Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tím. 3:16) Níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ní ìmísí, a ní ìdí gbogbo láti lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ àgbègbè ti ọdún yìí ni “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò fún ìgbàgbọ́ wa nínú Bíbélì lókun, yálà a ti mọ òtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣalábàápàdé ètò àjọ Jèhófà. Ó yẹ kí gbogbo wa ṣètò láti pésẹ̀ nígbà gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ẹ wo bí yóò ti gbéni ró tó bí àwọn ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ìfẹ́ hàn, ní pàtàkì àwọn tí a ń bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bá pésẹ̀ pẹ̀lú wa!
2 Àpéjọpọ̀ Ọlọ́jọ́ Mẹ́ta: Lọ́dún yìí, a ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta fún àǹfààní wa. Lọ́tẹ̀ yí, a óò ṣe àpéjọpọ̀ 110 lápapọ̀ ní Nàìjíríà. Ní báyìí, a ti sọ fún ọ nípa àpéjọpọ̀ tí a yan ìjọ rẹ sí, ó sì yẹ kí o ti ṣe ìwéwèé tí ó ṣe gúnmọ́ láti pésẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. O ha ti tọ agbanisíṣẹ́ rẹ lọ láti gba ìsinmi tí o nílò bí? Bí o bá ní àwọn ọmọ tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, tí àpéjọpọ̀ yín sì bọ́ sí àkókò tí ilé ẹ̀kọ́ ń lọ lọ́wọ́, o ha ti fi inú rere sọ fún àwọn olùkọ́ wọn pé àwọn ọmọ rẹ kì yóò wá sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ Friday nítorí apá pàtàkì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn wọn yìí bí?—Diu. 31:12.
3 Ní àfikún sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn àpéjọpọ̀ yóò wà ní èdè Abua, Èdè Àwọn Adití, Edo, Ègùn, Ẹ́fíìkì, Gòkánà, Haúsá, Ìgbò, Ijaw, Ishan, Ísókó, Khana, Tiv, Urhobo, àti Yorùbá.
4 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Friday ní 9:20 òwúrọ̀, yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Saturday àti Sunday ní 9:00 òwúrọ̀.
5 Ṣe Dáadáa Nípa Fífiyèsí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà: Àpọ́sítélì Pétérù rán àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní létí pé wọn yóò ṣe dáadáa láti fún ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bíi fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn. (2 Pét. 1:19) Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa wa. Ṣe ni gbígbé nínú ayé ògbólógbòó yìí tí ó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì dà bíi wíwà ní ibi tí ó ṣókùnkùn. A kún fún ìmoore pé a ti ké sí wa kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí. (Kól. 1:13; 1 Pét. 2:9; 1 Jòh. 5:19) Láti máa bá a nìṣó nínú ìmọ́lẹ̀, a ní láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nípa fífiyèsí Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí a mí sí. Àpéjọpọ̀ àgbègbè wa lọ́dún yìí yóò fún wa níṣìírí láti ṣe ìyẹn gan-an.
6 Ó lè béèrè ìsapá lọ́wọ́ wa bí a óò bá pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ṣùgbọ́n ó dájú pé a óò bù kún wa fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. A ní láti sakun láti sinmi dáadáa kí a tó wá sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀ kí a baà lè wà lójúfò ní àwọn àkókò ìjókòó. Jẹ́ kí àkókò tí ó pọ̀ tó wà fún ọ láti dé ilẹ̀ àpéjọ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kí o baà lè wà lórí ìjókòó rẹ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, dara pọ̀ nínú orin ìbẹ̀rẹ̀ àti àdúrà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Kí àwọn àgbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, kí àwọn òbí sì dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́.—Éfé. 6:4.
7 Bí a bá wo àwọn àkọlé ọ̀rọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà tó bẹ̀rẹ̀, a lè gbìyànjú láti fojú sọ́nà fún àwọn kókó tí a lè mú jáde ní àkókò ìjókòó yẹn. Èyí yóò mú kí ọkàn ìfẹ́ wa nínú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ sí i nígbà tí a bá gbé e kalẹ̀. A lè fojú sọ́nà fún àwọn kókó tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìdí tí a fi gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú ìlérí rẹ̀ tí ó dájú láti san èrè fún àwọn tí ń wá a taratara. (Héb. 11:1, 6) A ti dábàá rẹ̀ pé kí a máa kọ àkọsílẹ̀ ṣókí láti ràn wá lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Bí a bá kọ àkọsílẹ̀ jàn-ànràn jan-anran, a lè pàdánù àwọn kókó pàtàkì kan nítorí pé ìwé kíkọ ni a gbájú mọ́. A óò tún ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ lọ́nà tí ó sàn jù nígbà tí a bá ń fojú bá a lọ nínú Bíbélì tiwa bí a ti ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́.
