Bá A Ṣe Lè Dẹni Tó Lẹ́bùn Fífarabalẹ̀ Títẹ́tí Síni
“Ẹ ṢÉ gan-an pé ẹ fara balẹ̀ gbọ́ mi.” Ǹjẹ́ a rẹ́ni tó dúpẹ́ báyìí lọ́wọ́ rẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn mà dára o! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló mọrírì ẹni tó bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí síni. Bá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn tó wà nínú ìpọ́njú tàbí àwọn tó wà nínú ìṣòro, ìyẹn á jẹ́ kára tù wọ́n. Tẹ́nì kan bá sì jẹ́ ẹni tó ń fara balẹ̀ tẹ́tí síni, ǹjẹ́ àwọn èèyàn ò ní fẹ́ràn onítọ̀hún? Fífarabalẹ̀ tẹ́tí síni jẹ́ ara ọ̀nà pàtàkì tá a fi ń “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà” nínú ìjọ Kristẹni.—Hébérù 10:24.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ bá a ṣe ń tẹ́tí síni rárá. Dípò kí wọ́n gbọ́ ohun tí ẹlòmíì fẹ́ sọ, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí fún un nímọ̀ràn tàbí kí wọ́n máa sọ ìrírí tiwọn tàbí èrò tiwọn. Ẹ̀bùn ni o láti mọ bá a ṣe ń tẹ́tí síni. Àmọ́ báwo la ṣe lè dẹni tó mọ bá a ṣe ń fara balẹ̀ tẹ́tí síni?
Ohun Kan Tó Ṣe Pàtàkì
Jèhófà ni “Olùkọ́ni [wa] Atóbilọ́lá.” (Aísáyà 30:20) Ó lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ nípa bá a ṣe lè tẹ́tí síni. Wo bí Jèhófà ṣe ran wòlíì Èlíjà lọ́wọ́. Nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba halẹ̀ mọ́ Èlíjà, ẹ̀rù bà á ó sì sá lọ sí aginjù, ó ní ó tiẹ̀ sàn kóun kú. Áńgẹ́lì Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Nígbà tí wòlíì yìí ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ó sì fi agbára ńlá rẹ̀ hàn án. Kí ló yọrí sí? Ẹ̀rù tó ń ba Èlíjà fò lọ, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. (1 Àwọn Ọba 19:2-15) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń tẹ́tí gbọ́ ẹ̀dùn ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? Torí pé ó bìkítà nípa wọn ni. (1 Pétérù 5:7) Ohun pàtàkì tó lè sọ wá dẹni tó ń fara balẹ̀ tẹ́tí síni nìyẹn o, ìyẹn ni pé ká máa bìkítà nípa àwọn èèyàn kí ire wọn sì jẹ wá lógún.
Nígbà tí ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè Bolivia dẹ́ṣẹ̀ ńlá kan, inú rẹ̀ dùn gan-an pé ire òun jẹ ẹnì kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tòun lógún. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ara mi ti sú mi pátápátá nígbà yẹn. Bóyá ni ǹ bá sin Jèhófà mọ́ bí kì í bá ṣe ti arákùnrin kan tó fara balẹ̀ gbọ́ mi. Kò sọ̀rọ̀ lọ títí o, àmọ́ bó ṣe tẹ́tí gbọ́ mi yẹn lásán fún mi lókun gan-an. Kì í ṣe pé mò ń fẹ́ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ohun tó yẹ kí n ṣe; èmi fúnra mi mọ̀ ọ́n. Ohun tí mo kàn ń fẹ́ ni pé kí n ṣáà rẹ́ni tó máa gbọ́ ẹ̀dùn ọkàn mi. Bó ṣe tẹ́tí gbọ́ mi yẹn ló mú kí ẹ̀dùn ọkàn mi fò lọ.”
Ní ti ká fara balẹ̀ tẹ́tí síni, Jésù Kristi jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà. Láìpẹ́ sígbà tí Jésù kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì ń ti Jerúsálẹ́mù lọ sí abúlé kan tó tó kìlómítà mọ́kànlá sí Jerúsálẹ́mù. Láìsí àní-àní, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá wọn. Jésù Kristi tó ti jíǹde nígbà náà wá ń bá wọn rìn lọ. Ó fọgbọ́n bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní ìbéèrè láti fi jẹ́ kí wọ́n sọ èrò ọkàn wọn, àwọn náà sì fèsì. Wọ́n ṣàlàyé ìrètí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, bí ìjákulẹ̀ ṣe bá wọn àti bí gbogbo nǹkan ṣe dà rú mọ́ wọn lójú báyìí. Jésù ṣaájò àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì náà ó sì fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ wọn, èyí tó mú káwọn náà fẹ́ gbọ́rọ̀ tirẹ̀ pẹ̀lú. Jésù wá “túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.”—Lúùkù 24:13-27.
Ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tá a lè gbà mú káwọn èèyàn tẹ́tí gbọ́ wa ni pé ká kọ́kọ́ tẹ́tí gbọ́rọ̀ tiwọn. Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Bolivia sọ pé: “Àwọn òbí mi àtàwọn òbí ọkọ mi ò fara mọ́ bí mo ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ mi. Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ rárá, síbẹ̀ kò dá mi lójú pé mò ń ṣe ojúṣe mi bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bí òbí. Àárín ìgbà yẹn ni obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sọ́dọ̀ mi. Ó bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run. Àmọ́, bó ṣe ń béèrè èrò mi nípa ọ̀rọ̀ tó ń sọ jẹ́ kí n rí i pé ó jẹ́ ẹni tó máa tẹ́tí gbọ́rọ̀ mi. Mo bá ní kó wọlé. Bó sì ṣe wọlé, mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìṣòro mi fún un. Ó fara balẹ̀ gbọ́ mi. Ó béèrè irú ìgbésí ayé tí mò ń fẹ́ fáwọn ọmọ mi àti ohun tí ọkọ mi rò nípa rẹ̀. Ara tù mí gan-an ni pé mo rẹ́ni tó gbìyànjú láti gbọ́ mi yé. Nígbà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tí Bíbélì sọ nípa ètò ìdílé hàn mí, ọkàn mi balẹ̀ pé mo ti rí ẹni tó bìkítà nípa mi.”
Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Èyí fi hàn pé tá a bá fẹ́ fara balẹ̀ tẹ́tí síni, ńṣe ló yẹ ká pa ohun tá à ń ṣe tì ná ká gbọ́ tonítọ̀hún. Táwọn èèyàn bá ń bá wa sọ̀rọ̀ pàtàkì, ó lè gba pé ká pa tẹlifíṣọ̀n, ká gbé ìwé ìròyìn tá à ń kà sílẹ̀ tàbí ká pa tẹlifóònù alágbèéká wa. Tá a bá ń tẹ́tí síni, ohun tónítọ̀hún ń sọ fún wa ló yẹ kó jẹ wá lógún. Tó fi hàn pé a ò ní máa sọ irú ọ̀rọ̀ bíi, “Ó mú mi rántí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà kan báyìí,” láti fi gbé ọ̀rọ̀ tiwa wọnú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lóòótọ́ o, kò burú láti ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá jọ ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, àmọ́ tẹ́nì kan bá ń bá wa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, ńṣe ló yẹ ká ṣì gbé ọ̀rọ̀ tara wa tì ná. Ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà fi hàn pé ire àwọn ẹlòmíì jẹ wá lógún.
Fetí Sílẹ̀ Lọ́nà Tí Wàá Fi Mọ Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹlòmíràn
Ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá làwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù gbọ́rọ̀ lẹ́nu Jóòbù. Ṣùgbọ́n Jóòbù ṣì kédàárò pé: “Ì bá ṣe pé mo ní ẹnì kan tí yóò fetí sí mi!” (Jóòbù 31:35) Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò rí ìtura kankan nínú gbígbọ́ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọn ò bìkítà nípa Jóòbù, wọn ò sì fẹ́ mọ bí ohun tó ń sọ ṣe rí lára rẹ̀ rárá. Wọn ò lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn tí ì bá jẹ́ kí wọ́n fọ̀rọ̀ tó ń sọ fún wọn ro ara wọn wò. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pétérù gbà wá ni pé: “Lakotan, ki gbogbo yin jẹ́ onínú kan, ẹ maa bá ara yin kẹ́dùn ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 3:8, Bíbélì Yoruba Atọ́ka) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn? Ọ̀nà kan ni pé ká máa fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara wa wò, ká sì gbìyànjú láti gbọ́ wọn yé. Tá a bá ń sọ ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn bíi, “irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dunni” tàbí “ó dà bíi pé wọn ò gbọ́ ẹ yé,” yóò fi hàn pé à ń ṣaájò ẹni tó ń bá wa sọ̀rọ̀. Ọ̀nà míì ni pé ká tún àlàyé onítọ̀hún sọ lọ́rọ̀ ara wa, èyí tí yóò fi hàn pé ohun tó sọ yé wa. Tá a bá ń tẹ́tí síni tìfẹ́tìfẹ́, ọ̀rọ̀ ẹni náà nìkan kọ́ la ó máa fiyè sí, a ó tún máa kíyè sí bí ohun tó ń sọ ṣe rí lára òun fúnra rẹ̀.
