ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/97 ojú ìwé 1
  • Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Mú Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Mú Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀, Láìjẹ́ Pé Ẹnì Kan Fi Mí Mọ̀nà?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Apá Kìíní: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 9/97 ojú ìwé 1

Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Mú Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde

1 “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà béèrè lẹ́yìn tí Fílípì “polongo ìhìn rere nípa Jésù fún un.” (Ìṣe 8:27-39) Nínú ọ̀ràn ti ìwẹ̀fà náà, òun ti ní ìfẹ́ fún àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí ti Ọlọ́run tẹ́lẹ̀, lẹ́yìn tí ó sì ti gba ìrànwọ́ tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Fílípì, òun ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ìdánilójú pé wọ́n nílò fífúnra wọn ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́.

2 Ọpẹ́ ni pé ètò àjọ Jèhófà ti pèsè ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, láti fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò ìhìn iṣẹ́ Bíbélì fún ọjọ́ wa. Ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà yẹ kí ó fa àwọn olótìítọ́ inú mọ́ra, tí wọ́n lè má lè kàwé dáradára, tí wọn kò sì tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì. Ohun èlò dídára yìí ni a pète fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

3 Nígbà tí o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá dídára tí a tẹ̀ jáde nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, lórí bí a ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń méso jáde nínú ìwé Ìmọ̀ yóò ṣèrànwọ́. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀síwájú tí akẹ́kọ̀ọ́ ti ní kí o baà lè pinnu àgbègbè tí ń fẹ́ àfiyèsí síwájú sí i. Fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti máa múra ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ní wíwo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Àlàyé tí òun ṣe ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ lè fi ìmọrírì àtọkànwá tí òun ní fún òtítọ́ hàn. Àwọn tí ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Society ní àfikún sí i, tí wọ́n sì ń lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé sábà máa ń ní ìtẹ̀síwájú yíyára kánkán. Fún un níṣìírí láti máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láìjẹ́ bí àṣà nípa ohun tí òun ń kẹ́kọ̀ọ́. Fi inú rere fi ohun tí òun ní láti ṣe láti ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí hàn án. Kò yẹ kí a bá àwọn aláìnípinnu ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ títí lọ kánrin. Ó yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lo ìdánúṣe láti kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n mú ìdúró gbọn-in fún òtítọ́, kí wọ́n sì tẹ̀ síwájú sí ìyàsímímọ́ àti ìbatisí.

4 Ní àwọn agboolé kan, ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń darí ju ẹyọ kan lọ, níwọ̀n bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé ti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n, níní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àjùmọ̀ṣe lè dára jù nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn, níwọ̀n bí yóò ti ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé sún mọ́ra nípa tẹ̀mí.

5 Àṣẹ Jésù ni pé kí a lọ sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19) Láti ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n fi lè béèrè pé, “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́