Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
1 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ka ìtọ́ni Ọlọ́run kún. Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí fún yín, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìwàláàyè yín.” (Diu. 32:45-47) Ǹjẹ́ a kò dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ìwàláàyè wa ṣeyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lójú rẹ̀ tí kò fi ṣíwọ́ọ fífi Ọ̀rọ̀ àtàtà rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà? Ìdí nìyẹn tí ojú wa fi wà lọ́nà gan-an fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” tí yóò jẹ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta àti ohun tí Jèhófà fi pa mọ́ dè wá.
2 Lọ́dún yìí, ibi méjìlélógún tó rọgbọ la ṣètò àpéjọpọ̀ àgbègbè sí jákèjádò Nàìjíríà. Ní àfikún sí èdè Yorùbá, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ yóò wáyé ní èdè Àbúà, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, Ègùn, Ẹ̀dó, Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì, Gòkánà, Haúsá, Ìgbò, Ìjọ́, Ísókó, Íṣàn, Kánà, Tífí, àti Ùròbò.
3 Ó dájú pé o ti ṣètò láti lọ ní gbogbo ọjọ́ tí àpéjọpọ̀ náà ó fi wáyé nítorí o gbà gbọ́ pé Jèhófà retí pé kí o wà níbẹ̀. Kí ó dá ẹ lójú pé ó rí ìsapá àti ìrúbọ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe láti lè wà níbẹ̀, ó mọrírì rẹ̀, kò sì jẹ́ gbàgbé. (Héb. 6:10) Nípa wíwà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ àpéjọpọ̀ náà látìgbà orin ìṣípàdé títí dìgbà àdúrà ìparí, a ń fi han Jèhófà pé a mọrírì ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí wa. (Diu. 4:10) A tún fi hàn pé a mọyì iṣẹ́ ribiribi tí ọ̀pọ̀ àwọn ará ṣe láti múra sílẹ̀ de àpéjọpọ̀ yìí.
4 Ṣíṣètò bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ṣe pé jọ ní àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan ń béèrè fún wíwéwèé ṣáájú àti ṣíṣètò tó dáa gbáà. Mímọ̀ táa mọ̀ pé ètò onífẹ̀ẹ́ ti wà nílẹ̀ fún àpéjọpọ̀ yìí yẹ kó sún wa láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí “ohun gbogbo [lè] máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́r. 14:40) A pèsè ìsọfúnni àti ìránnilétí tó tẹ̀ lé e yìí kí o lè wà ní sẹpẹ́ láti gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí àti ìfararora Kristẹni nígbà tóo bá dé àpéjọpọ̀.
Ṣáájú Àpéjọpọ̀
5 Ǹjẹ́ àwọn tóò ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lè mọ ètò tó yẹ kí wọ́n ṣe láti lè lọ sí àpéjọpọ̀? Ohun tí wọ́n bá rí tàbí tí wọ́n bá gbọ́ níbẹ̀ lè jẹ́ kí wọ́n di olùjọsìn Jèhófà. (1 Kọ́r. 14:25) Ó yẹ káwọn alàgbà mọ̀ nípa ẹnikẹ́ni tó bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nípa ibùwọ̀ tàbí bí wọn yóò ṣe dé àpéjọpọ̀, àgàgà àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ, kí wọ́n sì fi tìfẹ́tìfẹ́ rí sí i pé wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́.—Gál. 6:10.
6 Ǹjẹ́ ẹ ti parí ètò lórí ibùwọ̀? Ní báyìí, ó yẹ kí akọ̀wé ìjọ ti fi gbogbo fọ́ọ̀mù Ìbéèrè Ibùwọ̀ fáwọn tó ní àkànṣe àìní, tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ fọwọ́ sí, ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì àpéjọpọ̀ tó yẹ kí fọ́ọ̀mù náà lọ. Bí wọ́n bá ti ṣètò ibùwọ̀ fún ẹ lábẹ́ ìṣètò àkànṣe àìní, tó sì di dandan pé kí ó fagi lé e, jọ̀wọ́ fi tó Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ibùwọ̀ lágbègbè yín létí lójú ẹsẹ̀, kí wọ́n lè ṣètò ibùwọ̀ náà fẹ́lòmíràn. Àdírẹ́sì wọn wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé kejì lára fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ibùwọ̀.
7 Bóo bá ń fẹ́ ìsọfúnni nípa àpéjọpọ̀ kan, akọ̀wé ìjọ lè fún ẹ ní àdírẹ́sì náà gan-an tóo fẹ́, bó ti wà lẹ́yìn fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ibùwọ̀.
