“Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀”
FÍFETÍSÍLẸ̀ ṣe pàtàkì gan-an nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́. Ó tún lè pinnu bóyá ẹnì kan á yè bọ́ tàbí kò ní yè bọ́. Nígbà tí Jèhófà ń múra láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Íjíbítì, ó fún Mósè ní àwọn ìtọ́ni, Mósè wá sọ fún àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì nípa ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò ṣe láti dáàbò bo àkọ́bí ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ áńgẹ́lì aṣekúpani. (Ẹ́kís. 12:21-23) Àwọn àgbààgbà sì mú ìsọfúnni yìí tọ olúkúlùkù agboolé lọ. Ẹnu ni wọ́n fi sọ ọ́ o. Ńṣe làwọn èèyàn yẹn ní láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wọn. Ìhà wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kọ sí i? Bíbélì ròyìn pé: “Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè àti Áárónì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Ẹ́kís. 12:28, 50, 51) Nípa bẹ́ẹ̀, Ísírẹ́lì rí ìdáǹdè àgbàyanu gbà.
Lóde òní, ìdáǹdè tó tilẹ̀ tún ga ju ìyẹn lọ ni Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ fún. Dájúdájú, ìtọ́ni tó ń pèsè yẹ fún àfiyèsí wa lójú méjèèjì. A máa ń gba irú ìtọ́ni yìí ní àwọn ìpàdé ìjọ. Ǹjẹ́ ò ń jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú irú àwọn ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó sinmi púpọ̀ lórí bí o ṣe ń fetí sílẹ̀ sí.
Ǹjẹ́ o máa ń rántí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìtọ́ni tí a máa ń gbà ní ìpàdé bí? Ṣé ó ti mọ́ ọ lára láti máa wá ọ̀nà láti fi ìtọ́ni tí o bá gbà sílò déédéé nínú ìgbésí ayé rẹ tàbí kí o sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀?
Múra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀
Ká tó lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú ìtọ́ni tá à ńrí gbà nínú àwọn ìpàdé Kristẹni, a ní láti múra ọkàn wa sílẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣàkóso Jèhóṣáfátì ọba Júdà túbọ̀ jẹ́ ká rí bí ìyẹn ti ṣe pàtàkì tó. Jèhóṣáfátì fi hàn pé gbágbáágbá lòun ti ìsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Ó “mú àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ kúrò ní Júdà,” ó sì yan àwọn olórí, àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà káàkiri gbogbo ìlú Júdà. Síbẹ̀, “àwọn ibi gíga kò di àwátì.” (2 Kíró. 17:6-9; 20:33) Ìdí ni pé ìbọ̀rìṣà àti ìjọsìn àìbófinmu tí wọ́n ń ṣe sí Jèhófà ní àwọn ojúbọ tó wà níbi gíga ti mọ́ àwọn èèyàn náà lára gan-an tó fi jẹ́ pé wọn kò pa á rẹ́ pátápátá.
Kí nìdí tí ìtọ́ni tí Jèhóṣáfátì ṣètò pé kí wọ́n fún wọn kò fi pẹ́ lọ́kàn wọn? Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Àwọn ènìyàn náà kò sì tíì múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.” Kì í ṣe pé wọn ò kúkú gbọ́, wọn ò kàn ṣiṣẹ́ lé e lórí ni. Bóyá wọ́n rò pé lílọ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù láti máa rúbọ ń fún àwọn ní wàhálà. Lọ́nà kan ṣáá, wọn ò ní ìgbàgbọ́ tó lè sún ọkàn wọn ṣiṣẹ́.
Kí a má bàa di ẹni tó rìn kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ padà sínú àwọn ọ̀nà ayé Sátánì, a ní láti múra ọkàn wa sílẹ̀ láti gba ìtọ́ni tí Jèhófà ń pèsè lóde òní. Lọ́nà wo? Ọ̀nà pàtàkì kan jẹ́ nípa àdúrà gbígbà. A ní láti gbàdúrà pé kí a lè fi ẹ̀mí ọpẹ́ gba ìtọ́ni tí Ọlọ́run ń pèsè. (Sm. 27:4; 95:2) Èyí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì akitiyan tí àwọn arákùnrin wa ń ṣe, àwọn tó jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì yọ̀ǹda ara wọn pé kí Jèhófà lò wọ́n láti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ìyẹn á mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn nǹkan tuntun tí a ń rí kọ́, yóò tún mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àǹfààní tí a ní láti lè mú kí ìmọrírì wa fún àwọn nǹkan tí a ti kọ́ tẹ́lẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Bí a sì ṣe ń fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní kíkún, a ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. . . . Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Sm. 86:11.
