Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ?
1 Nínú ìwé Ìṣe, a sọ fún wa pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣepé nípa ‘jíjẹ́rìí kúnnákúnná’ fún àwọn èèyàn. (Ìṣe 2:40; 8:25; 28:23) Ète tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn gan-an nìyẹn. (Ìṣe 20:24) Àbí kì í ṣe ohun tí ìwọ pẹ̀lú ń lépa bí ajíhìnrere nìyẹn? Báwo lo ṣe lè ṣe é?
2 Múra Ọ̀nà Tóo Máa Gbà Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀: Ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì fún ọ láti lè rí i dájú pé o wàásù lọ́nà tó mọ́yán lórí lóde ẹ̀rí. Ìgbà tóo bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn lọni lèyí tiẹ̀ túbọ̀ ṣe pàtàkì jù nítorí pé ìgbà gbogbo ni kókó tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lé máa ń yí padà. Kí a lè gbára dì lọ́nà tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i, ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí bẹ̀rẹ̀ gbígbé ohun tuntun kan jáde, ìyẹn lápá òsì, níbi tí àwọn àpẹẹrẹ ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a lè lò láti fi àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni wà. Kókó kan tó bágbà mu tí yóò fa ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ra nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀ka yẹn yóò máa gbé jáde. Báwo lo ṣe lè lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣókí yìí?
3 Yan ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tóo bá mọ̀ pé yóò ṣiṣẹ́ jù lọ ní ìpínlẹ̀ yín. Fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ tí ìwé ìròyìn náà sọ̀rọ̀ lé, kí o sì kíyè sí àwọn kókó pàtó tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn mọ́ra. Wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí a tọ́ka sí nínú ìwé ìròyìn náà tó bá ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ mu, tí o máa kà fún onílé. Fi ọ̀rọ̀ ìparí ṣókí kún un láti fún ẹni tí o ń bá sọ̀rọ̀ náà níṣìírí pé kí ó ka ìwé náà, bí ó bá sì yẹ bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé ní ṣókí pé onílé lè fi ọrẹ àtinúwá ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe jákèjádò ayé. Wàyí o, fi ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ dánra wò.
4 Wéwèé Láti Lo Bíbélì: Bí o bá wéwèé dáadáa, ọ̀pọ̀ ìgbà ni yóò ṣeé ṣe fún ọ láti fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan kún ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ ibi, àwọn akéde onírìírí ṣàṣeyọrí nípa mímú Bíbélì dání lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọn yóò kí onílé, wọn yóò sì sọ pé:
◼ “A ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn bóyá wọ́n gba gbólóhùn yìí gbọ́ . . . ” Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:1, kí o sì wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ o gbà pé òótọ́ ni gbólóhùn yẹn?” Bí ẹni náà bá gbà pé òótọ́ ni, kí o wá sọ pé: “Èmi náà gbà pé òótọ́ ni. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o rò pé bó bá jẹ́ Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, a jẹ́ pé òun náà ló ń fa ìwà ibi?” Lẹ́yìn tí o bá ti dúpẹ́ fún èsì ẹni náà, ka Oníwàásù 7:29. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 71, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2. Fún ẹni náà níṣìírí pé kí ó ka ìwé náà.
5 Padà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Ẹni Tó Bá Fìfẹ́ Hàn: O kò lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ bí o kì í bá padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn. Bí o bá bá ẹnì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà tó lárinrin, bóyá o fi ìwé ìròyìn tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ níbẹ̀ o tàbí o kò ṣe bẹ́ẹ̀, kọ orúkọ ẹni yẹn àti àdírẹ́sì rẹ̀ sílẹ̀. Sapá gidigidi láti lè mú kí ìfẹ́ tí ẹni yẹn ní pọ̀ sí i nípa títètè padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Kí o rí i dájú pé o fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní mọ̀ pé àṣẹ ló jẹ́ látọ̀dọ̀ Jésù láti “jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Àṣẹ yẹn kan àwa náà pẹ̀lú, nítorí ọ̀nà yẹn nìkan ṣoṣo la lè gbà sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—2 Tím. 4:5.