ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/96 ojú ìwé 3-6
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 6/96 ojú ìwé 3-6

Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

1 Góńgó fífanilọ́kàn mọ́ra fún gbogbo Kristẹni jẹ́ láti fi òtítọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n sì sọ àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 13:48; Mat. 28:19, 20) Ètò àjọ Jèhófà ti pèsè irin iṣẹ́ àgbàyanu fún wa tí a lè fi ṣàṣeparí èyí—ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àkòrí rẹ̀ tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gíga lọ́lá tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ní, nítorí pé ìyè àìnípẹ̀kun sinmi lórí gbígba ìmọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà, àti ti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, sínú.—Joh. 17:3.

2 Nísinsìnyí, ìwé Ìmọ̀ ni ìtẹ̀jáde pàtàkì ti Society, tí ó wà fún dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ní lílò ó, a lè fi òtítọ́ kọ́ni pẹ̀lú ìrọ̀rùn, lọ́nà ṣíṣe kedere, àti láàárín àkókò kúkúrú. Èyí yóò ṣèrànwọ́ láti dé inú ọkàn àwọn tí a ń kọ́. (Luk. 24:32) Àmọ́ ṣáá o, àìní wà fún olùdarí láti lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jíjíire. Fún ète yẹn, a ti ṣètò àkìbọnú yìí láti pèsè àwọn àbá àti ìránnilétí nípa àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, tí ó ti gbéṣẹ́. Pẹ̀lú ìfòyemọ̀, àti ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti lo díẹ̀ tàbí gbogbo ohun tí a pèsè níhìn-ín ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Tọ́jú àkìbọnú yìí, kí o sì máa ṣàyẹ̀wò rẹ̀ déédéé. Onírúurú kókó inú rẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú lílo ìwé Ìmọ̀ láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.

3 Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé Tí Ń Tẹ̀ Síwájú: Fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni hàn nínú akẹ́kọ̀ọ́ náà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn àti arákùnrin tàbí arábìnrin tẹ̀mí lọ́la. Jẹ́ ọlọ́yàyà, ẹni tí ń yá mọ́ni, àti onítara. Nípa jíjẹ́ ẹni tí ń fetí sílẹ̀ dáradára, ìwọ lè wá mọ ẹni náà—ìgbésí ayé àtilẹ̀wá rẹ̀ àti ipò rẹ̀ ní ìgbésí ayé—èyí tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fòye mọ bí o ṣe lè ràn án lọ́wọ́ jù lọ nípa tẹ̀mí. Múra tán láti lo ara rẹ nítorí akẹ́kọ̀ọ́ náà.—1 Tẹs. 2:8.

4 Gbàrà tí a bá ti fìdí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan múlẹ̀, ó dára jù pé kí a kẹ́kọ̀ọ́ àwọn orí tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀ bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra. Èyí yóò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ jèrè òye òtítọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, níwọ̀n bí ìwé náà ti ṣàlàyé àwọn kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú jù lọ. Jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà rọrùn kí ó sì gbádùn mọ́ni, kí ó baà lè tani jí kí ó sì máa tẹ̀ síwájú. (Rom. 12:11) Ní sísinmi lórí bí ipò àyíká akẹ́kọ̀ọ́ bá ti rí àti bí òye rẹ̀ bá ti tó, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti kárí orí tí ó pọ̀ jù lọ ní ìjókòó wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ díẹ̀, láìkánjú ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní ìtẹ̀síwájú dáradára bí olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ bá ń pa àdéhùn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ mọ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Nípa báyìí, fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó lè ṣeé ṣe láti parí gbogbo orí 19 ìwé náà láàárín nǹkan bí oṣù mẹ́fà.