8 Ní ọdún tí ó kọjá, ní àwọn àpéjọpọ̀ mélòó kan, a tún rí àwọn àgbà àti èwe díẹ̀ tí wọ́n ń rìn gbéregbère káàkiri ilẹ̀ àpéjọ tí wọ́n sì ń bẹ àwọn mìíràn wò nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́, dípò kí wọ́n tẹ́tí sí ohun tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ti pèsè fún àǹfààní wa. Jésù ṣèlérí láti fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mát. 24:45-47) Nítorí náà, ṣe ni ó yẹ kí a wà níbẹ̀ láti jàǹfààní láti inú oúnjẹ yẹn, kì í ṣe láti fi àìnímọrírì hàn. (2 Kọ́r. 6:1) Ó tún dà bíi pé nígbà tí ara àwọn ọmọ kan kò bá balẹ̀, wọ́n sábà máa ń sọ pé àwọn ń lọ sí ilé ìtọ̀ tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún dídìde kí wọ́n sì máa rìn káàkiri. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bíbẹ́tọ̀ọ́ mu láti ilé yóò mú kí lílọ sí ilé ìtọ̀ tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lóòrèkóòrè di aláìpọndandan. Nígbà míràn, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n tójúúbọ́ máa ń jókòó pa pọ̀, wọ́n máa ń rojọ́, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, wọ́n sì máa ń fi àkọsílẹ̀ ránṣẹ́ sí ara wọn. Àwọn ọ̀dọ́ wa, tí wọ́n dojú kọ ọ̀pọ̀ pákáǹleke lónìí, nílò pípọkànpọ̀ sórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń gbé kalẹ̀, kì í ṣe kí wọ́n máa ṣe àwọn ohun mìíràn nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Àwọn ìfẹ́ ọkàn èwe tí kò bá ìlànà Bíbélì mu ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún. (Fi wé Tímótì Kejì 2:22.) Àfiyèsí gbogbogbòò, tàgbà tèwe, yóò bọlá fún Jèhófà, yóò sì mú un láyọ̀.
9 Bí ó bá pọn dandan fún ọ̀kan nínú àwọn olùṣàbójútó èrò láti fún ẹnikẹ́ni ní ìmọ̀ràn lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ìpèsè onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. (Gál. 6:1) Gbogbo wa ní láti rántí pé ìdí tí a fi sapá láti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ náà jẹ́ kí a baà lè ‘fetí sílẹ̀, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́.’ (Diu. 31:12) Pẹ̀lúpẹ̀lù, “ọlọgbọ́n yóò gbọ́, yóò sì máa pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́.” (Òwe 1:5) Ní àkókò tí ó ṣẹ́ kù kí ẹ tó lọ sí àpéjọpọ̀, ẹ jíròrò gẹ́gẹ́ bí ìdílé, bí ó ti yẹ kí ẹ jókòó pa pọ̀ nínú àwùjọ, kí ẹ wà ní ìjókòó nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ, àti pé kí ẹ fiyè sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà dáadáa kí ẹ baà lè jàǹfààní kíkún láti inú rẹ̀.
10 Ọ̀ṣọ́ Tí Inú Jèhófà Dùn Sí: Àwọn ènìyàn Jèhófà wà lójútáyé fún gbogbo ayé láti rí. (1 Kọ́r. 4:9) A mọ̀ wá ní gbogbogbòò fún ìlànà rere tí a ní ní ti aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra. Fífi ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ó wà nínú Tímótì Kíní 2:9, 10 àti Pétérù Kíní 3:3, 4 sílò ti yọrí sí àwọn ìyípadà ńláǹlà nínú ìrísí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú bí wọ́n ṣe rí nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìlànà ìwọṣọ àti ìmúra tí ń burú sí i ṣáá, èyí tí a ń rí nínú ayé. A fẹ́ wà lójúfò kí a má baà dà bí ayé nínú ìrísí wa—wíwọ aṣọ tí kò bójú mu, ṣíṣagbátẹrù àṣà ìgbàlódé ti ayé nínú ọ̀nà ìgbàṣerun, tàbí ṣíṣàìmúra níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìwọṣọ àti ìmúra wa tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ yẹ kí ó ran àwọn ẹni tuntun tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ lọ́wọ́ láti rí bí ó ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.
