ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 11/15 ojú ìwé 26-30
  • Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Ọ̀gá Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Ọ̀gá Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Máa Ń Gba Àwọn Èèyàn Níyànjú Láti Sọ Èrò Wọn
  • Jésù Máa Ń Fetí Sílẹ̀ Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
  • Jésù Máa Ń Mọ Ohun Tó Yẹ Kóun Sọ
  • Jésù Kọ́ Àwọn Tó Jẹ́ Ẹni Yíyẹ
  • Jésù Máa Ń Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko
  • Jésù Tẹ́tí Gbọ́rọ̀ Àwọn Ọmọdé
  • Máa Bá A Lọ Ní Títẹ̀lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Bá A Ṣe Lè Dẹni Tó Lẹ́bùn Fífarabalẹ̀ Títẹ́tí Síni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Fetí sí Ohùn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Tìtorí Èyí Ni A Ṣe Rán Mi Jáde”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 11/15 ojú ìwé 26-30

Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Ọ̀gá Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn

“Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”—LÚÙKÙ 8:18.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fiyè sí bí Jésù ṣe bá àwọn èèyàn lò nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù?

JÉSÙ KRISTI tó jẹ́ Olùkọ́ Ńlá àti ọ̀gá nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn sọ ọ̀rọ̀ kan fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ojúṣe rẹ̀ ló sì ń ṣe nígbà tó sọ̀rọ̀ ọ̀hún. Ó ní: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:16-18) Ó yẹ kó o máa tẹ̀ lé ìlànà yẹn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Tó o bá ń fiyè sí àwọn ìtọ́ni tá à ń gbá látinú Bíbélì, wàá lè fi sílò wàá sì lè máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko. Ká sòótọ́, o ò lè gbóhùn Jésù lónìí, àmọ́ o lè kà nípa àwọn ohun tó sọ àtàwọn ohun tó ṣe nínú Bíbélì. Kí làwọn nǹkan wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀nà tó gbà ń bá àwọn èèyàn lò nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù?

2 Jésù jẹ́ oníwàásù tí kò lẹ́gbẹ́, ọ̀nà tó sì ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ta yọ. (Lúùkù 8:1; Jòhánù 8:28) Nǹkan méjì ló wà nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn ni wíwàásù àti kíkọ́ni. Àmọ́, ó máa ń ṣòro fáwọn ará kan tó mọ̀ bá a ṣe ń wàásù dáadáa láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó múná dóko. Wíwàásù ò ju pé kéèyàn kéde ìhìn rere, àmọ́ kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé gba pé kí ẹni tó ń kọ́ni náà mú àwọn tó ń kọ́ lọ́rẹ̀ẹ́. (Mátíù 28:19, 20) Bó ṣe lè ṣe èyí ni pé kó máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Olùkọ́ Ńlá àti ọ̀gá nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn.—Jòhánù 13:13.

3. Tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àǹfààní wo ló máa ṣe fún ọ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?

3 Tó o bá ń kọ́ni lọ́nà tí Jésù gbà ń kọ́ni, ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti ṣe lò ń ṣe yẹn. Ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín. Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:5, 6) Ó gba ìsapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ tó o bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, wàá lè máa kọ́ni lọ́nà tó múná dóko nítorí pé wàá lè “fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan” bó ṣe yẹ.

Jésù Máa Ń Gba Àwọn Èèyàn Níyànjú Láti Sọ Èrò Wọn

4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù jẹ́ni tó máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa?

4 Àtìgbà tí Jésù ti wà ní kékeré ló ti máa ń fetí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀, ó sì máa ń gbà wọ́n níyànjú láti sọ èrò wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, àwọn òbí rẹ̀ rí i láàárín àwọn olùkọ́ nínú tẹ́ńpìlì, “[tó] ń fetí sí wọn, [tó] sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” (Lúùkù 2:46) Kì í ṣe pé Jésù lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ fi ìmọ̀ rẹ̀ dójú ti àwọn olùkọ́ náà o. Ńṣe ló lọ síbẹ̀ láti lọ gbọ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tún bi wọ́n ní ìbéèrè. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jésù ṣe máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa ló mú kó rí ojú rere Ọlọ́run àti èèyàn.—Lúùkù 2:52.