5 Nasẹ̀ ìjókòó kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú gbólóhùn ṣókí tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ìwọ yóò kíyè sí i pé àkòrí orí kọ̀ọ̀kan ni ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a ní láti tẹnu mọ́. Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan fa kókó pàtàkì kan yọ, ní ríràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ọkàn pọ̀ sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ orí náà. Ṣọ́ra kí o má ṣe sọ̀rọ̀ jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀ jáde. Bíbéèrè àwọn ìbéèrè atọ́ka pàtó lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí a gbé karí ohun tí òún ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, yóò ràn án lọ́wọ́ láti ronú, kí ó sì dórí ìpinnu tí ó tọ̀nà. (Mat. 17:24-26; Luk. 10:25-37; wo Iwe-Amọna, ojú ìwé 52, ìpínrọ̀ 10.) Rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìsọfúnni tí a tẹ̀ sínú ìwé Ìmọ̀. Sísọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míràn lọ́tọ̀ lè pe àfiyèsí kúrò lórí àwọn kókó pàtàkì tàbí kí ó ṣíji bò wọ́n, kí ó sì mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà falẹ̀. (Joh. 16:12) Bí a bá béèrè ìbéèrè tí kò jẹ mọ́ kókó ẹ̀kọ́ tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, o lè dáhùn rẹ̀ ní òpin ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Èyí yóò mú kí o lè kárí ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ náà láìyagbó yajù. Ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ náà pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a óò dáhùn ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìbéèrè tí ó ní bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń bá a nìṣó.—Wo Iwe-Amọna, ojú ìwé 94, ìpínrọ̀ 14.

6 Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá gbà gbọ́ gidigidi nínú Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, iná hẹ́ẹ̀lì, tàbí irú àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké mìíràn bẹ́ẹ̀, tí ohun tí a sì pèsè nínú ìwé Ìmọ̀ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn, o lè fún un ní ìwé Reasoning tàbí ìtẹ̀jáde mìíràn, tí ó jíròrò kókó ẹ̀kọ́ náà. Sọ fún un pé ìwọ yóò jíròrò kókó náà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti ronú nípa ohun tí ó kà.

7 Bíbẹ̀rẹ̀ àti píparí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pẹ̀lú àdúrà fún ìdarísọ́nà àti ìbùkún Jèhófà ń buyì kún àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ń fúnni ní ipò ọkàn tí ó jẹ́ ọlọ́wọ̀, ó sì ń pe àfiyèsí sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ tòótọ́ náà. (Joh. 6:45) Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣì ń lo tábà, o lè ní láti sọ fún un lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láti jáwọ́ nínú rẹ̀.—Ìṣe 24:16; Jak. 4:3.

8 Fi Ìwé Mímọ́, Àwọn Àwòrán, àti Ìbéèrè Àtúnyẹ̀wò Kọ́ni Lọ́nà Gbígbéṣẹ́: Láìka iye ìgbà tí òún ti lè kẹ́kọ̀ọ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà tẹ́lẹ̀ sí, ọ̀jáfáfá olùkọ́ yóò ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ní níní akẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an lọ́kàn. Èyí ń ṣèrànwọ́ láti wòye mọ díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè akẹ́kọ̀ọ́ náà. Láti kọ́ni lọ́nà gbígbéṣẹ́, lóye àwọn kókó pàtàkì inú orí náà dáradára. Yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí wọ́n ṣe bá àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà mu, kí o sì pinnu èwo ni ó yẹ kí ẹ kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ronú nípa bí o ṣe lè kọ́ni ní lílo àwọn àwòrán àti ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tí ó wà lópin orí náà.

9 Nípa lílo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́, ìwọ yóò ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọrírì pé òún ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tòótọ́. (Ìṣe 17:11) Ní lílo àpótí náà, “Lo Bibeli Rẹ Lọ́nà Rere,” ní ojú ìwé 14 ìwé Ìmọ̀, kọ́ ọ bí a ṣe ń wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ rí. Fi bí a ṣe ń mọ àwọn ẹsẹ tí a fà yọ nínú ẹ̀kọ́ hàn án. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, ẹ yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí tí a kò fà yọ wò, kí ẹ sì kà wọ́n. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ti ohun tí a sọ nínú ìpínrọ̀ náà lẹ́yìn tàbí bí wọ́n ṣe mú un ṣe kedere sí i. Tẹnu mọ́ àwọn apá pàtàkì inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà kí òún lè mọrírì àwọn ìdí kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà. (Neh. 8:8) Ní gbogbogbòò, kò sí ìdí fún olùkọ́ láti mú àfikún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọnú ìjíròrò náà ju èyí tí ìwé náà pèsè. Sọ̀rọ̀ lórí ìníyelórí mímọ àwọn orúkọ àti ìtòtẹ̀léra àwọn ìwé Bíbélì. Ó lè ṣèrànwọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ka Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1991, ojú ìwé 27 sí 30. Nígbà tí ó bá yẹ, fún un níṣìírí láti lo New World Translation. O lè ṣàṣefihàn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé bí a ṣe ń lo onírúurú apá fífanimọ́ra tí ó ní, irú bí àwọn ìtọ́kasí etí ìwé àti atọ́ka àṣàyàn ọ̀rọ̀ Bíbélì.

