Fí Ọwọ́ Tó Tọ́ Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
1 Nígbà tí Fílípì ń jẹ́rìí fún ìjòyè ọba kan, ó “la ẹnu rẹ̀ àti pé, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ [kan], ó polongo ìhìn rere nípa Jésù fún un.” (Ìṣe 8:35) Fílípì “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15) Àmọ́ lóde òní, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn akéde ni kì í sábà lo Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń wàásù. Ṣé o máa ń lo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
2 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni orísun gbogbo ohun tí a gbà gbọ́ tí a sì ń fi kọ́ni. (2 Tím. 3:16, 17) Òun ló ń fa àwọn èèyàn sún mọ́ Jèhófà tí ó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ìyè. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì láti máa lo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dípò tí a ó kàn fi máa jíròrò àwọn kókó tá a nífẹ̀ẹ́ sí nìkan. (Héb. 4:12) Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì, a ní láti kà á jáde tààràtà kí wọ́n lè mọ bí ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ ṣe wúlò tó, kí wọ́n sì lè mọ irú ọjọ́ iwájú tí ó nawọ́ rẹ̀ jáde fún aráyé.
3 Ka Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Jáde Tààràtà: Bí àwọn èèyàn tó ń gbé lágbègbè rẹ bá máa ń ṣiyè méjì nípa ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ àwọn tí ń gbé àpò kiri láti wàásù, o lè gbìyànjú láti wàásù láìgbé àpò òde ẹ̀rí dání. O lè kó ìwé tó o fẹ́ fi lọni sínú àpò pẹlẹbẹ kan, kí o sì mú Bíbélì rẹ dání tàbí kí o fi sínú àpò aṣọ rẹ. Nígbà náà, bó o ti ń bá ẹni kan fọ̀rọ̀ wérọ̀, rọra fa Bíbélì yọ láìjẹ́ kí ẹni náà máa ronú pé ìwàásù tó ń gba àkókò lo fẹ́ gbẹ́nu lé. Yálà o wà lórí ìjókòó tàbí o wà lórí ìdúró, rọra yí ara lọ́nà tí ẹni tó o ń bá sọ̀rọ̀ á fi lè máa fojú bá Bíbélì tó o ń kà náà lọ. O tiẹ̀ lè ní kó ka ẹsẹ Bíbélì kan sókè ketekete. Bó bá fojú ara rẹ̀ rí ohun tí Bíbélì sọ, èyí á tẹ ọ̀rọ̀ náà mọ́ ọn lọ́kàn ju pé kó kàn fetí gbọ́ ọ lásán. Àmọ́ ṣá o, láti mú kí ibi tí o kà yé e, tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé kókó ibẹ̀ yọ.
4 Fífi Ẹsẹ Bíbélì Kan Ṣoṣo Báni Sọ̀rọ̀: Lẹ́yìn tó o bá ti sọ ẹni tó o jẹ́ tán, o lè sọ pé: “Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn ń yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé wọn. Ibo nìwọ́ rò pé ó dára jù lọ tá a lè yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Sọ èrò rẹ nípa gbólóhùn yìí fún mi. [Ka Òwe 2:6, 7, kí o sì jẹ́ kó fèsì.] Òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ lọgbọ́n ọmọ aráyé, ó sì ti fìdí àìmọye èèyàn jálẹ̀. Àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe é gbára lé, àǹfààní tó ń tinú rẹ̀ jáde sì máa ń wà títí lọ kánrin ni.” Lẹ́yìn náà, fi ìwé tó o mú dání lọ̀ ọ́, kí o sì fi àpẹẹrẹ kan hàn án láti inú rẹ̀ nípa bí ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe gbéṣẹ́ tó.
5 Jésù lo Ìwé Mímọ́ láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́. (Lúùkù 24:32) Pọ́ọ̀lù fi Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí sí àwọn ohun tó fi kọ́ni. (Ìṣe 17:2, 3) Ìgboyà tá a ní láti wàásù àti ayọ̀ wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò pọ̀ sí i bí a ti túbọ̀ ń ní òye sí i nínú bí a ti ń fi ọwọ́ tó tọ́ mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.