8 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìtọ́jú pàjáwìrì nìkan ni Ẹ̀ka Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀ tó wà ní àpéjọpọ̀ ń bójú tó, a dá a lámọ̀ràn pé kí o mú asipirín-ìn, báńdéèjì, oògùn tí a ń fà símú, oògùn amóúnjẹ-dà, àtàwọn ohun èlò báyẹn tó jẹ́ tìrẹ dání wá sí àpéjọpọ̀ náà, bí wọn yóò bá wúlò fún ẹ. Bí ìwọ tàbí aráalé rẹ bá ní ìṣòro ńlá tí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, bí àrùn ọkàn, àtọ̀gbẹ, tàbí àwọn tí gìrì máa ń mú, jọ̀wọ́ kó àwọn oògùn tó yẹ dání wá sí àpéjọpọ̀ fún àìsàn wọ̀nyí. Á bọ́gbọ́n mu kí ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó mọ̀ nípa ìṣòro náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ onítọ̀hún, torí pé ẹni yẹn ni yóò tètè mọ ìrànlọ́wọ́ tó yẹ ní ṣíṣe.
9 Àǹfààní kò ní ṣàìṣí sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà bí o ti ń lọ, tí o sì ń bọ̀ láti àpéjọpọ̀. Ṣé o ti ṣe tán láti ṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Gbogbo wa, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá, lè kópa, nípa fífi ìwé ìléwọ́ lọ àwọn tí ń ta epo nílé epo, àwọn tí ń gbowó ibodè, àtàwọn mí-ìn tóo bá ṣalábàápàdé lẹ́nu lílọ-bíbọ̀. Àwọn àǹfààní yóò ṣí sílẹ̀ láti pín ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn fáwọn tó bá fìfẹ́ hàn sí i. Múra tán láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà fáwọn tó ṣòroó bá pàdé lẹ́nu ìjẹ́rìí bí àṣà.
Nígbà Àpéjọpọ̀
10 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yóò bẹ̀rẹ̀ láago 9:20 àárọ̀ lọ́jọ́ Friday, ṣùgbọ́n yóò bẹ̀rẹ̀ láago 9:00 àárọ̀ lọ́jọ́ Sátidé àti Sunday. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ tàbí àwọn tẹ́ẹ jọ wọkọ̀ wá nìkan ni o lè gbàyè fún. A ó ṣètò àyè ìjókòó tó rọgbọ fáwọn àgbàlagbà. Kò ṣeé ṣe láti pèsè àwọn àkànṣe iyàrá níbi àpéjọpọ̀ fáwọn tí nǹkan tí ń bẹ láyìíká wọn máa ń fi àìsàn ṣe tàbí àwọn tó ní èèwọ̀ ara. Lójoojúmọ́, bóo bá ti ń fi ibi ìjókòó rẹ sílẹ̀, jọ̀wọ́ wò yí ká, kí o sì rí i dájú pé o ti kó gbogbo ẹrù rẹ.
11 Ṣé àpéjọpọ̀ àgbègbè yìí lo ti máa ṣe batisí? Nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ Sátidé, a ó ṣètò ìjókòó fáwọn tó fẹ́ ṣe batisí, àwọn olùtọ́jú èrò yóò sì fi ibẹ̀ hàn ẹ́. Bó bá ṣeé ṣe, jọ̀wọ́ rí i dájú pé o ti wà ní ìjókòó kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. Gbé Bíbélì, ìwé orin, aṣọ ìnura, àti aṣọ ìwẹ̀ tó bójú mu dání. Àwọn ṣòkòtò jín-ìn-sìn táa sọ di péńpé, àwọn síńgílẹ́ẹ̀tì tó ní ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán lára, àti irú àwọn aṣọ báwọ̀nyẹn kò yẹ irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó lọ́lá bẹ́ẹ̀yẹn. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé olúkúlùkù ló lóye kókó wọ̀nyí nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè inú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ ṣe batisí. Níwọ̀n bí ìbatisí ti jẹ́ àmì ìyàsímímọ́ tí èèyàn nìkan ṣe sí Jèhófà Ọlọ́run, kò ní bójú mu pé káwọn tó fẹ́ ṣe batisí di ara wọn lọ́wọ́ mú nígbà tí wọ́n bá ń batisí wọn.