10 Ìkẹ́kọ̀ọ́ 34 nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun ṣàlàyé pé àwọn àpèjúwe máa ń ru ipa ọ̀nà ìrònú ẹni sókè, ó sì ń jẹ́ kí ó rọrùn láti lóye àwọn èrò tuntun. Wọ́n ń so ọgbọ́n ìrònú àti ipá ìmí ẹ̀dùn pọ̀, kí a baà lè gbé ìhìn iṣẹ́ náà kani lọ́kàn pẹ̀lú ipá kan tí kì í sábà ṣeé ṣe pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ lásán. (Mat. 13:34) Ìwé Ìmọ̀ ní ọ̀pọ̀ àpèjúwe tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n rọrùn, síbẹ̀ tí wọ́n lágbára. Fún àpẹẹrẹ, àpèjúwe kan tí a lò ní orí 17 gbé ìmọrírì ró fún bí Jèhófà, lọ́nà tẹ̀mí, ṣe ń pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. A lè lo àwọn àpèjúwe aláwòrán rírẹwà ti inú ìwé Ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti ru ìmọ̀lára sókè. Lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, “Àjíǹde Onídùnnú-Ayọ̀,” ní ojú ìwé 185, a óò fún ipá tí ìpínrọ̀ 18 ní lókun nípa mímú kí akẹ́kọ̀ọ́ padà wo àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 86. Èyí lè mú kí ó ronú nípa àjíǹde gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ gidi nínú Ìjọba Ọlọ́run.

11 Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti ń kárí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Fún ìdí yìí, má ṣe kùnà láti béèrè àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò nínú àpótí “Dán Ìmọ̀ Rẹ Wò” tí ó fara hàn ní òpin orí kọ̀ọ̀kan. Fetí sílẹ̀ fún ohun tí ó ju àlàyé onírònúmòye nípa ohun tí ẹ kọ́. A pète ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti mú kí a dáhùn láti inú ọkàn wá. Fún àpẹẹrẹ, wo ojú ìwé 31, níbi tí a ti béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Èwo nínú àwọn ànímọ́ Jehofa Ọlọrun ni ó fà ọ́ mọ́ra níti gidi?”—2 Kọr. 13:5.

12 Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Múra Sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́: Akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá ka ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, tí ó sàmì sí àwọn ìdáhùn, tí ó sì ronú nípa bí òun yóò ṣe sọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ yóò ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tí ó túbọ̀ yára kánkán. Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ àti ìṣírí tìrẹ, o lè kọ́ ọ láti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀. Fi ìwé tìrẹ hàn án, níbi tí o ti sàmì sí tàbí fàlà sábẹ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn. Ṣàlàyé bí a ṣe ń rí àwọn ìdáhùn tààràtà sí àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀. Mímúra orí kan sílẹ̀ pa pọ̀ lè ṣèrànwọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà. Fún un níṣìírí láti sọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀. Kìkì ìgbà náà ni ó tó ṣe kedere bóyá ó lóye àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá ka ìdáhùn rẹ̀ láti inú ìwé, o lè ru ìrònú rẹ̀ sókè nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí yóò ṣe ṣàlàyé kókó náà fún ẹlòmíràn ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀.

