ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àwọn oṣù àpéjọpọ̀. Kí àwọn ìjọ ṣe ìyípadà tó yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kẹ́yìn kí ẹ tó lọ sí àpéjọpọ̀ láti ṣàtúnsọ àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tí ó bá ìjọ yín mu nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Ní oṣù February 2002, a ó ṣètò odindi Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì nínú àpéjọpọ̀ náà. Láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn, gbogbo wa lè kọ àkọsílẹ̀ tó nítumọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà, kí a sì jẹ́ kí àwọn kókó tí àwa fúnra wa fẹ́ fi sílò nínú ìgbésí ayé wa àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wà lára rẹ̀. Nígbà náà, a ó lè múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé bí a ti ṣe fi àwọn àbá wọ̀nyẹn sílò látìgbà táa ti lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Gbígbọ́ bí a ṣe jàǹfààní látinú ìtọ́ni àtàtà tí a rí gbà náà yóò gbé gbogbo wa ró.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 10

Orin 86

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

13 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé. Ṣàyẹ̀wò ètò tí ìjọ ṣe fún àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ti ọ̀sẹ̀ yìí. Ṣàlàyé bí gbogbo àwọn tó bá wá ṣe lè mú kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ní àwọn ìpàdé náà túbọ̀ ṣàǹfààní. Rọ gbogbo ìjọ pé kí wọ́n ṣètìlẹyìn fún ètò iṣẹ́ ìsìn yìí.

22 min: “Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ?”a Lẹ́yìn bíbá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí ìpínrọ̀ 1 sí 3, ṣàṣefihàn kan tàbí méjì tó ṣe ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ September 15, kí ìkejì sì lo Jí! September 8. Lẹ́yìn fífọ̀rọ̀wérọ̀ lórí ìpínrọ̀ 4, fi ìwé Ìmọ̀ ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ táa dábàá.

Orin 124 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 17

Orin 92

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

14 min: “Ìgbà Àpéjọpọ̀ Jẹ́ Àkókò Ayọ̀!” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ. Ṣàlàyé ìdí tí àwọn èèyàn Jèhófà fi máa ń kóra jọ ní àpéjọ ńláńlá ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àti ìdí tí àwọn àpéjọpọ̀ yẹn fi ṣàǹfààní lónìí bíi tìgbà yẹn. Àkókò wọ̀nyẹn máa ń pèsè ìbákẹ́gbẹ́ tí ń fúnni lókun àti oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe kókó. Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa wà ní àpéjọpọ̀ àgbègbè yìí ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

16 min: “A Pé Jọpọ̀ ‘Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò.’”b Ṣàlàyé díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ètò tí a ní láti ṣe láti lè múra sílẹ̀ fún àpéjọpọ̀ kan. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífọwọ́sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú gbogbo ìlànà tí a ti gbé kalẹ̀ láti ṣe wá láǹfààní. Ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí gbogbo wa lè gbà fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn kí á sì yẹra fún àwọn ìṣòro tí wọ́n ṣeé yẹra fún.

Orin 31 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 24

Orin 97

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà nínú “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn,” ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ October 1, kí ìkejì sì lo Jí! October 8.

17 min: “Ẹ Fetí Sílẹ̀ Kí Ẹ sì Gba Ìtọ́ni Púpọ̀ Sí I.” Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé ìdí tí ìtọ́ni tí a ń pèsè ní àwọn àpéjọpọ̀ fi jẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí ṣíṣe kókó táa nílò. Sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá tí ṣíṣètò irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀ máa ń gbà. Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè ṣe láti rí i pé òun àtàwọn ẹlòmíràn jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa wà lórí ìjókòó wa nígbà tí ìpàdé kọ̀ọ̀kan bá bẹ̀rẹ̀.

18 min: “Ṣe Rere Kí O sì Gba Ìyìn!”c Ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń kíyè sí wa nígbà tí a bá lọ sí àpéjọpọ̀. Ọ̀rọ̀ rere táwọn èèyàn bá sọ nípa wa máa ń fi kún ìjẹ́rìí nípa Ìjọba náà, ṣùgbọ́n àríwísí lè mú káwọn èèyàn máà fẹ́ láti gbọ́rọ̀ wa. Sọ àwọn nǹkan pàtó tí a ní láti ṣe láti fi hàn pé a ní àwọn ànímọ́ Kristẹni tí a sì ń ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn ní ti gidi.

Orin 105 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 1

Orin 106

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù September sílẹ̀.

15 min: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Ṣe Dáadáa ní Ilé Ẹ̀kọ́? Alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan àti ìyàwó rẹ̀ ń bá ọmọ wọn tó ti ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀. Wọ́n ń ṣàníyàn nítorí pé ọmọ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀yìn nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, orí 18, wọ́n sì jíròrò ohun tí ọmọ náà nílò láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i. Àwọn òbí tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó kí èèyàn lè lo gbogbo agbára rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.

20 min: “Ṣé Ohun Ìdènà Ló Jẹ́ fún Iṣẹ́ Ìwàásù?”d Tẹnu mọ́ ìdí táa fi ní láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kí á sì fi ire Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú àwọn ohun àkọ́múṣe wa. Ké sí àwọn olórí ìdílé kan nínú ìjọ pé kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe ń borí ìpèníjà pípèsè nípa ti ara fún ìdílé wọn láìjẹ́ pé wọ́n pa bíbójú tó ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí tì.

Orin 137 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́