Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
1 Ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ tí Kristẹni òbí kan lè fún àwọn ọmọ rẹ̀ ni pé kó gbin irú ìfẹ́ tóun fúnra rẹ̀ ní fún Jèhófà sí wọn lọ́kàn. Ìgbà tó dára jù lọ tó o lè ṣe èyí ni “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ” lásìkò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Diu. 6:5-7) Yálà ọkọ tàbí aya rẹ jẹ́ Kristẹni bíi tìẹ, tàbí kí ẹ̀sìn ẹ̀yin méjèèjì má pa pọ̀, tàbí kó jẹ́ pé òbí anìkàntọ́mọ ni ọ́, o ṣì lè mú káwọn ọmọ rẹ sún mọ́ ọ kí wọ́n sì sún mọ́ Jèhófà, bó o bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ déédéé.
2 Bó O Ṣe Máa Bẹ̀rẹ̀: Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé kó o jẹ́ kí kíkẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ lára. Tó bá ṣòro láti mú àkókò kan tí ẹ ó máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ẹ ò ṣe jíròrò ẹ̀ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé? (Òwe 15:22) Bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣì kéré, o lè pinnu pé ẹ ò ní máa lo àkókò tó gùn ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan, àti pé ṣe lẹ fẹ́ máa ṣe é kúúkùùkú láàárín ọ̀sẹ̀. Ìṣètò tó máa rọ ìdílé rẹ lọ́rùn jù lọ ni kó o ṣe. Kọ àkókò pàtó tí ìdílé rẹ á máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kó o sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé e.
3 Kí lẹ lè fi máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ná? Àwọn kan máa ń múra ibi tá a máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ọ̀sẹ̀ yẹn sílẹ̀. Àwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tó bá dá lórí àwọn ọ̀dọ́. Baba kan tó ní ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan sọ pé: “Ohun kan tó máa ń jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ wa di àkókò táwọn ọmọ gbádùn jù lọ láàárín ọ̀sẹ̀ ni pé a máa ń fi àwọn ìtàn inú Iwe Itan Bibeli Mi ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́. Bó ṣe wọ̀ wọ́n lọ́kàn tó, àti bó ṣe yé wọn tó ṣe pàtàkì gidigidi ju iye ìpínrọ̀ tá a kà lọ.”
4 Ẹ Máa Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀: Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ségesège, ohun tí olúkúlùkù ń fayọ̀ retí ló sì yẹ kó jẹ́. Ó yẹ kí ọjọ́ àti àkókò tá à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè ṣeé yí padà nítorí ìgbà táwọn nǹkan tá a ò retí bá ṣẹlẹ̀. Ìgbà mìíràn sì lè wà tó máa gba pé ká yí kókó tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ padà. Ṣùgbọ́n o, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí ìyípadà ráńpẹ́ yẹn da ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tẹ́ ẹ ti ń bá bọ̀ rú o. Nínú ìdílé kan, ọmọbìnrin kan sọ pé: “Bó bá pọndandan láti yí àkókò tá à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ padà, Dádì sábà máa ń lẹ àkókò tuntun náà mọ́ ara ilẹ̀kùn fíríìjì, kí gbogbo wa lè mọ àkókò mìíràn tó máa jẹ́.” Àwọn wọ̀nyí mà káre láé fún ìsapá tí wọ́n ṣe kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn má bàa di ségesège! Bó o ṣe ń bá a nìṣó láti máa tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” ló ń fi bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ àti Baba wa ọ̀run tó hàn.—Éfé. 6:4.