ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 9/8 ojú ìwé 30
  • Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́
  • Jí!—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Dẹni Tó Lẹ́bùn Fífarabalẹ̀ Títẹ́tí Síni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Ọ̀gá Nínú Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀”
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Apa 1
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jí!—2002
g02 9/8 ojú ìwé 30

Fetí Sílẹ̀ kó o sì Kẹ́kọ̀ọ́

ÌRÒYÌN kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Nípa fífetí sílẹ̀ la fi mọ ìdá márùnlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun tá a mọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú àkókò wa la máa ń fi fetí sílẹ̀ sí nǹkan, “ìdá márùnléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àkókò ọ̀hún ló jẹ́ pé ibòmíràn lọkàn wa máa ń wà, tá ó máa ro nǹkan mìíràn tàbí ká má tiẹ̀ rántí ohun tá a gbọ́.” Àwọn ìsọfúnni yíyanilẹ́nu wọ̀nyí jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ ṣiṣẹ́ lórí bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, “àìmọ béèyàn ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀ ló wà nídìí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bẹ láwùjọ.” Rebecca Shafir, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti ọ̀mọ̀ràn nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ sọ pé, ìṣòro yìí ló sábà máa ń fa fífọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni, ìwà ipá ilé ẹ̀kọ́, bí ìdílé ṣe ń túká, àti lílo oògùn olóró.

Àwọn onímọ̀ nípa àwùjọ ẹ̀dá èèyàn sọ pé, ọ̀nà tí àwa èèyàn gbà ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́, tí wọ́n á sì fẹ́ mọ gbogbo fìn-ín ìdí kókò tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn kan sì rèé, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni wọ́n máa ń fẹ́ mọ̀, tí wọ́n á sì máa fẹ́ kí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà tètè lọ sórí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwé ìròyìn Star wá sọ pé: “Ohun tá a lè sọ nípa ẹgbẹ́ méjèèjì yìí ni pé ọ̀rọ̀ wọn lè máà yéra wọn.”

Abájọ tí Jésù fi tẹnu mọ́ kókó náà pé, “ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Títẹ́tísílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀ fi ìwà ọmọlúwàbí hàn. Ó sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjíròrò. Lára àwọn ìdámọ̀ràn díẹ̀ tó wúlò nípa béèyàn ṣe lè tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni, ṣíṣàìjẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹni níyà, títẹ orí síwájú díẹ̀, fífi ojú dáhùn padà nípa wíwo ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà lójú, àti mími orí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti fi hàn pé ò ń lóye onítọ̀hún. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ohun tí à ń kọ́ ti sinmi lórí fífetísílẹ̀ dáadáa, fífiyè sílẹ̀ jẹ́ ohun tó yẹ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti ṣiṣẹ́ lé lórí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́