11 Nígbà tí ó jẹ́ pé èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí àpéjọpọ̀ ọdún tí ó kọjá fúnni dára gan-an, ìwọṣọ àti ìmúra ayé ń bá a nìṣó láti jẹ́ ìṣòro pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan, ní pàtàkì ní àkókò fàájì. Nígbà tí a bá ń wéwèé láti lọ sí àpéjọpọ̀, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò ara wa fínnífínní ní ti ìwọṣọ àti ìmúra wa. Ẹ̀yin òbí, ẹ fi ọgbọ́n ṣèkáwọ́ ohun tí àwọn ọmọ yín kéékèèké àti ọ̀dọ́langba yóò wọ̀. Ẹ rí i dájú pé a kò jẹ́ kí àwọn àṣà ìṣeǹkan àti àṣà ìgbàlódé ayé ní ipa búburú lórí ìrísí Kristẹni wa.
12 Pa Ìwà Rere Mọ́: Ìwà rere jẹ́ àmì àwọn Kristẹni tòótọ́. (1 Pét. 2:12) Ìwà wa níbikíbi tí a bá wà—ní àpéjọpọ̀, ní ìgboro, àti ní àwọn ibi tí a fi wá wọ̀ sí, títí kan ìgbà tí a bá ń rìnrìn àjò—lè pèsè ìjẹ́rìí rere, kí ó sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ohun tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè ṣe fún àwọn ènìyàn. Èyí lè sún àwọn kan láti wá mọ Jèhófà. (Fi wé Pétérù Kíní 3:1, 2.) A ní àǹfààní láti fi ìwà wa yin Ọlọ́run lógo. Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Àpéjọ kan kọ̀wé pé: “Ipò ẹlẹ́mìí àlàáfíà [ní] àpéjọpọ̀ ní àkókò ìjókòó kọ̀ọ̀kan àti lẹ́yìn rẹ̀ mú wa láyọ̀.” Ní ṣíṣàlàyé síwájú sí i, ìròyìn wọn sọ pé: “Àwọn òbí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gidigidi, wọn kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn máa rìn gbéregbère kiri.” Ìròyìn láti ibi àpéjọpọ̀ míràn sọ pé “àwọn ará pa ìlànà gíga mọ́ ní ti ìwàlétòlétò jálẹ̀ àkókò àpéjọpọ̀ náà.” Olóyè kan, tí ó pésẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ náà ni ìwà àwọn alápèéjọpọ̀ wú lórí. Ó wí pé: “Mo ti lọ sí onírúurú àjọ ìsìn . . . ṣùgbọ́n, mo ti rí i pé àwọn ìyàtọ̀ kan wà láàárín ẹ̀yin àti àwọn. Fún àpẹẹrẹ, mo rí àwọn ọlọ́pàá àti àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò míràn níbi ìkórajọpọ̀ àwọn ìsìn míràn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n, n kò tí ì rí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ níhìn-ín. . . . Ní tòótọ́, ẹ ń fi ohun tí ẹ fi ń kọ́ni ṣèwàhù.” Àwọn ìròyìn bí ìwọ̀nyí ń dùn mọ́ni láti kà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí ó ti wù kí ó rí, àìní wà láti wà lójúfò kí a baà lè pa orúkọ rere ti àwọn ènìyàn Jèhófà mọ́.