12 O lè lo kámẹ́rà táa fi ń ya fọ́tò, kámẹ́rà ti fídíò, àti rédíò tí ń gbohùn sílẹ̀ ní àpéjọpọ̀. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ gbé wọn dí ojú ọ̀nà, tàbí kí o fi dí àwọn ẹlòmíràn lójú, tàbí kí nǹkan wọ̀nyí máa pe àfiyèsí àwọn èèyàn kúrò lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ lè dá ṣiṣẹ́, láìsí pé o so wọ́n mọ́ iná tàbí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tiwa. Kò bójú mu láti sọ àpéjọpọ̀ di ibi ìpolówó iṣẹ́ fọ́tò téèyàn ń ṣe, tàbí ká máa wá oníbàárà kiri ní àpéjọpọ̀.
13 Nítorí àkókò àti ìmú-ǹkan-rọrùn, Society ti sọ fún wa pé ká máa gbé oúnjẹ ọ̀sán wa dání wá sí àpéjọpọ̀ lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ló ti ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, wọ́n sì ti rí i pé lẹ́yìn táa bá ní ká lọ fún ìsinmi ọ̀sán, wọ́n lè jókòó pẹ̀lú ìdílé wọn, kí wọ́n sì jẹ ohun tí wọ́n gbé dání lọ́jọ́ yẹn. Ọ̀pọ̀ sọ pé àwọn ti gbádùn àǹfààní sísinmi nígbà ìsinmi ọ̀sán àti títúbọ̀ lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará. Èyí ń béèrè pé kí a gbé oúnjẹ tiwa wá látilé. A fẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá wá sí àpéjọpọ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí.
14 Ǹjẹ́ o lè yọ̀ǹda ara rẹ fún iṣẹ́ ìmọ́tótó lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá parí lójoojúmọ́? Tàbí kẹ̀, ǹjẹ́ o lè ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ tó wà ní àpéjọpọ̀? Tóo bá lè ṣèrànwọ́, dákun wá sí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ti àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọ̀dọ́mọdé pẹ̀lú lè wá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òbí wọn tàbí àgbàlagbà mí-ìn tó tóótun. Àmọ́ o, olúkúlùkù ló lè ṣèrànwọ́ láti rí i pé ibi gbogbo mọ́ tónítóní nípa ṣíṣa ìdọ̀tí tí wọ́n bá rí, kí wọ́n sì lọ jù ú síbi tó yẹ.
15 A ti rí ìtọ́sọ́nà àtàtà gbà nípa ọ̀nà tó yẹ ká gbà wọṣọ, ká sì múra lọ sáwọn àpéjọpọ̀ wa. Fún àpẹẹrẹ: A ti rí ìtọ́sọ́nà gbà lórí ọ̀ràn yìí nínú àwọn àkìbọnú tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a ti rí àwọn àkàwé àti àwòrán nínú àwọn ìwé wa, àti lékè gbogbo rẹ̀, a ti rí nǹkan tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì. (Róòmù 12:2; 1 Tím. 2:9, 10) Àwọn èèyàn mọ ẹni táa jẹ́ àti ìdí táa fi pé jọ sílùú wọn. Fún ìdí yìí, ìwọṣọ àti ìmúra wa alára ń jẹ́rìí lọ́nà tó kàmàmà. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jèhófà ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a máa ń rí ẹ̀mí ayé nínú bí àwọn kan tó máa ń wá sí àpéjọpọ̀ wa ṣe ń wọṣọ tí wọ́n sì ń múra. Wíwọ irú aṣọ èyíkéyìí tí ń fi ohun téèyàn wọ̀ sísàlẹ̀ hàn yóò fi hàn pé olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tẹ̀mí tó pe ara rẹ̀. Ìrísí mímọ́ tónítóní, tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ló ń fani mọ́ra jù lọ. Fún ìdí yìí, àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ lajú wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò ohun táwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn fẹ́ wọ̀. Èyí tún kan ìgbà táa bá kúrò níbi àpéjọpọ̀ o. Wíwọ káàdì àyà wa kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ túbọ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá mọ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn mímọ́ rẹ̀.—Fi wé Máàkù 8:38.
