̀ náà. (Lúùkù 19:40) Ṣùgbọ́n ó ti yàn láti fi àwọn àǹfààní wọ̀nyí dá wa lọ́lá. Nítorí náà, nígbà tí a bá fún un ní ohun ìní wa fún ìtẹ̀síwájú ire Ìjọba, a ń ní ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà ti mímọ̀ pé a ń kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń lọ lọ́wọ́ nínú ayé yìí.—Mátíù 24:14.

Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní sísọ mọ́ pé gbígbọ́ bùkátà iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń béèrè owó. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995, Society ná ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 60 mílíọ̀nù dọ́là lórí bíbójú tó kìkì àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì, àti àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá tí a yàn fún wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyẹn kéré níye ní ìfiwéra pẹ̀lú ìnáwó ìkọ́lé àti ìṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ilé ìtẹ̀wé káàkiri ayé. Síbẹ̀, ọrẹ àtinúwá mú kí gbogbo rẹ̀ ṣeé ṣe!

Ní gbogbogbòò, àwọn ènìyàn Jèhófà kì í rò pé, bí àwọn fúnra wọn kò bá rí jájẹ, àwọn kúkú lè jẹ́ kí àwọn mìíràn gbé ẹrù náà. Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí pípàdánù nínú irú apá yìí tí ó jẹ́ ti ìjọsìn wa. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ, “ipò òṣì paraku” fi ìyà jẹ àwọn Kristẹni ní Makedóníà. Síbẹ̀, wọ́n bẹ̀bẹ̀ ṣáá fún àǹfààní fífúnni. Pọ́ọ̀lù sì jẹ́rìí sí i pé, ohun tí wọ́n fúnni “ré kọjá agbára ìlèṣe wọn gan-an”!—Kọ́ríńtì Kejì 8:1-4.

Ìkẹrin, Jèhófà ti mú kí fífúnni jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́ nítorí pé fífúnni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀. Jésù fúnra rẹ̀ wí pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bí Jèhófà ṣe dá wa nìyẹn. Ó tún jẹ́ ìdí mìíràn tí a fi lè nímọ̀lára pé láìka bí ohun tí a fún un ti ṣe lè pọ̀ tó, kò lè tó ìmọrírì tí a ní fún un ní ọkàn-àyà wa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó múni láyọ̀ pé, Jèhófà kò retí ju ohun tí agbára wá ká láti fún un lọ. A lè ní ìgbọ́kànlé pé, inú rẹ̀ ń dùn nígbà tí a bá fi tayọ̀tayọ̀ fún un ní ohun tí a bá lè fún un!—Kọ́ríńtì Kejì 8:12; 9:7.

Ìbùkún Ń Wá Láti Inú Fífi Ẹ̀mí Fífúnni Hàn

Láti padà sí àpẹẹrẹ wa ìṣáájú, kí a gbà pé opó Sáréfátì nì ti wí àwíjàre pé ẹlòmíràn lè bójú tó àìní tí Èlíjà ní fún oúnjẹ. Ẹ wo irú ìbùkún tí ì bá ti pàdánù!

Kò sí àní àní pé Jèhófà ń bù kún àwọn tí ń fi ẹ̀mí fífúnni hàn. (Òwe 11:25) Opó Sáréfátì kò jìyà nítorí pé ó fi ohun tí ó rò pé ó jẹ́ oúnjẹ àjẹkẹ́yìn rẹ̀ tọrẹ. Jèhófà fi iṣẹ́ ìyanu san èrè fún un. Gẹ́gẹ́ bí Èlíjà ti ṣèlérí, kólòbó ìyẹ̀fun àti ti òróró rẹ̀ kò gbẹ títí tí ọ̀dá náà fi kọjá lọ. Ṣùgbọ́n ó tún rí èrè ńláǹlà míràn gbà. Nígbà tí ọmọkùnrin rẹ̀ dùbúlẹ̀ àìsàn, tí ó sì kú, Èlíjà, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, mú un padà wá fún un. Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti gbé ipò tẹ̀mí rẹ̀ ró tó!—Àwọn Ọba Kìíní 17:16-24.