13 Fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí ṣùgbọ́n tí a kò fà yọ wò, gẹ́gẹ́ bí apá kan ìmúrasílẹ̀ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ̀, níwọ̀n bí àkókò ti lè ṣàìsí láti ka gbogbo wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́. Gbóríyìn fún un fún ìsapá tí ó ń ṣe lórí ẹ̀kọ́ rẹ̀. (2 Pet. 1:5; wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1993, ojú ìwé 13 àti 14, fún àfikún àbá lórí ohun tí olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ lè ṣe láti mú kí òye gbé pẹ́ẹ́lí sí i nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.) Lọ́nà yìí, a ń dá akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ láti múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, kí ó sì dáhùn lọ́nà tí ó nítumọ̀. Òun yóò máa kọ́ bí a ṣe ń mú àṣà ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí ó jíire dàgbà, tí yóò mú un gbara dì láti máa bá ìtẹ̀síwájú nínú òtítọ́ nìṣó lẹ́yìn tí ó bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀.—1 Tim. 4:15; 1 Pet. 2:2.

14 Darí Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Jèhófà: Ó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn láti darí ọkàn-ìfẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ sí ètò àjọ Jèhófà. Akẹ́kọ̀ọ́ yóò tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú tẹ̀mí kíákíá, bí ó bá mọ ètò àjọ náà, tí ó sì mọrírì rẹ̀, tí ó sì rí àìní náà láti di apá kan rẹ̀. A fẹ́ kí ó gbádùn kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run, kí ó sì máa wọ̀nà fún wíwà pẹ̀lú wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, níbi tí ó ti lè rí ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára tí ìjọ Kristẹni ń fi fúnni gbà.—1 Tim. 3:15.

15 A tẹ ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹrii Jehofa—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé jáde, láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti mọ ètò àjọ kan ṣoṣo tí a lè fojú rí, tí Jèhófà ń lò lónìí láti ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀. Gbàrà tí o bá ti fìdí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà múlẹ̀, èé ṣe tí o kò fi fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀dà kan? Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, máa ké sí akẹ́kọ̀ọ́ náà sí àwọn ìpàdé. Ṣàlàyé bí a ṣe ń darí wọn. O lè sọ àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí ń bọ̀ fún un tàbí kí o fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a óò jíròrò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà hàn án. Bóyá o lè mú un lọ wo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà nígbà tí kò bá sí ìpàdé tí ń lọ lọ́wọ́, kí o baà lè dín hílàhílo èyíkéyìí tí òún lè ní nípa lílọ sí ibi tuntun fún ìgbà àkọ́kọ́ kù. Ó lè ṣeé ṣe kí o pèsè ohun ìrìnnà lọ sí ìpàdé. Nígbà tí ó bá wá sí ìpàdé, jẹ́ kí ó nímọ̀lára pé a tẹ́wọ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, kí ara sì tù ú. (Mat. 7:12) Fi í han àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn, àti àwọn alàgbà. A retí pé òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí wo ìjọ gẹ́gẹ́ bí ìdílé rẹ nípa tẹ̀mí. (Mat. 12:49, 50; Mak. 10:29, 30) O lè gbé góńgó kan kalẹ̀ fún un, bíi wíwá sí ìpàdé kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí o sì máa fi kún góńgó náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé.—Heb. 10:24, 25.

16 Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ti ń bá a nìṣó nínú ìwé Ìmọ̀, tẹnu mọ́ apá tí ó tẹnu mọ́ àìní náà fún kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú ìjọ ní àwọn ìpàdé. Ṣàkíyèsí ní pàtàkì, ojú ìwé 52, 115, 137 sí 139, 159, àti orí 17. Sọ ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí ìwọ fúnra rẹ ní fún ètò àjọ Jèhófà jáde. (Mat. 24:45-47) Sọ̀rọ̀ dáradára nípa ìjọ àdúgbò àti nípa ohun tí o ń kọ́ ní àwọn ìpàdé. (Sm. 84:10; 133:1-3) Yóò dára bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá lè wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò Society, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Fún àbá síwájú sí i lórí bí a ṣe ń darí ọkàn-ìfẹ́ sí ètò àjọ náà, wo Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1985, ojú ìwé 14 sí 18, àti àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, July 1993.