5, 6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń fetí sílẹ̀ nígbà tí àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá ń sọ̀rọ̀?

5 Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi tí Ọlọ́run sì fẹ̀mí yàn án gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, ó ń bá a lọ láti máa fetí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀. Kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó ń sọ ká a lára débi tí kò fi ní jẹ́ káwọn olùgbọ́ rẹ̀ sọ sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà, á dánu dúró, á ní káwọn èèyàn sọ èrò wọn, á sì fetí sí ohun tí wọ́n bá sọ. (Mátíù 16:13-15) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Lásárù arákùnrin Màtá kú, Jésù sọ fún Màtá pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” Ó wá bi Màtá pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Ó sì dájú pé ó fetí sílẹ̀ nígbà tí Màtá fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, Ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.” (Jòhánù 11:26, 27) Ẹ ò rí i pé inú Jésù máa dùn bó ṣe gbọ́ bí Màtá ṣe sọ ohun tó gbà gbọ́ yìí!

6 Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn padà lẹ́yìn Jésù, Jésù fẹ́ gbọ́ èrò àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ló bá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Símónì Pétérù wá fèsì pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòhánù 6:66-69) Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ yẹn mú inú Jésù dùn gan-an ni! Ó sì dájú pé inú ìwọ pẹ̀lú á dùn tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá sọ ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́.

Jésù Máa Ń Fetí Sílẹ̀ Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀

7. Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà nígbàgbọ́ nínú Jésù?

7 Ìdí mìíràn tí Jésù fi ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn ni pé ó ka àwọn èèyàn sí, ó sì máa ń fetí sí wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó ń wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ ará Samáríà lẹ́bàá kànga Jékọ́bù tó wà ní ìlú Síkárì. Òun nìkan kọ́ ló ń sọ̀rọ̀ nígbà tó ń wàásù fún un, kàkà bẹ́ẹ̀ ó gbọ́ ohun tí obìnrin náà fẹ́ sọ. Nígbà tí Jésù ń tẹ́tí sí obìnrin náà, ó kíyè sí i pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn, ó wá sọ fún un pé Ọlọ́run ń wá àwọn tí yóò máa jọ́sìn Rẹ̀ ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́. Jésù fọ̀wọ̀ wọ obìnrin náà ó sì kà á sí, débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lobìnrin yìí lọ ròyìn Jésù fáwọn ẹlòmíì, “ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Samáríà láti ìlú ńlá yẹn [sì] ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ní tìtorí ọ̀rọ̀ obìnrin náà.”—Jòhánù 4:5-29, 39-42.

8. Níwọ̀n bí àwọn èèyàn ti máa ń fẹ́ láti sọ èrò wọn, báwo nìyẹn ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lóde ẹ̀rí?

8 Àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ láti sọ èrò wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará ìlú Áténì ayé ọjọ́un máa ń fẹ́ láti sọ èrò wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ gbọ́ ohun tuntun. Èyí ló mú kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù fún wọn lọ́nà tó múná dóko lórí òkè Áréópágù nílùú náà. (Ìṣe 17:18-34) Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan lóde ẹ̀rí lónìí, o lè sọ pé, “À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa [mẹ́nu kan kókó kan], ẹ jọ̀ọ́ kí lèrò yín nípa rẹ̀?” Fetí sílẹ̀ bó bá ṣe ń sọ èrò rẹ̀, kó o wá sọ nǹkan kan nípa èrò náà tàbí kó o bi í ní ìbéèrè nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà kó o fi ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó náà hàn án.

