ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/97 ojú ìwé 1
  • Fi Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣe Àkọ́kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣe Àkọ́kọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Olórí Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Máa Bá A Lọ Láìdáwọ́dúró Nínú Ìdílé Yín
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 9/97 ojú ìwé 1

Fi Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣe Àkọ́kọ́

1 Kí ni àwọn ohun díẹ̀ tí ó ṣe kókó fún ìlera wa nípa tẹ̀mí? Dájúdájú, ìwọ̀nyí yóò ní nínú, ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé, àdúrà láìsinmi, ìbákẹ́gbẹ́ rere, àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. A kò lè pa ìlera dídára nípa tẹ̀mí mọ́ bí a kò bá fi àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣáájú ní ìgbésí ayé wa.

2 Ṣùgbọ́n, gbogbo wa ní ìjà láti bá àwọn ìfẹ́ ọkàn ẹran ara jà, a sì nílò ìbáwí. (Gál. 5:17) A kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé a óò jèrè lọ́pọ̀lọpọ̀ bí a bá ń lépa àwọn ire onímọtara-ẹni-nìkan. (Jer. 17:9) Nítorí náà, bí a óò bá dáàbò bo ọkàn àyà wa kí a sì yẹra fún dídi ẹni tí a ṣì lọ́nà, ṣíṣe àyẹ̀wò ara ẹni déédéé ṣe pàtàkì.—Òwe 4:23; 2 Kọ́r. 13:5.

3 Ṣàyẹ̀wò Ọkàn Àyà Tìrẹ: Ìwọ lè ṣe èyí nípa bíbi ara rẹ léèrè àwọn ìbéèrè àìṣẹ̀tàn mélòó kan pé: Mo ha ń yán hànhàn láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí? (1 Pét. 2:2) Mo ha mọrírì ìjẹ́pàtàkì lílọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ bí? (Héb. 10:24, 25) Mo ha ń forí tì í nínú àdúrà bí? (Róòmù 12:12) Mo ha ń wá ìbákẹ́gbẹ́ àwọn ẹni tí ohun tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn bí? (Róòmù 1:11, 12) Mo ha nímọ̀lára pé ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún mi láti polongo ìhìn rere bí? (1 Kọ́r. 9:16) Dídáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni yóò fi hàn pé o fẹ́ láti fi àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ṣe àkọ́kọ́.

4 Ṣàyẹ̀wò Ìṣiṣẹ́ Rẹ Ojoojúmọ́: O ní láti ṣiṣẹ́ lórí àyẹ̀wò tí o ṣe lórí àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ nípa gbígbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀ ní ti lílo àkókò. Èyí kan ṣíṣètò àkókò fún kíka Bíbélì àti gbogbo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé, títí kan mímúrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé. A tún gbọ́dọ̀ ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìdílé láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì gbàdúrà pa pọ̀. Fi ààlà sí iye àkókò tí o ń lò níwájú tẹlifíṣọ̀n, lílo kọ̀ǹpútà, tàbí kí a kàn máa ṣèbẹ̀wò kí a sì máa rojọ́. Pinnu láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ, kí o sì ṣètò gbogbo ohun yòó kù yí wọn ká. Wéwèé fún gbogbo ìdílé láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

5 Láìṣiyèméjì, fífi àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ṣe àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wa yóò jẹ́ ìdí fún ayọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́