ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 29
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 9/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September

ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àkókò àpéjọpọ̀. Àwọn ìjọ lè ṣe àtúnṣe tí ó yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” àti lẹ́yìn náà, fún àtúnyẹ̀wò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú lórí àwọn kókó ìtẹnumọ́ láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọpọ̀ àgbègbè ni kí a yàn ṣáájú fún arákùnrin títóótun méjì tàbí mẹ́ta tí yóò lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì. Àtúnyẹ̀wò tí a múra sílẹ̀ dáradára yìí yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì fún ìfisílò ara ẹni àti fún lílò nínú pápá. Àlàyé láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àti ìrírí tí a óò sọ gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí, kí ó sì ṣe tààràtà.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 1

Orin 26

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Fi Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣe Àkọ́kọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti wà tó, sọ̀rọ̀ lórí “Gbígbé Awọn Ohun Àkọ́múṣe Títọsúnà Kalẹ̀” nínú Jí!, August 22, 1987, ojú ìwé 8 àti 9.

20 min: “Ṣíṣàjọpín Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kárí ìpínrọ̀ 1 àti 6 sí 8. Ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 2 sí 5. Tẹnu mọ́ ríronú nípa sísọni di ọmọ ẹ̀yìn àti dídórí góńgó ti bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Orin 107 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 8

Orin 27

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

10 min: Àwọn àìní àdúgbò.

10 min: “Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Mú Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde.” Ọ̀rọ̀ àsọyé.

15 min: Alàgbà jíròrò “Sún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Síhà Ìyàsímímọ́ àti Batisí” (Àkìbọnú km-YR 6/96, ìpínrọ̀ 20 sí 22) pẹ̀lú àwọn akéde onírìírí tí wọ́n máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́.

Orin 109 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 15

Orin 30

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìnáwó.

15 min: Lo Fídíò Lọ́nà Rere. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá lórí lílo àwọn fídíò Society, kí o sì sọ àwọn ìrírí àdúgbò tí ń fi hàn bí a ṣe lè lo àwọn fídíò náà lọ́nà púpọ̀ sí i, nínú ìdílé wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ ti 1997.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 13) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 8, 10, àti 13. Láti inú Ìwé Mímọ́, tẹnu mọ́ bí ó ṣe ṣe pàtàkì láti fara balẹ̀ pa ìrísí àti ìwà Kristẹni wa tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì mọ́ àti láti bójú tó àwọn ọmọ wa lọ́nà yíyẹ.

Orin 162 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 22

Orin 165

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ ti 1997.” (Ìpínrọ̀ 14 sí 20) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 14 àti 18 àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Tẹnu mọ́ bí ó ti yẹ láti wà létòlétò, kí a sì fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì nígbà tí ó bá di ti àyè ìjókòó. Parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọyé ṣókí tí ń ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè.”

17 min: Ṣàyẹ̀wò Ìròyìn Ìjọ ti Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 1997. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn gbóríyìn fún ìjọ fún ìsapá rere, ní pàtàkì ní oṣù March, April, àti May. Pèsè àbá tí a fúnni láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn alàgbà àti láti inú ìròyìn alábòójútó àyìká tí ó ṣe kẹ́yìn fún mímú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀ sí i. Sọ àwọn góńgó gbígbéṣẹ́ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun, títí kan bíbẹ̀rẹ̀ àti dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àwọn oṣù tí ó ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún—November, May, August.

Orin 113 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 29

Orin 32

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ìjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Mẹ́nu kàn án pé a óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ayọ̀ Ìdílé ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀. Ní ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwé ìròyìn ní oṣù October, jíròrò àìní náà láti “Ṣàyẹ̀wò Ìpínlẹ̀ Rẹ Fínnífínní,” “Mọ Àwọn Ìwé Ìròyìn Náà Dáradára,” “Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Sílẹ̀,” “Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Onílé Mu,” àti “Ẹ Ran Ara Yín Lọ́wọ́” láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, ojú ìwé 8.

15 min: Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò. Púpọ̀ lára àṣeyọrí wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sinmi lórí mímú tí a bá lè mú àwọn ẹlòmíràn wọnú ìjíròrò tí ó nítumọ̀. Nígbà tí a bá lè sọ ohun kan tí ó mú kí àwọn ẹlòmíràn fetí sílẹ̀, a ti ṣẹ́pá ọ̀kan nínú àwọn ìdènà títóbi jù lọ tí a ń dojú kọ nínú ìjẹ́rìí. Bá àwùjọ jíròrò àwọn kókó pàtàkì nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ 16, ìpínrọ̀ 11 sí 14. Jẹ́ kí àwọn akéde tí wọ́n jáfáfá, tí wọ́n sì gbéṣẹ́ nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tí wọ́n lò nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, irú àwọn bíi (1) ẹni tí ń rìn lọ ní òpópónà, (2) èrò ọkọ̀ kan nínú bọ́ọ̀sì, (3) òǹtàjà kan lẹ́yìn káńtà ọjà, (4) òǹrajà kan níbi ìgbọ́kọ̀sí.

15 min: Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Lógo. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ láti inú Ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 81 sí 83. Béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì: (1) Báwo ni a ṣe ń jàǹfààní nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù? (2) Báwo ni ẹrù iṣẹ́ wa láti wàásù ti ṣe pàtàkì tó? (3) Ìsúnniṣe wo ni ó sún wa láti ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà? (4) Irú ìwà wo ni a ń béèrè bí ẹnì kan yóò bá sin Ọlọ́run? (5) Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ọ̀nà tí Jésù gbà wàásù?

Orin 121 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́