ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Júdà ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ (1-4)

      • Ìbùkún tó wà nínú gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà (5-8)

      • Ọkàn tó ń tanni jẹ (9-11)

      • Jèhófà jẹ́ ìrètí Ísírẹ́lì (12, 13)

      • Àdúrà Jeremáyà (14-18)

      • Jẹ́ kí Sábáàtì wà ní mímọ́ (19-27)

Jeremáyà 17:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gègé.”

Jeremáyà 17:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:7; 2Kr 24:18; 33:1, 3
  • +Ais 1:29; Isk 6:13

Jeremáyà 17:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:11, 13; Jer 15:13
  • +Le 26:30; Isk 6:3

Jeremáyà 17:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Nítorí ìbínú mi ti mú kí ẹ ràn bí iná.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 5:2
  • +Di 28:48; Jer 16:13
  • +Ais 5:25; Jer 15:14

Jeremáyà 17:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkùnrin alágbára.”

  • *

    Ní Héb., “tó fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:1, 2
  • +2Ọb 16:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 44

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 10

    8/15/1998, ojú ìwé 6

Jeremáyà 17:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkùnrin alágbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:8; 146:5; Ais 26:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 10

Jeremáyà 17:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 1:3; 92:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    9/2019, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2011, ojú ìwé 28

    3/15/2011, ojú ìwé 14

    3/1/2009, ojú ìwé 16-17

Jeremáyà 17:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣe békebèke.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kò ṣeé wò sàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:5; 8:21; Owe 28:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 43-45

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2004, ojú ìwé 11

    10/15/2001, ojú ìwé 25

    8/1/2001, ojú ìwé 9-10

    3/1/2000, ojú ìwé 30

Jeremáyà 17:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:7; 1Kr 28:9; Owe 17:3; 21:2
  • +Ro 2:6; Ga 6:7; Ifi 2:23; 22:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 9

Jeremáyà 17:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwà àìtọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 28:20; Ais 1:23; Jem 5:4

Jeremáyà 17:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 2:5; Ais 6:1

Jeremáyà 17:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lọ́dọ̀ mi,” ó jọ pé Jèhófà ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 73:27; Ais 1:28
  • +Jer 2:13; Ifi 22:1

Jeremáyà 17:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:20

Jeremáyà 17:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:19; 2Pe 3:4

Jeremáyà 17:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa wọ́n ní àpatúnpa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:15; 20:11
  • +Jer 18:23

Jeremáyà 17:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 7:2

Jeremáyà 17:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 13:19

Jeremáyà 17:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:9, 10; Le 23:3
  • +Ẹk 31:13

Jeremáyà 17:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:4; Isk 20:13

Jeremáyà 17:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:12-14

Jeremáyà 17:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 132:11
  • +Jer 22:4

Jeremáyà 17:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gúúsù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 32:44
  • +Jer 33:13
  • +Le 1:3
  • +Ẹsr 3:3
  • +Le 2:1, 2
  • +Sm 107:22; 116:17; Jer 33:10, 11

Jeremáyà 17:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:9, 10; Jer 39:8
  • +2Ọb 22:16, 17; Ida 4:11

Àwọn míì

Jer. 17:2Ond 3:7; 2Kr 24:18; 33:1, 3
Jer. 17:2Ais 1:29; Isk 6:13
Jer. 17:32Ọb 24:11, 13; Jer 15:13
Jer. 17:3Le 26:30; Isk 6:3
Jer. 17:4Ida 5:2
Jer. 17:4Di 28:48; Jer 16:13
Jer. 17:4Ais 5:25; Jer 15:14
Jer. 17:5Ais 30:1, 2
Jer. 17:52Ọb 16:7
Jer. 17:7Sm 34:8; 146:5; Ais 26:3
Jer. 17:8Sm 1:3; 92:12, 13
Jer. 17:9Jẹ 6:5; 8:21; Owe 28:26
Jer. 17:101Sa 16:7; 1Kr 28:9; Owe 17:3; 21:2
Jer. 17:10Ro 2:6; Ga 6:7; Ifi 2:23; 22:12
Jer. 17:11Owe 28:20; Ais 1:23; Jem 5:4
Jer. 17:122Kr 2:5; Ais 6:1
Jer. 17:13Sm 73:27; Ais 1:28
Jer. 17:13Jer 2:13; Ifi 22:1
Jer. 17:14Jer 15:20
Jer. 17:15Ais 5:19; 2Pe 3:4
Jer. 17:18Jer 15:15; 20:11
Jer. 17:18Jer 18:23
Jer. 17:19Jer 7:2
Jer. 17:21Ne 13:19
Jer. 17:22Ẹk 20:9, 10; Le 23:3
Jer. 17:22Ẹk 31:13
Jer. 17:23Ais 48:4; Isk 20:13
Jer. 17:24Di 5:12-14
Jer. 17:25Sm 132:11
Jer. 17:25Jer 22:4
Jer. 17:26Jer 32:44
Jer. 17:26Jer 33:13
Jer. 17:26Le 1:3
Jer. 17:26Ẹsr 3:3
Jer. 17:26Le 2:1, 2
Jer. 17:26Sm 107:22; 116:17; Jer 33:10, 11
Jer. 17:272Ọb 25:9, 10; Jer 39:8
Jer. 17:272Ọb 22:16, 17; Ida 4:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 17:1-27

Jeremáyà

17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a ti fi kálàmù* irin kọ sílẹ̀.

