Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Nípìn-ín Kíkún—Nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1 Òtítọ́ máa ń fi ìtumọ̀ tòótọ́ àti ète kún ìgbésí ayé ìdílé, ṣùgbọ́n àṣeyọrí nínú sísin Jèhófà kì í ṣàdédé wá. Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá láti gbé agboolé kan tí ó lágbára nípa tẹ̀mí ró. Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tímọ́tímọ́ láti ṣe èyí. Àpilẹ̀kọ yìí tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ alápá mẹ́ta yóò dá lórí bí àwọn ìdílé ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára dàgbà.
2 Nípa Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́: Òwe 24:5 sọ pé “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ . . . ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.” Ìmọ̀ tí ẹnì kan ń jèrè láti inú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ń fún un lókun inú tí ó nílò láti dènà ìkọlù tí Sátánì bá ṣe sí ipò tẹ̀mí rẹ̀. (Sm. 1:1, 2) Ǹjẹ́ ẹ máa ń ka Bíbélì pa pọ̀ lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé? Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ṣètòlẹ́sẹẹsẹ “Àfikún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. Títẹ̀lé e ń béèrè ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá nínú àkókò ìdílé lójoojúmọ́. Ẹ yan àkókò tí ó rọgbọ, irú bí ìgbà oúnjẹ àárọ̀, lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, tàbí ṣáájú kí ẹ tó lọ sùn, láti ka Bíbélì kí ẹ sì ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Ẹ sọ èyí di ara nǹkan tí ìdílé yín máa ń ṣe lójoojúmọ́.
3 Nípa Kíkẹ́kọ̀ọ́ Pa Pọ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé ni ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún ìdílé lọ́sẹ̀. Ó yẹ kí mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan ti èyí lẹ́yìn nípa fífi ìháragàgà nípìn-ín nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí olórí ìdílé ronú nípa àwọn àìní ìdílé nígbà tí ó bá ń yan àkójọ ọ̀rọ̀ tí wọn yóò kẹ́kọ̀ọ́ àti ọjọ́ òun àkókò tí wọn yóò máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti bí yóò ṣe gùn tó. Ẹ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní ìjẹ́pàtàkì gidigidi nínú ìṣètò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì dí i lọ́wọ́.—Fílí. 1:10, 11.
4 Bàbá kan tí ó sábà máa ń gba ìkésíni fóònù ní ilé fún iṣẹ́ ajé rẹ̀ máa ń yọ okùn tẹlifóònù náà lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí àwọn oníbàárà bá wá sí ilé rẹ̀, ó máa ń ké sí wọn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí kí wọ́n dúró di ìgbà tí àwọn bá ṣe tán. Bàbá náà pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun di ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lọ́wọ́. Èyí ní ipa jíjinlẹ̀ lórí àwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ajé rẹ̀ sì ń bú rẹ́kẹ́.
5 Ẹ wo bí ó ṣe ń dùn mọ́ni tó nígbà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí! Fífi ìṣòtítọ́ sapá láti nípìn-ín kíkún nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé yóò mú ìbùkún Jèhófà wá.—Sm. 1:3.