Roberta jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Nígbà kan, ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Mo wá lọ bá alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó fara balẹ̀ gbọ́ mi, ó sì gbìyànjú láti mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára mi. Ó tiẹ̀ jọ pé ó mọ̀ pé mò ń bẹ̀rù bóyá òun máa bá mi wí. Ó wá fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì, àti pé ó ti ṣe òun náà bẹ́ẹ̀ rí. Ìyẹn fún mi lókun gan-an, mo sì ń bá iṣẹ́ náà lọ.”
Tẹ́nì kan bá ń sọ ohun kan tá ò fara mọ́ fún wa, ǹjẹ́ a ṣì lè tẹ́tí sí ohun tó ń sọ? Ǹjẹ́ a lè sọ fún èèyàn pé inú wa dùn pé ó tiẹ̀ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún wa? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bí ọmọ wa ọkùnrin kékeré bá jà níléèwé ńkọ́ tàbí kí ọ̀dọ́mọbìnrin wa ṣàdédé wọlé dé lọ́jọ́ kan kó ní ọmọkùnrin kan wu òun, òun sì fẹ́ fẹ́ ẹ? Ǹjẹ́ kò ní dára kí òbí kọ́kọ́ tẹ́tí gbọ́ ọmọ náà kó sì gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ àlàyé nípa ìwà tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́?
Ìwé Òwe 20:5 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yóò fà á jáde.” Bí ọlọ́gbọ́n èèyàn kan tó nírìírí kò bá fẹ́ fún wa nímọ̀ràn láìjẹ́ pé a sọ pé kó fún wa, ńṣe ló yẹ ká wá ọgbọ́n tá a ó fi mú kó sọ̀rọ̀. Bákan náà ni ọ̀rọ̀ fífarabalẹ̀ tẹ́tí síni rí. Ó gba òye láti mú kí ẹlòmíì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde. Tá a bá ń béèrè ìbéèrè, ó máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n a ní láti ṣọ́ra kó má di pé a lọ ń ṣàtojúbọ̀ nínú ohun tí ò kàn wá. Nígbà míì, ó máa dára ká sọ pé kí ẹni tó fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ara ohun tó rọ̀ ọ́ lọ́run jù lọ láti sọ. Bí àpẹẹrẹ, tí aya kan bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro ìdílé rẹ̀, ó lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bóun àti ọkọ rẹ̀ ṣe fẹ́ra wọn. Tó bá sì jẹ́ ẹni tí kì í jáde òde ẹ̀rí mọ́ ni, ó lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ látorí bó ṣe rí òtítọ́.
Kì Í Rọrùn Láti Fara Balẹ̀ Tẹ́tí Síni
Kì í rọrùn láti fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹnì kan tó ń bínú sí wa, torí pé kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ dá ara rẹ̀ láre. Kí la lè ṣe? Ìwé Òwe 15:1 sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” Ọ̀nà kan láti gbà dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́ sì ni pé ká fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ fún onítọ̀hún pé kó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ ká sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i bó ṣe ń sọ ọ́.
Táwọn èèyàn méjì bá ń pariwo mọ́ra wọn, tá a bá kíyè sí ọ̀rọ̀ wọn, a ó rí i pé ọ̀rọ̀ tí kálukú wọn ti sọ tẹ́lẹ̀ ni wọ́n kàn ń sọ lásọtúnsọ. Ẹnì kìíní á máa wò ó pé ẹnì kejì ò fetí sí ọ̀rọ̀ òun. Ì bá mà dára o ká ní ọ̀kan lára wọn lè dákẹ́ kó gbọ́ ẹnì kejì yé! Ohun kan ṣe pàtàkì ṣá o, ìyẹn ni pé ó yẹ kéèyàn máa kó ara rẹ̀ níjàánu kó sì máa sọ̀rọ̀ olóye àti onífẹ̀ẹ́. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”—Òwe 10:19.
Kì í ṣe ìwà àbínibí ènìyàn láti máa fara balẹ̀ tẹ́tí síni. Àmọ́ a lè dẹni tó mọ̀ ọ́n ṣe tá a bá sapá gidigidi láti fi kọ́ra. Ànímọ́ tó sì dára láti ní ni. Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni tó ń bá wa sọ̀rọ̀, èyí á fi hàn pé a fẹ́ràn onítọ̀hún. Yóò tún fún wa láyọ̀ pẹ̀lú. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an ni pé ká ní ẹ̀bùn fífarabalẹ̀ tẹ́tí síni!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Tẹ́nì kan bá ń bá wa sọ́rọ̀, ńṣe ló yẹ ká pa ohun tá à ń ṣe tì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kì í rọrùn láti tẹ́tí sí ẹnì kan tó ń bínú sí wa