17 Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Níṣìírí Láti Jẹ́rìí fún Àwọn Ẹlòmíràn: Ète tí a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn jẹ́ láti sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn tí ń jẹ́rìí fún Jèhófà. (Aisa. 43:10-12) Ìyẹ́n túmọ̀ sí pé olùkọ́ ní láti fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ń kọ́ láti inú Bíbélì. A lè ṣe èyí lọ́nà rírọrùn bíi bíbéèrè pé: “Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé òtítọ́ yìí fún ìdílé rẹ?” tàbí “Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ìwọ yóò lò láti mú èyí dá ọ̀rẹ́ kan lójú?” Tẹnu mọ́ àwọn ibi pàtàkì nínú ìwé Ìmọ̀ níbi tí a ti fún ìjẹ́rìí ní ìṣírí, irú bí ojú ìwé 22, 93 sí 95, 105, 106, àti orí 18. Nígbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀, a lè fún akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé àṣàrò kúkúrú díẹ̀ láti lò nínú ìjẹ́rìí àìjẹ́bí-àṣà fún àwọn ẹlòmíràn. Dábàá pé kí ó ké sí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ láti wà ní ìjókòó nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ó ha ní àwọn ọ̀rẹ́ tí yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú bí? Sọ fún un pé kí ó tọ́ka rẹ sí àwọn tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́.

18 Nípa wíwá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ọmọ ẹ̀yìn lọ́la náà lè gba àfikún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìsúnniṣe tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti di akéde ìhìn rere náà. Nígbà tí ó bá sọ ọkàn-ìfẹ́ láti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ náà jáde tàbí láti di akéde tí kò tí ì ṣe batisí, àwọn ìlànà tí a là lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 98 àti 99 nínú ìwé Iṣetojọ yóò gbéṣẹ́. Bí apá ìhà kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀ kò bá jẹ́ kí ó tóótun, o lè wá inú àwọn ìtẹ̀jáde Society fún àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ń ranni lọ́wọ́, tí ó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà, kí o sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, akẹ́kọ̀ọ́ kan lè ní ìṣòro ṣíṣẹ́pá ìfarajìn fún tábà tàbí àwọn oògùn líle mìíràn. Ìwé Reasoning tọ́ka sí àwọn ìdí lílágbára tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu tí àwọn Kristẹni fi ń yẹra fún irú àwọn àṣà tí ń pani lára bẹ́ẹ̀, àti ní ojú ìwé 112, ó sọ ọ̀nà kan tí ó ti ṣàṣeyọrí ní ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti jàjàbọ́. Gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀ nípa ọ̀ràn náà, ní kíkọ́ ọ láti gbára lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.—Jak. 4:8.

19 A ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà tí a ní láti tẹ̀ lé fún pípinnu bóyá ẹnì kan tóótun láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 6. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá tóótun, yóò ṣèrànwọ́ láti ṣe ìfidánrawò láti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ọjọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Lọ́nà tí ó ń gbéni ró, jíròrò ìdáhùnpadà àwọn ènìyàn àti àtakò tí ó wọ́pọ̀ ní agbègbè ìpínlẹ̀ rẹ. Mú kí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nínú iṣẹ́ ilé dé ilé bí ó bá ṣeé ṣe rara, kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ yòókù ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Bí o bá jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ rẹ ṣe ṣókí, tí ó sì rọrùn, yóò rọrùn fún un láti ṣàfarawé rẹ. Jẹ́ agbéniró àti afúnni-níṣìírí, ní fífi ayọ̀ hàn nínú iṣẹ́ náà, kí ó baà lè ní irú ẹ̀mí kan náà, kí ó sì fi í hàn síta. (Ìṣe 18:25) Góńgó ọmọ ẹ̀yìn tuntun yẹ kí ó jẹ́ láti di onítara akéde ìhìn rere, tí ń ṣe déédéé. Bóyá o lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbéṣẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn. Kí ó baà lè ṣeé ṣe fún un láti tẹ̀ síwájú nínú agbára àtijẹ́rìí rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, o lè dábàá pé kí ó ka Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1985, ojú ìwé 15 sí 25; July 15, 1988, ojú ìwé 9 sí 20; January 15, 1991, ojú ìwé 15 sí 20; àti January 1, 1994, ojú ìwé 20 sí 25.