Jésù Máa Ń Mọ Ohun Tó Yẹ Kóun Sọ

9. Kí ni Jésù kọ́kọ́ ṣe kó tó ‘ṣí Ìwé Mímọ́ payá lẹ́kùn-ún-rẹrẹ fún’ Kíléópà àti ẹnì kejì rẹ̀?

9 Jésù kì í wá ọ̀rọ̀ tó máa sọ tì. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa, ó sábà máa ń mọ ohun táwọn èèyàn ń rò, ó sì máa ń mọ ohun tó yẹ kóun sọ. (Mátíù 9:4; 12:22-30; Lúùkù 9:46, 47) Bí àpẹẹrẹ, láìpẹ́ sígbà tó jíǹde, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì kan ń ti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ẹ́máọ́sì. Ìwé Lúùkù sọ pé: “Bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ pọ̀, tí wọ́n sì ń jíròrò, Jésù fúnra rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn rìn; ṣùgbọ́n a pa ojú wọn mọ́ kúrò nínú dídá a mọ̀. Ó wí fún wọn pé: ‘Kí ni ọ̀ràn wọ̀nyí tí ẹ ń bá ara yín fà bí ẹ ti ń rìn lọ?’ Wọ́n sì dúró jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ojú fífàro. Ní ìdáhùn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíléópà wí fún un pé: ‘Ìwọ ha ń ṣe àtìpó ní Jerúsálẹ́mù nítorí náà tí o kò sì mọ àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?’ Ó sì wí fún wọn pé: ‘Àwọn nǹkan wo?’” Olùkọ́ Ńlá náà fetí sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé pé Jésù ará Násárétì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti pé àwọn èèyàn pa á. Àmọ́ ní báyìí, àwọn kan ń sọ pé ó ti jíǹde. Jésù jẹ́ kí Kíléópà àti ẹnì kejì rẹ̀ sọ èrò wọn. Lẹ́yìn náà, ó wá ṣàlàyé ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀, ó “ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún [wọn] lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”—Lúùkù 24:13-27, 32.

10. Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí ẹni tó o fẹ́ wàásù fún ń rò nípa ọ̀rọ̀ ìjọsìn?

10 O lè má mọ ohun tí ẹni tó o fẹ́ wàásù fún ń rò nípa ọ̀rọ̀ ìjọsìn. Kó o bàa lè mọ̀ ọ́n, o lè sọ fún un pé o máa ń fẹ́ mọ èrò àwọn èèyàn nípa àdúrà. Tó o bá sọ bẹ́ẹ̀ tán, o lè béèrè pé: “Ǹjẹ́ o rò pé ẹnì kan tiẹ̀ wà tó ń gbọ́ àdúrà?” Èsì ẹni náà lè jẹ́ kó o mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa èrò rẹ̀ àti bóyá ó ní ẹ̀sìn tàbí kò ní. Tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, o lè mú kó túbọ̀ sọ èrò rẹ̀ tó o bá bi í pé, “Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́, àbí àwọn kan wà tí kì í gbọ́?” Irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìjíròrò tó lárinrin wáyé. Tó bá yẹ kó o fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí kókó kan hàn án, fọgbọ́n ṣe é, má ta ko ohun tó gbà gbọ́. Tó bá gbádùn ìjíròrò náà, ó lè fẹ́ kó o padà wá. Àmọ́ tó bá béèrè ìbéèrè tó ò lè dáhùn ńkọ́? O lè lọ ṣèwádìí, kó o sì padà lọ láti jẹ́ kó mọ ‘ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú rẹ, kó o sì fi inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ ṣe é.’—1 Pétérù 3:15.

Jésù Kọ́ Àwọn Tó Jẹ́ Ẹni Yíyẹ

11. Kí lo máa ṣe tí wàá fi lè rí àwọn ẹni yíyẹ tó o máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?

11 Jésù ẹni pípé máa ń lo òye, èyí tó fi máa ń mọ àwọn tó yẹ kóun kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣòro gan-an fún àwa láti mọ àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣòro fáwọn àpọ́sítélì tí Jésù sọ fún pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Mátíù 10:11) Ìwọ náà ní láti ṣe bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù, kó o wá àwọn tí wọ́n fẹ́ láti fetí sílẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bó o ṣe lè rí àwọn ẹni yíyẹ ni pé kó o máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tó o bá ń bá sọ̀rọ̀ kó o sì máa kíyè sí ìṣesí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

12. Báwo lo ṣe lè máa bá a lọ láti ran ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ lọ́wọ́?

12 Tó o bá kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tó o bá sọ, á dáa kó o máa ronú nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó yẹ kó mọ̀. Tó o bá ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o kíyè sí lára ẹni tó o wàásù ìhìn rere fún, wàá lè fìyẹn mọ bó o ṣe lè máa kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìṣó. Nígbà tó o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò onítọ̀hún, o ní láti tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa kó o lè túbọ̀ mọ ohun tó gbà gbọ́, èrò rẹ̀ tàbí ipò rẹ̀ nígbèésí ayé.

