Ẹ̀yin Olórí Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Máa Bá A Lọ Láìdáwọ́dúró Nínú Ìdílé Yín
1 Láìka ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tí Dáníẹ́lì fi gbé ní ilẹ̀ Bábílónì tó kún fún àṣà ìbọ̀rìṣà àti ìwà ìbàjẹ́ sí, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ó jẹ́ ẹni tó sin Jèhófà “láìyẹsẹ̀.” (Dán. 6:16, 20) Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún un láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí? Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gún régé fún àwọn ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa gbàdúrà nígbà mẹ́ta lóòjọ́ látinú yàrá tó wà lórí òrùlé rẹ̀. (Dán. 6:10) Kò sí àní-àní pé ó tún ní àwọn ètò tó fìdí múlẹ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí mìíràn, irú bíi kíka Òfin Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó dojú kọ àdánwò kan tó fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu, Dáníẹ́lì kò yẹsẹ̀ nínú ìfọkànsìn rẹ̀ sí Jèhófà, a sì dá ẹ̀mí rẹ̀ sí lọ́nà ìyanu.—Dán. 6:4-22.
2 Bákan náà ló rí lónìí, a gbọ́dọ̀ tiraka láti “wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀.” (Éfé. 6:18) ‘Abẹ́ agbára ẹni burúkú náà’ ni ayé tí à ń gbé inú rẹ̀ yìí wà. (1 Jòh. 5:19) Àtakò tàbí àdánwò lè yọjú lójijì kó sì dán ìgbàgbọ́ wa wò. Nígbà ìpọ́njú ńlá, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yóò fi gbogbo agbára rẹ̀ gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, yóò sì dà bí ẹni pé kò sọ́nà àbáyọ kankan. Èyí á béèrè fún ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà.—Ìsík. 38:14-16.
3 “Kọ́kọ́rọ́ ṣíṣekókó kan ni sísọ Bíbélì kíkà, kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àti jíjíròrò rẹ̀ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, di ọ̀nà ìgbésí ayé.” Èyí ni gbólóhùn tá a fi nasẹ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó wáyé ní àpéjọ àgbègbè ọdún 1998, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Ẹ̀yin Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Jẹ́ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Yín!” Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Nígbà tí àwọn ìdílé bá tẹ̀ lé irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀ déédéé, tí ó sì jẹ́ lọ́nà tí ó mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì dà bí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan déédéé tí a gbé ka Bíbélì yìí lè ní ipa àgbàyanu lórí ìdílé. Ó ń mú kí ìmọ̀ wa pọ̀ sí i. Ó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Ó sì ń pèsè àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún wa—àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ gidigidi nígbàanì—tí wọ́n lè ru wá sókè, kí wọ́n sún wa ṣiṣẹ́ láti gbèjà òtítọ́.” Bí a óò ti máa ṣàgbéyẹ̀wò oríṣiríṣi àwọn apá tó ní í ṣe pẹ̀lú níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó jíire fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, kí àwọn olórí ìdílé máa wo ọ̀nà kan tàbí méjì tí wọ́n lè gbà mú kí ètò tí wọ́n ṣe fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí nínú ìdílé wọn sunwọ̀n sí i.
4 Máa Gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yẹ̀ Wò Lójoojúmọ́: “Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso láìsí alátakò, tí a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run, kò ní sí eléwu ènìyàn mọ́—rárá, kò tiẹ̀ ní sí ẹranko abèṣe pàápàá—tí yóò ‘ṣe ìpalára èyíkéyìí tàbí tí yóò fa ìparun èyíkéyìí.’ (Aísá. 11:9; Mát. 6:9, 10)” Gbólóhùn yìí fara hàn nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2001, nínú àlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti September 11. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ ìtùnú gbáà ni ìránnilétí yìí jẹ́! Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, ṣé àṣà rẹ ni láti máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì àti àlàyé rẹ̀ lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìdílé rẹ? Èyí ń ṣàǹfààní gan-an ni. Bí kò bá ṣeé ṣe fún un yín láti jókòó pọ̀ ní òwúrọ̀, bóyá ẹ lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ alẹ́. Bàbá kan sọ pé: “Àkókò oúnjẹ alẹ́ ló rọrùn fún wa láti máa fi jíròrò ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́.”
5 Bó o bá ti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó múná dóko fún jíjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, a gbóríyìn fún ọ. Bóyá ẹ tún lè jàǹfààní sí i nípa kíka apá kan nínú Bíbélì ní àkókò yẹn kan náà. Àwọn kan ti sọ ọ́ di àṣà láti máa ka gbogbo orí Bíbélì níbi tá a ti mú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ náà jáde. Àwọn mìíràn máa ń ka Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, tí wọ́n á máa mú àwọn ìwé inú Bíbélì ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé. Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ á ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti ní ìbẹ̀rù àtọkànwá fún Jèhófà, wọn kò sì ní fẹ́ láti mú un bínú, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ wọn láti ṣe ohun tó wù ú á túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i.—Diu. 17:18-20.