13 A ti pèsè ọ̀pọ̀ ìránnilétí ní ti ṣíṣàkóso àwọn ọmọ wa, ní ṣíṣàìjẹ́ kí wọ́n máa sáré kiri láìbójútó wọn, ní dídí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Lọ́dọọdún, Society ń rí ìròyìn gbà pé àwọn kan lára àwọn ọmọ wa ni a kì í bójú tó nínú gbọ̀ngàn àpéjọ àti ní àyíká rẹ̀ tàbí tí a rí wọn tí wọ́n ń sáré káàkiri ilẹ̀ àpéjọ. Ó sì bani lọ́kàn jẹ́ láti rí ìròyìn gbà láti àpéjọpọ̀ kan pé “ọwọ́ ba ọmọdékùnrin kan tí ó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún 12 tí ń jí owó nínú ọ̀kan lára àwọn àpótí ọrẹ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpéjọpọ̀ ń pèsè àǹfààní láti ṣèbẹ̀wò kí a sì kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará wa, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn síbẹ̀ pé, ojúṣe wọn ni láti pèsè àbójútó fún àwọn ọmọ wọn nígbà gbogbo. Èyí jẹ́ ẹrù iṣẹ́ tí Jèhófà gbé ka òbí kọ̀ọ̀kan lórí. (Òwe 1:8; Éfé. 6:4) Ìgbésẹ̀ àwọn ọmọ tí a kò bójú tó lè jin orúkọ rere tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòó kù ti ṣiṣẹ́ kára láti gbé ró lẹ́sẹ̀. (Òwe 29:15) Àwọn àgbègbè díẹ̀ wà tí a ti lè ṣe ìmúsunwọ̀n sí i. Ní àwọn ilẹ̀ àpéjọpọ̀ kan, ọ̀pọ̀ ń yàn láti dúró sábẹ́ igi tàbí sí ilé tí a fi wọ́n wọ̀ sí, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ fiyè sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, nínú àwọn ipò díẹ̀, àwọn kan juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò náà láti sọ àpéjọpọ̀ di ohun ìṣòwò. Nígbà míràn, wọ́n máa ń bá a dórí ṣíṣe àwọn nǹkan tí ó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ fún títà ní ilẹ̀ àpéjọ. Society kò fọwọ́ sí èyí.
14 Kíkájú Ìnáwó Àpéjọpọ̀: Gbogbo wa ni a óò náwó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀. Ìnáwó mìíràn wà tí a óò ṣe rere láti gbé yẹ̀ wò. Owó gọbọi ni a fi ń tọ́jú àwọn ohun èlò tí a ń lò fún àpéjọpọ̀. Àwọn ìnáwó mìíràn tún wà tí a gbọ́dọ̀ bójú tó. Jọ̀wọ́ rántí pé ní báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé orí àwọn ọrẹ àtinúwá tí ó wà nínú àwọn àpótí ọrẹ ni àwọn àpéjọpọ̀ gbára lé, níwọ̀n bí kò ti sí ilé oúnjẹ mọ́, bí kò ṣe kìkì ìpápánu díẹ̀, láti ṣèrànwọ́ ní kíkájú ìnáwó. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ‘kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ wá síwájú Jèhófà ní ọwọ́ òfo.’ (Diu. 16:16) Àwọn ọrẹ àtinúwá wa ọlọ́làwọ́ ní àwọn àpéjọpọ̀ ni a mọrírì gidigidi.—Ìṣe 20:35; 2 Kọ́r. 9:7, 11, 13.
15 Àyè Ìjókòó: Ìtọ́sọ́nà tí a ti fúnni fún ọdún mélòó kan ni a óò máa fi sílò lọ, ìyẹn ni pé, O LÈ GBA ÀYÈ SÍLẸ̀ FÚN KÌKÌ MẸ́ŃBÀ ÌDÍLÉ RẸ ÀTI ẸNIKẸ́NI TÍ Ó BÁ Ọ WÁ NÍNÚ ỌKỌ̀ AYỌ́KẸ́LẸ́ RẸ. Ó dára láti rí i pé àwọn púpọ̀ sí i ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, èyí sì ti mú kí ipò onífẹ̀ẹ́ tí a ń fi hàn ní àwọn àpéjọpọ̀ lọ sókè sí i. Ní àwọn ilẹ̀ àpéjọpọ̀ púpọ̀ jù lọ, ó máa ń rọrùn láti dé orí àwọn ìjókòó kan ju àwọn mìíràn lọ. Jọ̀wọ́ fi ìgbatẹnirò hàn, kí o sì fi àwọn ìjókòó tí ó túbọ̀ rọrùn sílẹ̀ fún àwọn tí àyíká ipò wọn béèrè fún wọn.
