Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Ẹni Tí Yóò Fetí Sílẹ̀?
1 Ní ìlú Fílípì, “obìnrin kan báyìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lìdíà, ẹni tí ń ta ohun aláwọ̀ àlùkò, . . . ń fetísílẹ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” (Ìṣe 16:14) Kí ni ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi kọ́ wa? Fífetí sílẹ̀ ni ó ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹnì kan láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àṣeyọrí wa nínú ṣíṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà sinmi ní pàtàkì lórí ìmúratán onílé láti fetí sílẹ̀. Gbàrà tí a bá ti rí ẹni tẹ́tí sílẹ̀, ó túbọ̀ ń rọrùn láti sọ ìhìn iṣẹ́ wa. Ṣùgbọ́n rírí ẹni fetí sílẹ̀ lè jẹ́ ìpèníjà kan. Kí ni a lè ṣe?
2 Ṣáájú nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn, ó yẹ kí á fún ìrísí wa àti àwọn irin iṣẹ́ tí a óò lò ní àfiyèsí. Èé ṣe? Àwọn ènìyàn túbọ̀ ní ìtẹ̀sí láti fetí sílẹ̀ sí ẹnì kan tí ó fi ara rẹ̀ hàn pẹ̀lú iyì. A ha múra lọ́nà tí ó fani mọ́ra, síbẹ̀ tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bí? Bí ìmúra wúruwùru tilẹ̀ lè gbajúmọ̀ nínú ayé, a ń yẹra fún irú àìbìkítà bẹ́ẹ̀ nítorí pé a jẹ́ òjíṣẹ́ tí ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run. Ìrísí wa tí ó mọ́ tónítóní, tí ó sì jẹ́ ti afínjú, ń fi ẹ̀rí rere kún ìhìn iṣẹ́ Ìjọba tí à ń wàásù rẹ̀.
3 Jẹ́ Ẹni Tí Ń Yá Mọ́ni Kí O Sì Fi Ọ̀wọ̀ Hàn: Láìka ìṣarasíhùwà tí ń yí padà lónìí sí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì, wọn yóò sì dáhùn padà lọ́nà rere sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó ní ọ̀wọ̀, tí ó sì jẹ́ ti ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, nípa ohun tí ó wà nínú Bíbélì. Ẹ̀rín músẹ́ ọlọ́yàyà, tí ó sì jẹ́ àtọkànwá, lè mú ara tu onílé, kí ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjíròrò tí ó gbádùn mọ́ni. Òtítọ́ inú àti ìwà rere wa tún yẹ kí ó fara hàn nínú ìsọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa, èyí tí ó kan fífetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sí àwọn ìlóhùnsí onílé.
4 Ète wá jẹ́ láti ṣàjọpín ìrètí Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ó yẹ kí á rí i dájú pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wa ń fani lọ́kàn mọ́ra, kì í ṣe èyí tí ń ṣàtakò tàbí peni níjà. Kò sí ìdí láti fi àkókò ṣòfò ní jíjiyàn pẹ̀lú ẹni tí ó hàn kedere pé ó ń ṣàtakò ni. (2 Tim. 2:23-25) A lè yàn láti inú onírúurú àwọn ìgbékalẹ̀ tí ń fúnni níṣìírí, tí ó sì bá ìgbà mu, tí a pèsè fún wa nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti ìwé Reasoning. Àmọ́ ṣáá o, a ní láti múra ìwọ̀nyí sílẹ̀ dáradára, kí a baà lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìtara, àti lọ́nà tí ń yíni lérò padà.—1 Pet. 3:15.
5 Lẹ́yìn ìkésíni wa, díẹ̀ nínú àwọn onílé ni ó lè rántí gbogbo ohun tí a sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni ó lè rántí ọ̀nà tí a gbà sọ ọ́. A kò gbọdọ̀ fojú tín-ínrín agbára tí ìwà rere àti inú rere ní láé. Dájúdájú, àwọn ẹni-bí-àgùntàn kún inú ìpínlẹ̀ wa, tí wọn yóò fetí sílẹ̀ sí òtítọ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí Lìdíà ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. Fífún ìrísí wa àti ọ̀nà tí a ń gbà sọ̀rọ̀ ní àfiyèsí kínníkínní, lè fún àwọn olóòótọ́ inú níṣìírí láti fetí sílẹ̀ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á lọ́nà rere.—Mak. 4:20.