6 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé rẹ fún kíka Bíbélì àti ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ á túbọ̀ ṣe yín láǹfààní gan-an bó o bá lè máa lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti jíròrò kókó pàtàkì tẹ́ ẹ lè mú lò nínú ìsọfúnni náà. Ìwé Ilé Ẹ̀kọ́, ní ojú ìwé 60, mú àbá yìí wá pé: “O lè yan àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ yẹn, kí o ṣàlàyé ìtumọ̀ rẹ̀, kí o sì wá béèrè àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: ‘Báwo ni èyí ṣe pèsè ìtọ́sọ́nà fún wa? Ọ̀nà wo la lè gbà lo ẹsẹ wọ̀nyí lóde ẹ̀rí? Kí ni wọ́n fi hàn nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe àwọn nǹkan, báwo ni ìyẹn sì ṣe mú kí a túbọ̀ mọyì rẹ̀?’” Irú àwọn ìjíròrò tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò ran gbogbo àwọn tó wà nínú agboolé rẹ lọ́wọ́ láti “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfé. 5:17.
7 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé: Dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an tí àwọn olórí ìdílé fi lè jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn rí i pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ní láti wà nípò àkọ́kọ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ pé: “Nígbà míì, á ti rẹ Dádì gan-an tó bá fi máa dé láti ibi iṣẹ́ tó fi jẹ́ pé agbára káká ló fi máa lè dá oorun mọ́jú, àmọ́ a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láìka èyí sí, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ ìjẹ́pàtàkì ìkẹ́kọ̀ọ́.” Àwọn ọmọ pẹ̀lú lè ṣe ipa tiwọn láti mú kí ìṣètò náà ṣàṣeyọrí. Ìdílé kan tó ní ọmọ mẹ́sàn-án máa ń jí ní aago márùn-ún àárọ̀ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn nítorí kò sí àkókò mìíràn tí wọ́n tún lè fi sí.
8 Kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó lè ṣàǹfààní, olórí ìdílé náà gbọ́dọ̀ ‘fiyè sí ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo.’ (1 Tím. 4:16) Ìwé Ilé Ẹ̀kọ́, ní ojú ìwé 32 sọ pé: “Ńṣe ni ká sọ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó gbéṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti orí fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìdílé rẹ fúnra rẹ. Báwo ni àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí? . . . Bí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá wà lóde ẹ̀rí, ṣé ó máa ń yá wọn lára láti sọ lójú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn? Ǹjẹ́ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà ti ìdílé ń gbádùn mọ́ wọn? Ǹjẹ́ wọ́n ń fi ọ̀nà Jèhófà ṣe ọ̀nà ìgbésí ayé wọn ní ti tòótọ́? Bí o bá fẹ̀sọ̀ ṣàkíyèsí wọn, wàá lè mọ ohun tí ìwọ olórí ìdílé ní láti ṣe láti lè gbin ànímọ́ tẹ̀mí sọ́kàn olúkúlùkù ẹni tó wà nínú ìdílé rẹ.”
9 Àwọn Ìpàdé Ìjọ: Ó yẹ kí mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀ àti pípésẹ̀ síbẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Láwọn ìgbà mìíràn, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti múra díẹ̀ lára àwọn apá ìpàdé náà sílẹ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ. Dípò tí wàá fi dúró di ìgbà tí àkókò bá ti lọ tán, ṣé o lè ṣètò láti ṣe ìmúrasílẹ̀ náà ṣáájú àkókò? Níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gún régé á jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ yín fún àwọn ìpàdé jẹ́ èyí tó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i, àwọn àǹfààní tẹ́ ẹ sì máa rí nínú àwọn ìpàdé náà á túbọ̀ pọ̀ sí i.—Òwe 21:5.
10 Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí kan yóò ṣe gbéṣẹ́ sí sinmi lórí bó ṣe múná dóko tó àti bó ṣe ń ṣe déédéé sí. Ká ní ipò àwọn nǹkan kò jẹ́ kó rọrùn fún ọ láti máa múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀ ńkọ́? Ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ ní ojú ìwé 31 dá àbá yìí pé: “Yẹra fún àṣìṣe pé kí o sáré ka ìwé yẹn fìrìfìrì láti kàn rí i pé o ṣáà kà á, tàbí àṣìṣe tó tiẹ̀ burú jù ìyẹn lọ, ìyẹn ni kí o tìtorí pé o kò ní lè ka gbogbo rẹ̀ tán kó o máà kúkú ka ìkankan rárá lára rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wo ìwọ̀nba tó o bá lè kà, kí o sì kà á dáadáa. Máa kà á bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tó bá yá, gbìyànjú láti máa kárí àwọn apá ìpàdé tí o kì í kárí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.”