16 Àwọn Kámẹ́rà, Àwọn Agbohùn-Gbàwòrán-Sílẹ̀, àti Àwọn Agbohùnsílẹ̀-Sórí-Kásẹ́ẹ̀tì: A lè lo kámẹ́rà àti ohun èlò tí ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ ní àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, a kò gbọ́dọ̀ fi lílò tí a ń lò wọ́n pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n pésẹ̀ níyà. A kò gbọ́dọ̀ máa rìn kiri ní àkókò ìjókòó láti ya àwòrán, níwọ̀n bí ìyẹn yóò ti ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A kò gbọ́dọ̀ so ohun èlò èyíkéyìí tí a fi ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ mọ́ iná tàbí mọ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi ohun èlò yí dí àwọn ọ̀nà àbákọjá tí ó wà láàárín ìjókòó, àwọn ọ̀nà àrìnlọrìnbọ̀, tàbí kí a fi dí ojú àwọn ẹlòmíràn.
17 Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀: Ẹ̀ka Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀ wà fún ìtọ́jú pàjáwìrì nìkan. Kò ṣeé ṣe fún ẹ̀ka yìí láti bójú tó àrùn tí ó ti di bárakú. Ìdí nìyẹn tí o fi gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò àìní rẹ àti ti ìdílé rẹ ní ti ìlera ṣáájú. Jọ̀wọ́, mú oògùn ibà, asipirín-ìn, àwọn oògùn amú-oúnjẹ-dà, báńdéèjì, pín-ìnnì, àti àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ tìrẹ wá, níwọ̀n bí irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ kì yóò ti sí ní àpéjọpọ̀. Àwọn tí wọ́n bá mọ̀ pé àrùn wárápá, gìrì, àrùn ọkàn àyà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lè kọ lu àwọn, gbọ́dọ̀ ronú nípa àìní wọn ṣáájú títí dé àyè tí ó bá ṣeé ṣe. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní àwọn egbògi tí ó pọn dandan lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé tàbí ti ìjọ tí ó lóye ipò wọn sì gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú wọn nígbà gbogbo láti pèsè ìrànwọ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá nílò. Bí àwọn kan tí wọ́n ní àkànṣe àìní ní ti ìlera kò bá ní àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, a ní láti jẹ́ kí àwọn alàgbà ìjọ wọn mọ̀ nípa ipò náà, kí wọ́n sì ṣe àwọn ètò tí ó pọn dandan láti ṣèrànwọ́.
18 Oúnjẹ ní Àpéjọpọ̀: Fún ìgbà àkọ́kọ́, a kì yóò gbọ́únjẹ ní àwọn àpéjọpọ̀ lọ́dún yìí, a kì yóò sì ta oúnjẹ. Èyí yóò yọrí sí pé ọ̀pọ̀ yóò lómìnira ní àwọn àkókò ìjókòó láti pọkàn pọ̀ sórí oúnjẹ tẹ̀mí. A ti rí ọ̀rọ̀ ìmọrírì mélòó kan gbà fún ìmúrọrùn tí ó jọ èyí láti ìgbà tí a ti gbé ìṣètò náà kalẹ̀ ní àpéjọ àyíká àti ọjọ́ àpéjọ àkànṣe. Kí gbogbogbòò múra sílẹ̀, kí wọ́n sì mú oúnjẹ tiwọn tí kì í mára wúwo, tí ó sì ń ṣara lóore wá fún ìsinmi ọ̀sán, irú bí àwọn tí a dábàá nínú lẹ́tà sí gbogbo ìjọ ti May 15, 1997. A fún yín níṣìírí láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán yín ní gbọ̀ngàn àpéjọ. Ó jẹ́ àǹfààní àtàtà láti sinmi, kí o sì kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jókòó yí ọ ká. Kìkì pé a fún ọ níṣìírí láti mọ́ tónítóní, kí o má sì dọ̀tí àgbègbè tí o jókòó sí. Jọ̀wọ́ nu oúnjẹ èyíkéyìí tí ó bá dànù, kí o sì jù wọ́n sínú ohun tí a ń kó ìdọ̀tí sí, títí kan àwọn ohun tí o fi di nǹkan, bébà, àti àwọn ìdọ̀tí mìíràn. Kí ẹ̀ka ìmọ́tótó wà lójúfò láti mú kí àwọn ohun tí a ń kó ìdọ̀tí sí wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún èyí ní gbọ̀ngàn àpéjọ. A kò gbọ́dọ̀ mú àwọn ohun mímu ọlọ́tí líle, títí kan ẹmu àti ògógóró, wá sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀. Kò bọ́gbọ́n mu láti mu ohun mímu ọlọ́tí líle ní àkókò ìsinmi. Àwọn kúlà oúnjẹ tí o bá gbé wá sí gbọ̀ngàn àpéjọ gbọ́dọ̀ wọ abẹ́ ìjókòó, wọn kò sì gbọ́dọ̀ dí àwọn ọ̀nà àbákọjá tí ó wà láàárín ìjókòó. A ti kíyè sí àwọn kan nínú àwùjọ tí wọ́n ń jẹ́, tí wọ́n sì ń mu nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Ṣíṣe èyí kò fi ọ̀wọ̀ hàn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti kíyè sí àwọn kan tí wọ́n lọ ń ra oúnjẹ lọ́wọ́ àwọn olóúnjẹ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Irú àṣà bẹ́ẹ̀ kò bójú mu.