Pọkàn Pọ̀ Sọ́nà Kan
Ohun púpọ̀ ló lè dí wa lọ́wọ́ ká má lè fetí sílẹ̀ dáadáa. Àwọn àníyàn ayé lè gbà wá lọ́kàn. Ariwo àti ìrìnsókèsódò láàárín ìpàdé tàbí ní ìta ilé ìpàdé lè fa ìpínyà ọkàn fún wa. Ìnira inú ara wa lè jẹ́ kí ó ṣòro fún wa láti pọkàn pọ̀. Àwọn tó ní ọmọ kékeré sábà máa ń rí i pé ó lè fa ìpínyà ọkàn fún àwọn. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń lọ lọ́wọ́?
Ojú sábà máa ń nípa gidigidi lórí ibi tí a máa pe àfiyèsí wa sí. Lo ojú rẹ lọ́nà tí yóò fi ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ nípa ṣíṣàìyíjú kúrò lọ́dọ̀ olùbánisọ̀rọ̀. Bí ó bá pe orí tàbí ẹsẹ Bíbélì kan, ì báà tiẹ̀ jẹ́ èyí tó o ti mọ̀, ṣí i, kí o sì máa fojú bá a lọ bí ó ṣe ń kà á. Má gbà kí ohunkóhun mú ọ máa yíjú wo gbogbo ibi tí o bá ti gbọ́ ariwo tàbí ibi tí nǹkan kan ti ń kọjá. Bí wíwòhín-wọ̀hún bá ń mú kí ọkàn rẹ pínyà, o ò ní gbọ́ ọ̀pọ̀ lára ohun tó ń lọ lórí pèpéle.
Bí ‘ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè’ bá mú kó ṣòro fún ọ láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń lọ lọ́wọ́, gbàdúrà sí Jèhófà fún ìbàlẹ̀ ọkàn tí yóò mú kí o lè pọkàn pọ̀. (Sm. 94:19; Fílí. 4:6, 7) Gbàdúrà yẹn lemọ́lemọ́ bó bá gbà bẹ́ẹ̀. (Mát. 7:7, 8) Àwọn ìpàdé ìjọ jẹ́ ìpèsè Jèhófà. Kí ó dá ọ lójú pé ó ń fẹ́ kí o jàǹfààní wọn.—1 Jòh. 5:14, 15.
Fífetísílẹ̀ sí Àwọn Àsọyé
Ó ṣeé ṣe kí o rántí kókó kan tó o ti gbọ́ rí nínú àsọyé, tó sì wù ọ́. Àmọ́ o, fífetísílẹ̀ sí àsọyé kò mọ sí kìkì gbígbọ́ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ nìkan. Bí ẹní ń rin ìrìn àjò ni àsọyé ṣe rí. Èèyàn lè máa rí ohun tó wuni lọ́nà bó ṣe ń lọ, àmọ́ ibi tó ń lọ gan-an ló ṣe pàtàkì, ìyẹn ni ohun tó ń lépa. Bí ó ti rí nìyẹn pẹ̀lú ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ kan ń lépa. Ó lè máa gbìyànjú láti gbin èrò kan sí àwùjọ lọ́kàn, ó sì lè fẹ́ sún wọn láti ṣe ohun kan.
Gbé ọ̀rọ̀ tí Jóṣúà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ nínú Jóṣúà 24:1-15 yẹ̀ wò. Ète tó ní lọ́kàn ni láti mú kí àwọn èèyàn náà rọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́ tímọ́tímọ́, pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀? Pípọ̀ tí ìsìn èké pọ̀ níbẹ̀ jẹ́ ewu gidigidi fún àjọṣe dídánmọ́rán tó wà láàárín orílẹ̀-èdè yẹn àti Jèhófà. Àwọn èèyàn yẹn sì dáhùn sí rírọ̀ tí Jóṣúà ń rọ̀ wọ́n, wọ́n ní: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀ láti lè sin àwọn ọlọ́run mìíràn. . . . Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn!—Jóṣ. 24:16, 18, 31.
Bí o bá ń gbọ́ àsọyé kan, gbìyànjú láti lóye ohun tí ọ̀rọ̀ náà ń fẹ́ kéèyàn ṣe. Ronú lórí bí àwọn kókó tí olùbánisọ̀rọ̀ ń mú jáde ṣe ń ṣàlàyé bí èèyàn ṣe lè ṣe ohun yẹn. Bi ara rẹ̀ léèrè nípa ohun tí ìsọfúnni náà ń sọ pé kó o ṣe.
Fífetísílẹ̀ Nígbà Ìjíròrò
A máa ń bójú tó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, àti àwọn apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tó dá lórí àpilẹ̀kọ tí a gbé karí Bíbélì.