Lónìí, a kò retí pé kí a fi iṣẹ́ ìyanu bù kún wa. (Kọ́ríńtì Kìíní 13:8) Ṣùgbọ́n, Jèhófà mú kí ó dá wa lójú pé, òun yóò pèsè fún àwọn tí ó bá ṣiṣẹ́ sin òun tọkàntọkàn. (Mátíù 6:33) Nítorí náà, a lè dà bí opó Sáréfátì lọ́nà yẹn, kí a fúnni pẹ̀lú ọ̀làwọ́, ní níní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò bójú tó wa. Bákan náà, a lè gbádùn èrè tẹ̀mí ńláǹlà. Bí fífúnni wa bá jẹ́ apá kan ohun tí a ń ṣe déédéé, dípò ọ̀ràn ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n, àfìwàǹwáraṣe, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ojú wa mú ọ̀nà kan, kí a sì pa àfiyèsí pọ̀ sórí ire Ìjọba, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti dámọ̀ràn. (Lúùkù 11:34; fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 16:1, 2.) Yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti nímọ̀lára pé a túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn. (Kọ́ríńtì Kìíní 3:9) Yóò sì fi kún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àti fífúnni ti a fi ń dá àwọn olùjọ́sìn Jèhófà mọ̀ kárí ayé.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÍ ÀWỌN KAN YÀN LÁTI FÚN UN NÍ NǸKAN

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a lẹ ìsọfúnni náà: “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká Ayé​—⁠Mátíù 24:14” mọ́ lára. Lóṣooṣù ni àwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́, yálà sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka ti àdúgbò.

A lè fi ìtọrẹ owó tí a fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-​2483, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè ẹni. A tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì míràn ṣètọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.

ÌṢÈTÒ ÌTỌRẸ ONÍPÒ ÀFILÉLẸ̀

A lè fún Watch Tower Society ní owó láti máa lò ó bí ohun afúnniṣọ́, títí di ìgbà ikú olùtọrẹ náà, pẹ̀lú ìṣètò pé tí àìní fún lílo owó náà bá dìde, a óò dá a padà fún ẹni tí ó fi tọrẹ. Fùn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí ó wà lókè yìí.

FÍFÚNNI TÍ A WÉWÈÉ

Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ìtọrẹ onípò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà míràn wà tí a lè gbà fúnni, fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba kárí ayé. Èyí ní nínú:

Owó Ìbánigbófò: A lè lo orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní nínú ìlànà ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí nínú ìwéwèé owó àsanfúnni fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. A ní láti fi irú ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.

Àkáǹtì Owó ní Báǹkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báǹkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan sí ìkáwọ́ tàbí mú kí ó ṣeé san nígbà ikú, fún Watch Tower Society, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báǹkì àdúgbò bá béèrè fún. A ní láti fi irú àwọn ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.

Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Lórí Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti lórí ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá, tàbí lábẹ́ ìṣètò kan, níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé wá lórí èyí fún olùtọrẹ náà.

Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeé tà, ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn pátápátá, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní olùtọrẹ náà, nígbà tí ó bá ṣì wà láàyè, ẹni tí ó ṣì lè máa gbé inú rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ẹnì kan ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Ìfisíkàáwọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, a sì lè dárúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní irú ìwé àdéhùn fífi ohun sí ìkáwọ́ ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́ tí ètò àjọ ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòò kan nínú ọ̀ràn owó orí. A ní láti fi ẹ̀dà kan nínú ìwé ìhágún tàbí ìwé àdéhùn ohun ìní ìfisíkàáwọ́ ránṣẹ́ sí Society.

Àwọn tí ó bá ní ọkàn ìfẹ́ nínú èyíkéyìí nínú ìṣètò fífúnni tí a wéwèé wọ̀nyí lè kàn sí Planned Giving Desk ní àdírẹ́sì tí a tò sísàlẹ̀ tàbí sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Planned Giving Desk ní láti rí ẹ̀dà kan àwọn ìwé pàtàkì tí ó jẹ mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò wọ̀nyí gbà.

Society ti mú ìwé pẹlẹbẹ kan jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a pè ní, Planned Giving. Àwọn tí wọ́n wà ní United States tí wọ́n ń wéwèé láti fún Society ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ nísinsìnyí tàbí láti fi ìwé ìhágún sílẹ̀ lẹ́yìn ikú lè rí i pé ìsọfúnni yìí yóò ṣèrànwọ́. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì bí wọ́n bá fẹ́ láti ṣàṣeparí àwọn góńgó ìdílé kan tàbí ète ìwéwèé dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ ní lílo àǹfààní owó orí láti dín iye owó ẹ̀bùn náà tàbí ogún náà kù. Ìwé pẹlẹbẹ náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí a bá béèrè fún un, yálà nípa kíkọ̀wé tàbí títẹ̀ wá láago.

PLANNED GIVING DESK

Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

100 Watchtower Drive, Patterson, New York 12563-​9204

Telephone: (914) 878-​7000

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́