19 Ní tòótọ́, a mọrírì àsè tẹ̀mí wa àti ipò ìsinmi alálàáfíà ti ìbákẹ́gbẹ́ nígbà ìsinmi kúkúrú ti ọ̀sán. Ní ìbámu pẹ̀lú ète ìṣètò yí, dípò kíkúrò ní ilẹ̀ àpéjọ nígbà ìsinmi ọ̀sán láti lọ ra oúnjẹ, jọ̀wọ́ gbé nǹkan dání wá. Àwọn ìpápánu tí kì í mára wúwo tí a óò mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí wà fún kìkì àìní pàjáwìrì nìkan, a kò sì ní in lọ́kàn pé kí ó pèsè gbogbo oúnjẹ tí a ń fẹ́. Nípa báyìí, ìwọ yóò ní àkókò púpọ̀ sí i láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ. A fún ọ níṣìírí láti tẹ̀ lé ìṣètò yí kan náà tí àwọn ará wa ń tẹ̀ lé kárí ayé. Ní ṣíṣètò fún oúnjẹ rẹ ti ọ̀sán, fi àwọn tálákà àti aláìní sọ́kàn.
20 Ẹ wo bí a ti láyọ̀ tó pé àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́! Gbogbo wa fẹ́ láti rí i dájú pé a ti múra sílẹ̀ láti pésẹ̀ nígbà gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, kí a baà lè gbádùn àsè ńlá tí Jèhófà ti pèsè fún wa nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Lọ́nà yẹn, a óò mú wa “gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo” ní àwọn ọjọ́ tí ó wà níwájú.—2 Tím. 3:17.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè
Ìbatisí: Àwọn tí yóò ṣe batisí ní láti wà lórí ìjókòó wọn ní apá tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ṣáájú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Saturday. Olúkúlùkù ẹni tí ó wéwèé láti ṣe batisí ní láti mú aṣọ ìwẹ̀ tí ó bójú mu àti aṣọ ìnura wá. Ní ìgbà tí ó ti kọjá, àwọn kan ti wọ aṣọ tí kò yẹ, tí ó sì tàbùkù sí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àwọn alàgbà tí ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú ìwé Iṣetojọ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe batisí gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n lóye kókó wọ̀nyí. Kìkì àwọn tí wọ́n ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé nínú ìwé Ìmọ̀, tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà sì fọwọ́ sí ni kí a fún ní fọ́ọ̀mù Gbólóhùn Ọ̀rọ̀ Ìrìbọmi. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìbatisí, tí olùbánisọ̀rọ̀ sì ti gbàdúrà, alága ìjókòó yóò pe orin. Lẹ́yìn ìlà tí ó kẹ́yìn, àwọn olùṣàbójútó èrò yóò darí àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí lọ sí odò ìrìbọmi. Jọ̀wọ́ má ṣe fi ibi ìjókòó rẹ̀ sílẹ̀ ṣáájú kí alága ìjókòó tó kéde pé a mú ìjókòó náà wá sí ìparí. Pẹ̀lúpẹ̀lù, má ṣe sáré, tàbí rọ́ gìdì lọ sí ibi ìrìbọmi. Ìbatisí ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ ẹnì kan jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n, tí ó sì jẹ́ ti ara ẹni, láàárín ẹni náà àti Jèhófà. Nítorí náà, kò bá a mu fún àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí láti wà mọ́ ara wọn tàbí láti di ọwọ́ ara wọn mú nígbà tí a ń batisí wọn.