13. Báwo lo ṣe lè mọ èrò ẹnì kan nípa Bíbélì?

13 Báwo lo ṣe lè mú káwọn èèyàn sọ èrò wọn nípa Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Láwọn ibì kan, àwọn èèyàn máa ń sọ ọ́ téèyàn bá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ rò pé ọ̀rọ̀ Bíbélì tiẹ̀ lè yéèyàn?” Ìdáhùn àwọn èèyàn sí ìbéèrè yìí sábà máa ń fi hàn bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì tàbí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí i. Ọ̀nà míì tó o lè gbà mọ èrò ẹnì kan nípa Bíbélì ni pé kó o ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, kó o wá bi í pé, “Kí lo rò nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ?” Tó o bá ń lo ìbéèrè tó yẹ, o lè ṣàṣeyọrí gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bíi ti Jésù. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan kan wà tó o ní láti ṣọ́ra fún tó o bá ń béèrè ìbéèrè.

Jésù Máa Ń Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko

14. Báwo lo ṣe lè wá ọ̀nà láti mọ èrò àwọn èèyàn láìjẹ́ pé o da ìbéèrè bò wọ́n?

14 Wá ọ̀nà láti mọ èrò táwọn èèyàn ní láìmú kójú tì wọ́n. Àpẹẹrẹ Jésù ni kó o tẹ̀ lé. Jésù kì í da ìbéèrè bo àwọn èèyàn, ńṣe ló kàn máa ń béèrè ìbéèrè tó máa mú kí wọ́n sọ èrò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun táwọn èèyàn bá ń sọ, ó máa ń mú kára tu àwọn olóòótọ́ ọkàn, ó sì máa ń mú kí ọkàn wọn balẹ̀. (Mátíù 11:28) Onírúurú èèyàn ló máa ń lọ bá a láti sọ ìṣòro wọn fún un láìtijú. (Máàkù 1:40; 5:35, 36; 10:13, 17, 46, 47) Bíwọ náà bá fẹ́ káwọn èèyàn máa sọ èrò wọn nípa Bíbélì àti ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ fún ẹ láìtijú, o ní láti rí i pé o kì í da ìbéèrè bò wọ́n.

15, 16. Kí lo lè ṣe láti mú káwọn èèyàn bá ọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìsìn?

15 Yàtọ̀ sí pé kó o máa lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko, o tún lè dá ìjíròrò sílẹ̀ nípa sísọ ohun kan tẹ́ni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ sí, kó o wá fetí sí ohun tó bá sọ. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fún Nikodémù pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Ọ̀rọ̀ yìí ya Nikodémù lẹ́nu débi pé ó fèsì, ó sì tún tẹ́tí gbọ́ ohun tí Jésù sọ. (Jòhánù 3:4-20) Bí ìwọ náà bá ṣe bíi ti Jésù, o lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọ fọ̀rọ̀ wérọ̀.

16 Lóde òní, ibi púpọ̀, títí kan ilẹ̀ Áfíríkà, Ìlà Oòrùn Yúróòpù àtàwọn orílẹ̀-èdè tó wà níhà Gúúsù Amẹ́ríkà, làwọn èèyàn ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé ṣe ń pọ̀ sí i. Nírú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nípa sísọ pé: “Bí ìsìn ṣe pọ̀ gan-an lóde òní ń kọ mí lóminú. Àmọ́ mo nírètí pé láìpẹ́, gbogbo èèyàn ni yóò máa ṣe ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo. Ṣé wàá fẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀?” Tó o bá sọ nǹkan kan tó yani lẹ́nu nípa ìrètí tó o ní, ìyẹn lè mú káwọn èèyàn sọ èrò wọn. Ó sì máa ń túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti dáhùn ìbéèrè tó bá jẹ́ èyí tó ní ìdáhùn méjì téèyàn lè mú ọ̀kan nínú ẹ̀. (Mátíù 17:25) Lẹ́yìn tó o bá ti gbọ́ èsì ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, kó o wá fi ẹsẹ Bíbélì kan tàbí méjì dáhùn ìbéèrè náà. (Aísáyà 11:9; Sefanáyà 3:9) Tó o bá tẹ́tí sí ìdáhùn onítọ̀hún dáadáa, wàá mọ ohun tí wàá bá a sọ nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Jésù Tẹ́tí Gbọ́rọ̀ Àwọn Ọmọdé