Ní àwọn ọ̀nà kan, fífetísílẹ̀ nígbà ìjíròrò dà bí ìgbà téèyàn ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Láti lè jàǹfààní ní kíkún, fetí sílẹ̀ dáadáa. Kíyè sí apá ibi tí ìjíròrò yẹn ń lọ. Ṣàkíyèsí bí olùdarí ìjíròrò náà ṣe ń tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àti àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀. Máa fọkàn dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó bá béèrè. Fetí sílẹ̀ láti gbọ́ bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ń ṣàlàyé àpilẹ̀kọ náà tí wọ́n sì ń sọ bí a ṣe le fi í sílò. Mímọ bí àwọn ẹlòmíràn ṣe lóye ìsọfúnni náà sì lè jẹ́ kí o tún rí ọ̀nà mìíràn tí o tún lè gbà lóye ẹ̀kọ́ kan tó o mọ̀ tẹ́lẹ̀. Lóhùn sí ìjíròrò náà, kí o sọ ohun tí ìwọ náà gbà gbọ́.—Róòmù 1:12.
Kíka ibi tí a yàn fún ìjíròrò ṣáájú yóò jẹ́ kí ìjíròrò náà wọ̀ ọ́ lára, kí o sì lè lóye àlàyé tí àwọn mìíràn ń ṣe. Bí ipò nǹkan tó yí ọ ká bá mú kó ṣòro fún ọ láti ka àpilẹ̀kọ náà kúnnákúnná, ó kéré tán rí i pé o lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi yẹ ìsọfúnni náà wò gààràgà ṣáájú ìpàdé náà. Tó o bá ṣe èyí, wàá túbọ̀ jèrè sí i nínú ìjíròrò náà.
Fífetísílẹ̀ ní Àwọn Àpéjọ
Àwọn ohun tó ń fa ìpínyà ọkàn ṣeé ṣe kó tilẹ̀ tún pọ̀ ní àwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká, àti àgbègbè ju ti ìpàdé ìjọ lọ. Èyí lè mú kí fífetísílẹ̀ túbọ̀ ṣòro gan-an. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?
Kókó pàtàkì kan ni pé kéèyàn rí i pé òun sùn dáadáa ní òru. Kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, fi ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà sọ́kàn. Wo àkòrí àsọyé kọ̀ọ̀kan, kí o sì gbìyànjú láti fọkàn ro ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n lè fẹ́ sọ nípa rẹ̀. Ṣí ẹsẹ Bíbélì tí a bá pè. Ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì ní ṣókí máa ń jẹ́ kí àwọn lè pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìtọ́ni tó o wéwèé láti lò nínú ìgbésí ayé rẹ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Jíròrò àwọn kókó mélòó kan bó o ṣe ń lọ tó ò ń bọ̀ láti ibi ìpàdé lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Èyí yóò jẹ́ kí o lè rántí ìsọfúnni náà.
Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Láti Máa Fetí Sílẹ̀
Àwọn Kristẹni òbí lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ wọn, títí kan àwọn ọmọ jòjòló pàápàá, láti dẹni tó di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà” nípa mímú wọn wá sí àwọn ìpàdé ìjọ, àti àpéjọ àkànṣe, ti àyíká àti ti àgbègbè. (2 Tím. 3:15) Nígbà tó jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà nínú ìtẹ̀sí ọkàn àwọn ọmọdé àti bí wọ́n ṣe lè pọkàn pọ̀ pẹ́ tó, ó gba òye láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Àwọn ìdámọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí lè wúlò fún ọ.
Ní ilé, yan àkókò tí àwọn ọmọ rẹ kéékèèké yóò máa jókòó jẹ́ẹ́ láti ka àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni wa tàbí kí wọ́n máa wo àwòrán inú rẹ̀. Bó o bá sì dé ìpàdé, má kàn ṣáà gbé ohun kan lé wọn lọ́wọ́ láti máa fi ṣeré nítorí kí wọ́n má bàa yọ ẹ lẹ́nu. Bó ṣe rí ní Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ náà ló ṣe rí lóde òní, pé ńṣe ni àwọn ọmọ kéékèèké wà níbẹ̀ “kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.” (Diu. 31:12) Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn òbí tilẹ̀ máa ń fún àwọn ọmọ kéékèèké ní ẹ̀dà tiwọn lára ìwé tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́. Bí àwọn ọmọ bá ti dàgbà díẹ̀ sí i, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ kí wọ́n lè kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bá ń béèrè fún ìlóhùnsí látọ̀dọ̀ àwùjọ.
Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká rí ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ tí ń bẹ láàárín fífetí sí Jèhófà àti ṣíṣègbọràn sí i. A lè rí èyí látinú ọ̀rọ̀ tí Mósè bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ, pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè . . . nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Diu. 30:19, 20) Lóde òní, fífetí sí ìtọ́ni tí Jèhófà pèsè àti ṣíṣe ìgbọràn nípa mímú un lò nínú ìgbésí ayé wa ṣe pàtàkì gan-an bí èèyàn yóò bá rí ojú rere Ọlọ́run, kéèyàn sì rí ìbùkún ìyè ayérayé gbà. Nígbà náà, ó mà ṣe pàtàkì o, pé ká kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìṣítí tí Jésù sọ, pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀”!—Lúùkù 8:18.