A ti fi ṣóńṣó dáyámọ́ǹdì fín in sára wàláà ọkàn wọn

Àti sára àwọn ìwo pẹpẹ wọn,

 2 Nígbà tí àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ wọn àti òpó òrìṣà* wọn+

Lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, lórí àwọn ibi tó ga,+

 3 Lórí àwọn òkè ní àwọn ìgbèríko tó tẹ́jú.

Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, gbogbo ìṣúra rẹ ni màá jẹ́ kí wọ́n kó lọ+

Títí kan àwọn ibi gíga rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+

 4 Ìwọ fúnra rẹ máa yọ̀ǹda ogún tí mo fún ọ.+

Màá sì mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò mọ̀,+

Nítorí o ti mú kí ìbínú mi ràn bí iná.*+

Yóò máa jó títí lọ.”

 5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ègún ni fún ọkùnrin* tó gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásánlàsàn,+

Tó gbára lé agbára èèyàn,*+

Tí ọkàn rẹ̀ sì pa dà lẹ́yìn Jèhófà.

 6 Yóò dà bí igi tó dá wà ní aṣálẹ̀.

Kò ní rí i nígbà tí ohun rere bá dé,

Ṣùgbọ́n àwọn ibi tó gbẹ nínú aginjù ni yóò máa gbé,

Ní ilẹ̀ iyọ̀ tí kò sí ẹnì kankan tó lè gbé ibẹ̀.

 7 Ìbùkún ni fún ọkùnrin* tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,

Ẹni tó fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ̀.+

 8 Yóò dà bí igi tí a gbìn sí etí omi,

Tó na gbòǹgbò rẹ̀ sínú odò.

Kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ooru bá dé,

Ṣùgbọ́n àwọn ewé rẹ̀ yóò máa tutù yọ̀yọ̀ ní gbogbo ìgbà.+

Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, kò ní ṣàníyàn,

Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yéé so èso.

 9 Ọkàn ń tanni jẹ* ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.*+

Ta ló lè mọ̀ ọ́n?

10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn,+

Mo sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú,*

Kí n lè san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀

Àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.+

11 Bí ẹyẹ àparò tó máa ń sàba lórí ẹyin tí kì í ṣe tirẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tó ń fi èrú* kó ọrọ̀ jọ.+

Wọ́n á fi í sílẹ̀ ní ọ̀sán gangan ayé rẹ̀,

Ní ìkẹyìn, á wá hàn pé òmùgọ̀ ni.”

12 Ìtẹ́ ológo tí a gbé ga láti ìbẹ̀rẹ̀,

Ni ibi mímọ́ wa jẹ́.+

13 Jèhófà, ìwọ ni ìrètí Ísírẹ́lì,

Ojú máa ti gbogbo àwọn tó bá fi ọ́ sílẹ̀.

Àwọn tó bá pẹ̀yìn dà lọ́dọ̀ rẹ* ni a ó kọ orúkọ wọn sórí eruku ilẹ̀,+

Torí pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ orísun omi ìyè.+

14 Wò mí sàn, Jèhófà, ara mi á sì dá.

Gbà mí là, màá sì rí ìgbàlà,+

Nítorí ìwọ ni èmi yóò máa yìn.

15 Wò ó! Àwọn kan ń sọ fún mi pé:

“Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà?+

Jọ̀wọ́, jẹ́ kó wá!”

16 Ṣùgbọ́n ní tèmi, mi ò sá kúrò lẹ́yìn rẹ bí mo ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn,

Mi ò sì máa retí pé kí ọjọ́ àjálù dé.

Gbogbo ohun tí mo fi ètè mi sọ lo mọ̀ dáadáa;

Ìṣojú rẹ ni gbogbo rẹ̀ wáyé!

17 Má ṣe jẹ́ ohun ẹ̀rù fún mi.

Ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ àjálù.

18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+

Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.

Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá wọn,

Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá mi.

Mú kí ọjọ́ àjálù dé bá wọn,+

Fọ́ wọn túútúú, kí o sì pa wọ́n run pátápátá.*

19 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ, kí o sì dúró ní ẹnubodè àwọn ọmọ èèyàn náà, èyí tí àwọn ọba Júdà ń gbà wọlé, tí wọ́n sì ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+ 20 Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹ̀ ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé. 21 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ ṣọ́ ara* yín, ẹ má sì ru ẹrù èyíkéyìí ní ọjọ́ Sábáàtì tàbí kí ẹ gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù wọlé.+ 22 Ẹ kò gbọ́dọ̀ gbé ẹrù kankan jáde láti inú ilé yín ní ọjọ́ Sábáàtì, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.+ Ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.+ 23 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀, wọ́n ya alágídí* kí wọ́n má bàa ṣègbọràn, kí wọ́n má sì gba ìbáwí.”’+

24 “‘“Àmọ́, bí ẹ bá ṣègbọràn sí mi délẹ̀délẹ̀,” ni Jèhófà wí, “tí ẹ kò gbé ẹrù kankan gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì, tí ẹ sì jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́ ní ti pé ẹ kò ṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,+ 25 nígbà náà, àwọn ọba àti àwọn ìjòyè, tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, àwọn àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, máa gba àwọn ẹnubodè ìlú yìí wọlé,+ àwọn èèyàn á sì máa gbé inú ìlú yìí títí láé. 26 Àwọn èèyàn á sì wá láti àwọn ìlú Júdà àti láti àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ + àti láti àwọn agbègbè olókè àti láti Négébù.* Wọ́n á máa mú odindi ẹbọ sísun + àti ẹbọ+ àti ọrẹ ọkà+ àti oje igi tùràrí wá, wọ́n á sì máa mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà.+

27 “‘“Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ jẹ́ kí ọjọ́ Sábáàtì máa jẹ́ mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù, tí ẹ sì ń gbé e gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì, ṣe ni màá sọ iná sí àwọn ẹnubodè rẹ̀, ó sì dájú pé á jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Jerúsálẹ́mù run,+ a kò sì ní pa iná náà.”’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́