11 Nígbà tí àwọn ìdílé bá tètè dé sí ìpàdé, èyí á jẹ́ kí wọ́n múra ọkàn wọn sílẹ̀ láti yin Jèhófà àti láti jàǹfààní látinú ìtọ́ni tó ń pèsè. Ṣé àṣà ìdílé rẹ ni láti máa tètè dé sí ìpàdé? Èyí ń béèrè fún ìwéwèé tó dára àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo ẹni tó wà nínú ìdílé. Bó o bá ti máa ń ṣàkíyèsí pé ìdílé rẹ máa ń sá sókè sá sódò láwọn ọjọ́ ìpàdé tí ara wọn kì í sì í balẹ̀, ṣé o lè ṣe àwọn àyípadà kan nínú ìgbòkègbodò yín? Ṣé àwọn nǹkan kan wà tẹ́ ẹ lè ṣe kó tó tó àsìkò ìpàdé? Bí iṣẹ́ bá pọ̀ jù fún ẹnì kan nínú ìdílé, ṣé àwọn tó kù lè ṣèrànwọ́? Ǹjẹ́ ara á túbọ̀ tù yín sí i ká ní gbogbo yín lẹ ti múra tán fún ìpàdé ní ó ku ìṣẹ́jú díẹ̀ kẹ́ ẹ jáde nílé? Ètò tó múná dóko máa ń túbọ̀ fi kún àlááfíà ìdílé àti ti ìjọ.—1 Kọ́r. 14:33, 40.
12 Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Ṣíṣètò àwọn àkókò pàtó kan fún kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún jẹ́ apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó jíire. Ọ̀dọ́langba kan tó ń jẹ́ Jayson sọ pé: “Nínú ìdílé wa, a sábà máa ń jáde òde ẹ̀rí ní àràárọ̀ Sátidé. Èyí ṣe mí láǹfààní gan-an nítorí pé bí mo ṣe túbọ̀ ń jáde òde ẹ̀rí ni mo túbọ̀ ń rí ohun rere tí iṣẹ́ náà ń ṣe láṣeyọrí, bẹ́ẹ̀ náà ni mo sì túbọ̀ ń gbádùn rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ àwọn tá a tọ́ dàgbà nínú ìdílé Ẹlẹ́rìí ti rí i pé, níní àkókò pàtó tí ìdílé yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristẹni.
13 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gún régé tún lè ṣèrànwọ́ láti mú kí àkókò tí ìdílé rẹ ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá túbọ̀ gbádùn mọ́ni, kó sì túbọ̀ méso jáde. Báwo lọwọ́ yín ṣe lè tẹ èyí? Ilé Ìṣọ́ July 1, 1999, ní ojú ìwé 21 dá àbá tó tẹ̀ lé e yìí pé: “Nígbà mìíràn, ǹjẹ́ ẹ máa ń lo àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín láti ran àwọn mẹ́ńbà ìdílé yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá tọ̀sẹ̀ náà? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní púpọ̀. (2 Tímótì 2:15) Ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìsìn wọn nítumọ̀, kó sì méso jáde. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ya odidi àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sọ́tọ̀ fún irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé o lè sọ̀rọ̀ ṣókí lórí apá tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá tàbí kó o sọ ọ́ ní àwọn àkókò mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀.” Ǹjẹ́ ìdílé rẹ ti gbìyànjú èyí?
14 Máa Bá A Lọ Ní Títẹ̀síwájú: Nínú àgbéyẹ̀wò tá a ṣe yìí, ṣé o ti rí àwọn àgbègbè tí ìdílé rẹ ti ń ṣe dáadáa? Gbóríyìn fún wọn, kẹ́ ẹ sì gbìyànjú láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i láwọn àgbègbè wọ̀nyí. Bó o bá rí àwọn àgbègbè bíi mélòó kan tó nílò àtúnṣe, mú ọ̀kan tàbí méjì nínú wọn láti ṣiṣẹ́ lé lórí lákọ̀ọ́kọ́. Tí àwọn wọ̀nyí bá ti wá di apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò tẹ̀mí tẹ́ ẹ̀ ń ṣe déédéé, tún ṣiṣẹ́ lórí ọ̀kan tàbí méjì sí i. Máa ní èrò rere lọ́kàn pé ẹ̀ ẹ́ kẹ́sẹ járí, kó o sì máa fòye bá ìdílé rẹ lò. (Fílí. 4:4, 5) Fífi ìdí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó gún régé múlẹ̀ nínú agboolé rẹ gba ọ̀pọ̀ ìsapá, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí Jèhófà mú un dá wa lójú pé: “Ní ti ẹni tí ń pa ọ̀nà tí a là sílẹ̀ mọ́, dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí ó rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run.”—Sm. 50:23.