17. Kí ló fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé?

17 Àwọn àgbàlagbà nìkan kọ́ ni Jésù nífẹ̀ẹ́ sí o, ó nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọmọdé pẹ̀lú. Ó mọ oríṣiríṣi eré táwọn ọmọdé máa ń ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n máa ń sọ. Ó máa ń pe àwọn ọmọdé sọ́dọ̀ nígbà míì. (Lúùkù 7:31, 32; 18:15-17) Ọ̀pọ̀ ọmọdé wà lára àwọn èèyàn tó ń wá gbọ́rọ̀ Jésù. Nígbà táwọn ọmọdékùnrin ń fohùn rara yin Jésù torí pé ó jẹ́ Mèsáyà, kò ṣàì kíyè sí i, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 14:21; 15:38; 21:15, 16) Lónìí, ọ̀pọ̀ ọmọdé ló ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Báwo lo ṣe máa wá ràn wọ́n lọ́wọ́?

18, 19. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ táá fi dọmọ ẹ̀yìn Jésù?

18 Tó o bá fẹ́ ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè dọmọ ẹ̀yìn, o ní láti máa tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè mọ èrò rẹ̀ tó lè máà bá ìfẹ́ Jèhófà mu. Ohun yòówù kí ọmọdé náà sì sọ, ohun tó dáa ni pé kó o kọ́kọ́ yìn ín. Lẹ́yìn náà, kó o wá lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yẹ láti fi jẹ́ kó mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lójú Jèhófà.

19 O lè lo ìbéèrè láti fi mọ èrò àwọn ọmọdé, àmọ́ báwọn àgbàlagbà ò ṣe fẹ́ kéèyàn máa da ìbéèrè bo àwọn làwọn ọmọdé náà ò ṣe fẹ́. Dípò tí wàá fi da ìbéèrè bo ọmọ rẹ, o lè kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ ṣókí kan fún un nípa ara rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ irú èrò tó o máa ń ní nígbà kan rí àti ìdí tó o fi nírú èrò bẹ́ẹ̀, ìyẹn tọ́rọ̀ yín bá jẹ mọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kó o wá bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń ní irú èrò yẹn?” Ìdáhùn rẹ̀ lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún yín láti jọ sọ̀rọ̀ lórí kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó máa ràn án lọ́wọ́.

Máa Bá A Lọ Ní Títẹ̀lé Àpẹẹrẹ Jésù

20, 21. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa fetí sílẹ̀ dáadáa bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?

20 Yálà ọmọ rẹ lò ń bá sọ̀rọ̀ tàbí ẹlòmíì, ó ṣe pàtàkì kó o máa tẹ́tí gbọ́ni dáadáa. Ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tó o bá ń fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ nìyẹn jẹ́, yóò sì tún fi hàn pé o kà wọ́n sí àti pé ò ń gba ti wọ́n rò. Láìsí àní-àní, kó o tó lè sọ pé o tẹ́tí gbọ́rọ̀ ẹnì kan, o ní láti máa fọkàn bá ohun tó ń sọ lọ.

21 Bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀. Tó o bá ń fiyè sí ohun tí wọ́n ń sọ, wàá lè mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ sí jù. Kó o sì wá lo onírúurú ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ ọ̀gá nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni Jésù ṣe láti mú káwọn èèyàn sọ èrò wọn?

• Kí nìdí tí Jésù fi máa ń tẹ́tí gbọ́rọ̀ àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?

• Báwo lo ṣe lè máa lo ìbéèrè lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

• Kí lo lè ṣe láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ kí wọ́n lè dọmọ ẹ̀yìn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Rí i dájú pé ò ń tẹ́tí sáwọn èèyàn tó ò ń wàásù fún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé nígbà tá a bá ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti dọmọ ẹ̀yìn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́