A Péjọ Pọ̀ Láti Yin Jèhófà Lógo
1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ ọdún yìí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà lógo?
1 Alágbára ńlá ni Jèhófà, àwámárìídìí ni ọgbọ́n rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ pé, òun sì ní ọba ìfẹ́. Òun nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá, Olùfúnni-ní-Ìyè àti Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run. (Sm. 36:9; Ìṣí. 4:11; 15:3, 4) Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” wa ti ọdún yìí yóò mú kí ìpinnu wa láti máa yin Jèhófà nítorí pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà túbọ̀ lágbára sí i.—Sm. 86:8-10.
2, 3. Báwo ni ìṣètò tó dára ṣe lè mú ká jàǹfààní ní kíkún?
2 Ó Gba Ìṣètò Tó Dára: Láti lè jàǹfààní ní kíkún nínú àsè tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ dè wá, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìṣètò tó dára. (Éfé. 5:15, 16) Ǹjẹ́ o ti parí ètò lórí ilé tí wàá dé sí, ètò ọkọ̀ àti bí wàá ṣe gbàyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní iléèwé? Má ṣe fi àwọn nǹkan pàtàkì wọ̀nyí sílẹ̀ títí dìgbà tí yóò fi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sórí. Bí o kò bá tètè tọrọ àyè, ó ṣeé ṣe kó o pàdánù apá kan nínú àkókò aláyọ̀ yìí. Ó yẹ kí gbogbo wa wà níbẹ̀ jálẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà.
3 Pinnu láti tètè máa dé sí ilẹ̀ àpéjọ ní gbogbo ọjọ́ àpéjọ náà. Èyí á jẹ́ kó o ti máa sinmi lórí jókòó rẹ ká tó kọ orin ìbẹ̀rẹ̀, kí o sì lè fọkàn balẹ̀ láti gbọ́ ìtọ́ni tí wọn yóò fún wa. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe gbàyè ìjókòó sílẹ̀ fún àwọn mìíràn yàtọ̀ sáwọn tẹ́ ẹ jọ wọkọ̀ kan náà wá.
4. Kí nìdí tá a fi fẹ́ kí gbogbo wa gbé oúnjẹ ọ̀sán dání wá sí àpéjọ?
4 À ń fẹ́ kí gbogbo wa gbé oúnjẹ ọ̀sán dání wá sí àpéjọ dípò tí a óò fi máa lọ ra oúnjẹ níta lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Bí a bá kọ́wọ́ ti ìṣètò yìí, á mú kí àwọn nǹkan lè lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, á sì jẹ́ ká lè ráyè púpọ̀ láti bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa fara rora. (Sm. 133:1-3) Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi sọ́kàn pé a ò gbà kí ẹnikẹ́ni mú àwọn ohun èlò onígíláàsì àti ọtí líle wá sí ilẹ̀ àpéjọ o.
5. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí múra ọkàn wa sílẹ̀ de àpéjọ náà?
5 Fetí Sílẹ̀ Kí O Kẹ́kọ̀ọ́: Ẹ́sírà múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa láti lè gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ẹ́sírà 7:10) Ó fọkàn sí àwọn ẹ̀kọ́ Jèhófà. (Òwe 2:2) Ká tiẹ̀ tó kúrò nílé, a lè bẹ̀rẹ̀ sí múra ọkàn wa sílẹ̀ de àpéjọ náà nípa ṣíṣe àṣàrò lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ náà àti nípa bíbá ìdílé wa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
6. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ? (Wo àpótí.)
6 Ní gbọ̀ngàn tí ó tóbi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló lè gbàfiyèsí wa. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú ká má pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n ń sọ lórí pèpéle. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì á gba ẹ̀yìn etí wa kọjá. Àwọn àbá tó wà nínú àpótí inú àpilẹ̀kọ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ pọkàn pọ̀.
7, 8. Báwo la ṣe lè gba tàwọn mìíràn rò, kí sì ni ohun tó yẹ kí àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ dáadáa ṣe láti jàǹfààní ní kíkún látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà?
7 Gba Tàwọn Ẹlòmíràn Rò: A lè lo kámẹ́rà àti ẹ̀rọ tá a fi ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́, àmọ́ orí ìjókòó wa ni ká ti lò wọ́n kí á má bàa fa ìpínyà ọkàn bá àwọn ẹlòmíràn. Kí á mú kí tẹlifóònù alágbèérìn àti ohun èlò atanilólobó wa wà ní ipò tí kò fi ní pariwo sáwọn mìíràn létí. Àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ dáadáa lè jókòó sítòsí ẹ̀rọ gbohùngbohùn kí wọ́n lè jàǹfààní ní kíkún nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe so ẹ̀rọ àdáni mọ́ iná mànàmáná tàbí mọ́ ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ tó wà ní ilẹ̀ àpéjọ.
8 Láìsí àní àní, a ti ń fojú sọ́nà sí ìgbà tí a óò péjọ láti yin Jèhófà lógo! Ǹjẹ́ kí a pinnu láti yìn ín lógo nípa wíwà níbẹ̀ jálẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà, nípa títẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ àti nípa fífi àwọn nǹkan tí a óò kọ́ sílò.—Diu. 31:12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Bí A Ṣe Lè Fetí Sílẹ̀ Ní Àpéjọ
▪ Ṣàṣàrò lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ àsọyé
▪ Wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́
▪ Ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí
▪ Ya àwọn kókó tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí sọ́tọ̀
▪ Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun tí o kọ́