20 Sún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Síhà Ìyàsímímọ́ àti Batisí: Ó yẹ kí ó ṣeé ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ aláìlábòsí ọkàn láti kọ́ ohun tí ó tó nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, láti ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọ́run, kí ó sì tóótun fún batisí. (Fi wé Ìṣe 8:27-39; 16:25-34.) Bí ó ti wù kí ó rí, kí a tó lè sún ẹnì kan láti ṣe ìyàsímímọ́, ó ní láti mú ìfọkànsìn dàgbà fún Jèhófà. (Sm. 73:25-28) Jálẹ̀ àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, wá àyè láti mú ìmọrírì rẹ̀ dàgbà fún àwọn ànímọ́ Jèhófà. Sọ ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí o ní fún Ọlọ́run jáde. Ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti ronú nípa mímú ipò ìbátan ọlọ́yàyà, ti ara ẹni, dàgbà pẹ̀lú Jèhófà. Bí ó bá mọ Ọlọ́run ní tòótọ́, tí ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, nígbà náà òun yóò fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn Ín, nítorí pé ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú bí a ṣe nímọ̀lára nípa Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan.—1 Tim. 4:7, 8; wo Iwe-Amọna, ojú ìwé 76, ìpínrọ̀ 11.

21 Sapá láti dé inú ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ náà. (Sm. 119:11; Ìṣe 16:14; Rom. 10:10) Ó ní láti rí bí òtítọ́ ṣe kan òun fúnra rẹ̀, kí ó sì pinnu ohun tí ó yẹ kí ó ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ti kọ́. (Rom. 12:2) Ó ha gba òtítọ́ tí a fi ń kọ́ ọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gbọ́ ní ti gidi bí? (1 Tẹs. 2:13) Láti ṣe èyí, o lè dé inú ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ náà nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè tí ń fòye mọ ojú ìwòye, irú bíi: Kí ni èrò rẹ nípa èyí? Báwo ni o ṣe lè lo èyí nínú ìgbésí ayé rẹ? Nípasẹ̀ ìdáhùn rẹ̀, o lè fòye mọ ibi tí o ti nílò ìrànlọ́wọ́ sí i láti dé inú ọkàn rẹ̀. (Luk. 8:15; wo Iwe-Amọna, ojú ìwé 52, ìpínrọ̀ 11.) Àkọlé àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 172 àti 174 nínú ìwé Ìmọ̀ béèrè pé: “O ha ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun nínú àdúrà bí?” àti “Kí ni ó dí ọ lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Èyí lè sún akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́.

22 A ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà tí a ní láti tẹ̀ lé nígbà tí akéde tí kò tí ì ṣe batisí bá ní ìfẹ́ ọkàn láti ṣe batisí sínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 17, ìpínrọ̀ 9. A kọ ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú ète mímú ẹni náà gbara dì láti dáhùn “Awọn Ibeere fun Awọn Wọnni Tí Ifẹ-Ọkan Wọn Jẹ́ Lati Ṣe Iribọmi,” tí ó wà nínú àfikún ẹ̀yìn ìwé Iṣetojọ, tí àwọn alàgbà yóò ṣàtúnyẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀. Bí o bá ti tẹnu mọ́ àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀ sínú ìwé Ìmọ̀, ó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ti gbara dì dáradára fún àkókò ìjókòó fún ìbéèrè tí àwọn alàgbà yóò darí ní ìmúrasílẹ̀ fún batisí rẹ̀.