16 A mí sí Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba láti sọ pé “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí” àti pé “ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” (Òwe 22:15; 29:15) Nígbà típàdé ń lọ lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jẹ́ ọmọdé ti yọ àwọn ará lẹ́nu, àwọn ẹni ẹlẹ́ni tí ń gbìyànjú láti jàǹfààní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń lọ lọ́wọ́. Ó dájú pé àwọn ọmọ wọ̀nyí kò jàǹfààní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí táa dìídì ṣètò fún wọn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn òbí ni yóò jíhìn fún Jèhófà nítorí ìwà àwọn ọmọ wọn, ọ̀nà kan ṣoṣo tí bàbá tàbí ìyá fi lè mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ ò ṣìwà hù àti pé wọ́n ń tẹ́tí sí ìtọ́ni Jèhófà ni bí àwọn ọmọ bá jókòó tì wọ́n. Àwọn olùtọ́jú èrò yóò lọ bá ẹnikẹ́ni tó bá ń dàpàdé rú, láti dá wọn lẹ́kun, wọ́n á sì fi sùúrù rán wọn létí pé kí wọ́n fọkàn sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń lọ lọ́wọ́.
17 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àtonílé-àtàlejò là ń pè wá sáwọn àpéjọpọ̀ wa, ó mọ́gbọ́n dání láti máa ṣọ́ àwọn ọmọdé àtàwọn ẹrù wa. Ẹ̀bùn iyebíye làwọn ọmọ wa jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ìwà apanijẹ tí Sátánì ń hù làwọn èèyàn ayé ń hù. Nítorí náà, ẹ dákun ẹ rí i dájú pé ẹ mọ ibi tọ́mọ yín wà nígbà gbogbo. Kò tán síbẹ̀ o, kámẹ́rà, àpamọ́wọ́, àtàwọn nǹkan iyebíye mí-ìn gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo, má fi wọ́n sílẹ̀ sórí ìjókòó. Rí i dájú pé o ti ọkọ̀ rẹ, kí o sì ti àwọn ẹrù rẹ mọ́ inú búùtù tàbí kí o kó wọn dání. Èyí ò ní jẹ́ káwọn olè dójú sọ ọkọ̀ rẹ láti wá jí nǹkan nínú rẹ̀.
18 Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ibùwọ̀ fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ bí ìṣòro bá dìde níbi tí wọ́n fi ẹ́ wọ̀ sí. Jọ̀wọ́ sọ ìṣòro-kíṣòro tóo bá ní nígbà tóo ṣì wà ní àpéjọpọ̀ fún Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ibùwọ̀. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí yóò láyọ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú rẹ̀ kí o lè máa bá a lọ ní gbígbádùn àpéjọpọ̀ náà.
19 Ó mà dáa o, láti rí àwọn ará, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọ́n ń kọ àkọsílẹ̀ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ tó ṣe ṣókí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀, yóò sì jẹ́ kí o rántí àwọn kókó pàtàkì. Yíyẹ àkọsílẹ̀ rẹ wò lẹ́yìn náà pẹ̀lú ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣàṣàrò lórí àwọn kókó-kókó tó jáde nínú àpéjọpọ̀ náà kí o má bàa gbàgbé.
20 Ọlọ́làwọ́ làwọn èèyàn Jèhófà látilẹ̀wá, àgàgà tó bá dọ̀ràn ká ṣètìlẹyìn fún àwọn nǹkan ìṣàkóso Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 36:5-7; 2 Kíró. 31:10; Róòmù 15:26, 27) Ọrẹ àtinúwá yín fún iṣẹ́ kárí ayé náà la ń lò láti fi kájú àwọn ìnáwó tó ń jẹyọ látinú bíbójútó àwọn ibi ńlá táa ti ń ṣe àpéjọpọ̀. Bó bá ṣe pé ìwé sọ̀wédowó lo fẹ́ lò, jọ̀wọ́ kọ ọ́ lọ́nà tí “Watch Tower” yóò fi lè rí i gbà.
21 Gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú Ámósì 3:7, Jèhófà sọ pé òun “kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé [òun] ṣí ọ̀ràn àṣírí [òun] payá fún àwọn ìránṣẹ́ [òun] wòlíì.” Gẹ́gẹ́ bí “Olùṣí àwọn àṣírí payá,” Jèhófà ti mú kí a kọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àsọtẹ́lẹ̀ sínú Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ kíkún lọ́nà tó péye. (Dán. 2:28, 47) Àwọn ìlérí kíkọyọyọ ṣì ń bẹ níwájú o. Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti ọdún 1999 yóò fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run. Fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fẹ́ bá ẹ sọ. Lo ohun tóo bá rí, tóo bá sì gbọ́—nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nínú ìjọ, àti nínú ìgbésí ayé rẹ. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà rọ̀jò ìbùkún sórí gbogbo ètò tí o ń ṣe láti lè pésẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ àpèjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ yìí!
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Wéwèé láti wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Friday, Saturday, àti Sunday!