Káàdì Àyà: Jọ̀wọ́, fi káàdì àyà ti 1997 sí àyà ní gbogbo ìgbà tí o bá wà ní àpéjọpọ̀ náà àti nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ àti nígbà tí o bá ń darí bọ̀. Èyí sábà máa ń fún wa láǹfààní láti jẹ́rìí lọ́nà rere. O ní láti gba káàdì àyà àti ike rẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ rẹ, níwọ̀n bí wọn kì yóò ti wà ní àpéjọpọ̀ náà. Má ṣe dúró títí di àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú àpéjọpọ̀ kí o tó béèrè fún káàdì rẹ àti ti ìdílé rẹ. Rántí láti mú káàdì Advance Medical Directive/Release rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání.
Ilé Gbígbé: A tún ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbogbòò ní ti ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ pèsè. Bí a bá ré ìṣètò Society kọjá, tí a sì gba ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ ti gbà tẹ́lẹ̀, a ń jin iṣẹ́ àṣekára àwọn arákùnrin wa, tí wọ́n dúnàádúrà fún iye owó tí ó tẹ́ni lọ́rùn jù, lẹ́sẹ̀. BÍ O BÁ NÍ ÌṢÒRO LÓRÍ ILÉ IBÙWỌ̀, jọ̀wọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti mú un wá sí àfiyèsí alábòójútó Ẹ̀ka Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà, kí ó baà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀ràn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé àwọn fọ́ọ̀mù Special Needs Room Request ni a tètè fi ṣọwọ́ sí àdírẹ́sì àpéjọpọ̀ tí ó yẹ. Bí o bá ní láti fagi lé wíwọ̀ sí ilé ibùwọ̀ kan tí a ṣètò nípasẹ̀ ètò fún àwọn àìní àkànṣe, o ní láti fi tó onílé náà àti Ẹ̀ka Ilé Gbígbé àpéjọpọ̀ náà létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí a baà lè yan iyàrá náà fún ẹlòmíràn. MÁ ṢE fi àwọn fọ́ọ̀mù Room Request tí o ti kọ ọ̀rọ̀ kún ránṣẹ́ sí Society. Fi wọ́n ránṣẹ́ ní tààràtà sí Ẹ̀ka Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà ní lílo àdírẹ́sì tí ó yẹ tí ó wà lẹ́yìn fọ́ọ̀mù náà.
Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ìwọ ha lè ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà láti ṣèrànwọ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ bí? Sísin àwọn ará wa, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ fún kìkì wákàtí díẹ̀, yóò ṣèrànwọ́ gidigidi, yóò sì mú ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ wá. Bí o bá lè ṣèrànwọ́, jọ̀wọ́ fara hàn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ọdún 16 pẹ̀lú lè ṣe ìtìlẹ́yìn dáradára nípa ṣíṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí tàbí àgbàlagbà míràn tí ó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́.
Ìkìlọ̀: Wà lójúfò sí àwọn ìṣòro tí ó lè yọjú, kí o baà lè yẹra fún ìṣòro tí kò pọn dandan. Àwọn olè àti ènìyànkénìyàn sábà máa ń dọdẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jìnnà sí àyíká ilé wọn. Rí i dájú pé o ti ọkọ̀ rẹ pa nígbà gbogbo, má sì ṣe fi ohunkóhun tí ojú lè tó sílẹ̀ láti dẹ ẹnì kan wò láti jalè. Àwọn olè àti àwọn jáwójáwó máa ń fojú sun àwọn ìkórajọpọ̀ ńlá. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti fi ohunkóhun tí ó ṣe iyebíye sílẹ̀ lórí ìjókòó rẹ. Kò lè dá ọ lójú pé gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ ni ó jẹ́ Kristẹni. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi dẹ ẹnikẹ́ni wò? A ti rí ìròyìn gbà nípa ìgbìdánwò àwọn ará ìta kan láti tan àwọn ọmọdé lọ. JẸ́ KÍ ÀWỌN ỌMỌ RẸ WÀ LỌ́DỌ̀ RẸ NÍGBÀ GBOGBO.