23 Ran Àwọn Tí Wọ́n Parí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé Lọ́wọ́: Ó yẹ kí a fojú sọ́nà pé nígbà tí ẹnì kan bá fi máa parí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, òótọ́ inú rẹ̀ àti bí ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run ti jinlẹ̀ tó yóò ti hàn kedere. (Mat. 13:23) Ìdí nìyẹn ti ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn nínú ìwé náà fi béèrè pé, “Kí Ni Ìwọ Yóò Ṣe?” Àwọn ìpínrọ̀ tí ó kẹ́yìn rọ akẹ́kọ̀ọ́ náà láti darí àfiyèsí sí ipò ìbátan tí òún ti lè mú dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run, sórí àìní náà láti lo ìmọ̀ tí òún ti kọ́, àti àìní náà láti gbé ìgbésẹ̀ kíámọ́sá láti ṣàṣefihàn ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà. Kò sí ìpèsè fún bíba àwọn tí wọ́n ti parí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìtẹ̀jáde mìíràn. Fi inú rere àti ìṣekedere ṣàlàyé ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ tí kò dáhùn padà sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní láti ṣe láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. O lè máa kàn sí i lóòrèkóòrè, ní ṣíṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún un láti gbé ìgbésẹ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Onw. 12:13.

24 Ọmọ ẹ̀yìn tuntun tí ó tẹ́wọ́ gba òtítọ́, tí ó sì ṣe batisí yóò ní láti mú kí ìmọ̀ àti òye rẹ̀ dàgbà sókè sí i lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ó baà lè dúró ṣinṣin dáradára nínú ìgbàgbọ́. (Kol. 2:6, 7) Dípò bíbá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé rẹ̀ nìṣó lẹ́yìn tí ẹ ti parí ìwé Ìmọ̀, o lè mú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti pèsè ìrànwọ́ ara ẹni èyíkéyìí tí òún lè nílò láti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. (Gal. 6:10; Heb. 6:1) Ní tirẹ̀, ó lè mú kí òye rẹ̀ kún rẹ́rẹ́ sí i nípa kíka Bíbélì lójoojúmọ́, nípa dídá kẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ti ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà, nípa mímúra sílẹ̀ àti lílọ sí àwọn ìpàdé, àti nípa jíjíròrò òtítọ́ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (Mat. 24:45-47; Sm. 1:2; Ìṣe 2:41, 42; Kol. 1:9, 10) Kíka ìwé Iṣetojọ, àti lílo àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀, yóò sa ipa pàtàkì láti mú un ṣètò ara rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣàkóso Ọlọ́run láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní kíkún.—2 Tim. 2:2; 4:5.

25 Mú Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Dàgbà: A ti pàṣẹ fún wa láti ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ní kíkọ́ wọn.’ (Mat. 28:19, 20) Níwọ̀n bí ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti tan mọ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn pẹ́kípẹ́kí, a fẹ́ sakun láti sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. (1 Tim. 4:16; 2 Tim. 4:2) Fún àfikún àbá lórí bí a ṣe lè mú ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa dàgbà sí i, o lè fẹ́ láti ka: “Mimu Ọna Ikọnilẹkọ Dagba-soke” àti “Dide Ọkan Awọn Olugbọ Rẹ” nínú Iwe-Amọna, ìkẹ́kọ̀ọ́ 10 àti 15; “Teacher, Teaching” (Olùkọ́, Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́) nínú ìwé Insight (Gẹ̀ẹ́sì), Ìdìpọ̀ 2; àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà “Kikọle Pẹlu Awọn Ohun-elo Tí Kò Lè Gbiná” àti “Nigba Tí O Bá Nkọni, Dé inu Ọkàn-àyà,” August 15, 1985; “Iwọ Ha Nwòyeronú Lọna Tí Ó Gbéṣẹ́ Lati inu Iwe-mimọ Bi?,” October 15, 1986; àti “Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Nínú Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn,” February 15, 1996.

26 Bí o ti ń sakun láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ní lílo ìwé Ìmọ̀, máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà, ẹni tí “ń mú kí ó máa dàgbà,” bù kún ìsapá rẹ láti dé inú ọkàn àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìhìn rere Ìjọba náà. (1 Kọr. 3:5-7) Ǹjẹ́ kí o nírìírí ayọ̀ ti kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn láti lóye, láti mọrírì, àti láti ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́