ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 5
  • ‘Ẹ Fetí Sílẹ̀ Kí Ẹ sì Gba Ìtọ́ni Púpọ̀ Sí I’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Fetí Sílẹ̀ Kí Ẹ sì Gba Ìtọ́ni Púpọ̀ Sí I’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fetí sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Fetí Sílẹ̀ Kó O sì Kẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • A Péjọ Pọ̀ Láti Yin Jèhófà Lógo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 5

‘Ẹ Fetí Sílẹ̀ Kí Ẹ sì Gba Ìtọ́ni Púpọ̀ Sí I’

1 Ìwé Òwe ṣàpèjúwe ọgbọ́n pé ó ń ké jáde pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, nítorí àwọn ohun àkọ́kọ́ ni mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ṣíṣí ètè mi sì jẹ́ nípa ìdúróṣánṣán. Mo ní ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n gbígbéṣẹ́. . . . Ẹ fetí sí mi; bẹ́ẹ̀ ni, àní aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́. Nítorí ẹni tí ó bá rí mi yóò rí ìyè dájúdájú, yóò sì rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Òwe 8:6, 14, 32, 35) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣàpèjúwe ìtọ́ni táa máa rí gbà ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

2 A ti ṣàyẹ̀wò kínníkínní nípa ohun tí ń fẹ́ àbójútó láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé, a sì ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ yìí láti bójú tó nǹkan wọ̀nyẹn. Bí a bá fi àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí àti àbá gbígbéṣẹ́ tí àpéjọpọ̀ náà yóò pèsè sílò, ó lè mú wa láyọ̀, yóò mú kí a lè máa ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, yóò sì mú kí a máa bá a lọ ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Dájúdájú, ó yẹ gidigidi pé kí á ‘fetí sílẹ̀ kí á sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.’—Òwe 1:5.

3 Kí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tó Bẹ̀rẹ̀: Láti lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ohun tí wọ́n á bá wa sọ níbẹ̀, ó yẹ kí á ti wà lórí ìjókòó wa kí a sì pọkàn pọ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá bẹ̀rẹ̀. Èyí ń béèrè pé kí olúkúlùkù ṣètò ara rẹ̀ dáadáa. Kókó pàtàkì kan ni pé kéèyàn tètè bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ẹ tètè lọ sùn ní alẹ́ ìpàdé ku ọ̀la. Ẹ tètè jí kí gbogbo ìdílé lè ní àkókò tí ó tó láti múra kí wọ́n sì jẹun. Ẹ tètè dé gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀ kí ẹ lè rí ibi jókòó sí kí ẹ sì bójú tó ohun tó bá yẹ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú ní ọjọ́ Friday, yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án ní ọjọ́ Saturday àti Sunday.

4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ète pàtàkì tí a fi ń pé jọ ni láti yin Jèhófà nínú “àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn,” ó yẹ kí apá kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tí yóò gbé Ọlọ́run wa ga. (Sm. 26:12) Láti ṣe ìyẹn, a rọ gbogbo wa pé ká ti wà lórí ìjókòó ṣáájú kí wọ́n tó pe orin ìbẹ̀rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣílétí Ìwé Mímọ́ pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́r. 14:40) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún olúkúlùkù wa? Bí o bá ti rí i tí alága jókòó sórí pèpéle ní àkókò tí orin yóò dún fún ìgbà díẹ̀, tètè lọ jókòó láyè rẹ. Ìyẹn á jẹ́ kí o lè fi tọkàntọkàn kópa nínú orin tí yóò bẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, tí a óò sì kọrin ìyìn sí Jèhófà.—Sm. 149:1.

5 Nígbà Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Ẹ́sírà “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́.” (Ẹ́sírà 7:10) Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa láti gba ìtọ́ni tí Jèhófà ń pèsè? Bí o ṣe ń ṣàyẹ̀wò àkọlé onírúurú apá tó wà lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a tẹ̀, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni Jèhófà n tipasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí sọ fún mi? Báwo ni mo ṣe lè fi ìsọfúnni yìí ṣe ara mi àti ìdílé mi láǹfààní?’ (Aísá. 30:21; Éfé. 5:17) Máa bá a lọ láti bi ara rẹ ní ìbéèrè wọ̀nyẹn jálẹ̀ àpéjọpọ̀ náà. Kọ àwọn kókó tí o wéwèé láti lò. Wá àyè láti jíròrò nípa wọn lópin ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn yóò jẹ́ kí o lè rántí ìsọfúnni náà kí o sì fi í sílò.

6 Pípọkànpọ̀ fún wákàtí tó pọ̀ díẹ̀ lè má rọrùn. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dènà ohun tí ó lè fẹ́ mú kí o má pọkàn pọ̀? Jẹ́ kí ojú rẹ ràn ọ́ lọ́wọ́. Dé ìwọ̀n gíga, ohun tí a bá tẹ ojú wa mọ́ ló máa ń gba àfiyèsí wa. (Mát. 6:22) Nítorí náà, dènà yíyíjú wo gbogbo ibi tí ariwo èyíkéyìí bá ti ṣẹlẹ̀ tàbí tí o bá ti gbọ́ ìró nǹkan. Máa wo olùbánisọ̀rọ̀. Máa fojú bá Bíbélì rẹ lọ nígbà tí wọ́n bá ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́, kí o sì jẹ́ kí Bíbélì rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé ẹsẹ náà.

7 Ìfẹ́ Kristẹni yóò mú ká yẹra fún dídí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 13:5) Àkókò “dídákẹ́ jẹ́ẹ́” tó sì yẹ ká fetí sílẹ̀ nìyí. (Oníw. 3:7) Nítorí náà, yẹra fún sísọ̀rọ̀ àti rírìn káàkiri àyàfi bí ó bá pọndandan. Dín lílọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kù nípa wíwéwèé ṣáájú. Má ṣe jẹun, má sì ṣe mu nǹkan títí dí ìgbà tí àkókò bá tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, àyàfi bí o bá ní àìlera tó gba pé kí o ṣe bẹ́ẹ̀. Kí àwọn tó bá gbé tẹlifóònù alágbèérìn, ẹ̀rọ tí ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀, àti ẹ̀rọ tí ń ya àwòrán wá má ṣe lò wọ́n lọ́nà tí yóò pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà. Kí àwọn òbí ṣètò kí gbogbo ìdílé wọn, títí kan àwọn ọ̀dọ́langba, jókòó pa pọ̀ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa.—Òwe 29:15.

8 Lọ́dún tó kọjá, alàgbà kan tó ti ń lọ sí àpéjọpọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Mo ronú pé àpéjọpọ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ìdí mìíràn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwùjọ, títí kan àwọn ọmọdé ló ń kọ àkọsílẹ̀. Ó dùn mọ́ni láti rí ìyẹn. Àwọn ará ń ṣí Bíbélì wọn nígbà tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ bá sọ pé kí wọ́n ṣí àwọn ẹsẹ kan.” A gbóríyìn fún fífetísílẹ̀ lọ́nà tó dára bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ó ń ṣe àwa àti àwọn tó tún wá sí àpéjọpọ̀ bíi tiwa láǹfààní, lékè gbogbo rẹ̀, ó ń fògo fún Atóbilọ́lá Olùfúnni-nítọ̀ọ́ni wa, Jèhófà Ọlọ́run.—Aísá. 30:20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́