Títẹ́wọ́gba Ẹrù Iṣẹ́ Bíbójútó Ìdílé
“Ẹ̀YIN, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọnnì tí a mí sí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbé ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ìdílé ka ibi ti ó yẹ ẹ́ ní kedere—ọrùn bàbá ni ó wà.
Nínú ìdílé púpọ̀ jù lọ, bàbá nìkan kọ́ ni ó ń bójú tó àwọn ọmọ. Aya rẹ̀, ìyá àwọn ọmọ rẹ̀, ń fi tayọ̀tayọ̀ ran ọkọ rẹ̀ lẹ́rù. Nípa báyìí, Sólómọ́nì Ọba polongo pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.”—Òwe 1:8.
Àbójútó Nípa ti Ara àti Tẹ̀mí
Àwọn òbí tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn kì í mọ̀ọ́mọ̀ pa wọ́n tì. Ní tòótọ́, kí àwọn Kristẹni ṣe bẹ́ẹ̀ yóò já sí sísẹ́ ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti lóye ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí Tímótì pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Àwọn Kristẹni mọ̀ pé títọ́ àwọn ọmọ dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” ń béèrè fún púpọ̀púpọ̀ ju pípèsè fún wọn nípa ti ara.
Ronú nípa ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n pabùdó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ó tún àwọn òfin Ọlọ́run sọ fún wọn, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni pe: “Kí ẹ sì fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí ọkàn-àyà yín àti ọkàn yín.” (Diutarónómì 11:18) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó ti rán wọn létí pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn-àyà wọn, ọkàn wọn, àti okunra wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fi kún un pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ.” (Diutarónómì 6:5, 6) Ó ṣe kókó pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ òbí jẹ́ kí Òfin Ọlọ́run wọ inú ọkàn-àyà wọn lọ. Pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó kún fún ìmọrírì nípa tẹ̀mí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ òbí lè ṣègbọràn lọ́nà gbígbéṣẹ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ Mósè tí ó tẹ̀ lé e: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n [àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin Ọlọ́run] sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:7; 11:19; fi wé Mátíù 12:34, 35.
Ṣàkíyèsí pé àwọn bàbá ní láti “fi ìtẹnumọ́ gbin” ọ̀rọ̀ wọnnì sínú ọmọ wọn kí wọ́n sì “máa sọ̀rọ̀ nípa wọn.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary, tú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “inculcate” sí “láti kọ́ni àti láti gbin nǹkan síni lọ́kàn nípasẹ̀ àsọtúnsọ tàbí ìṣílétí léraléra.” Nígbà tí àwọn òbí bá ń sọ̀rọ̀ nípa Òfin Ọlọ́run lójoojúmọ́—láàárọ̀, lọ́sàn-án, àti lálẹ́—wọ́n ń fi ohun púpọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn. Bí àwọn èwe náà ti rí ìfẹ́ tí àwọn òbí wọn ní fún Òfin Ọlọ́run, àwọn, ẹ̀wẹ̀, ni a sún láti ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Diutarónómì 6:24, 25) Ó gba àfiyèsí pé Mósè fún àwọn baba ní ìtọ́ni pàtó láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé wọn.’ Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara bíbójútó ìdílé. Ṣùgbọ́n lónìí ń kọ́?
“Nígbà Tí O Bá Jókòó Nínú Ilé Rẹ”
Janet, Kristẹni kan tí ó jẹ́ ìyá ọmọ mẹ́rin,a ṣàlàyé pé: “Kò rọrùn.” Paul, ọkọ rẹ̀, fohùn ṣọ̀kan, ó ní: “O gbọ́dọ̀ rọ́jú.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ òbí mìíràn tí í ṣe Ẹlẹ́rìí, Paul àti Janet ń sapá láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, ó kéré tán. “A máa ń gbìyànjú láti ṣe ìjíròrò Bíbélì ti ìdílé wa ní alaalẹ́ Monday ní àkókò pàtó tí a dá,” ni Paul ṣàlàyé, ó jẹ́wọ́ pé: “Kì í fi ìgbà gbogbo bọ́ sí i.” Gẹ́gẹ́ bí alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ rẹ̀, nígbà mìíràn a máa ń pè é lọ bójú tó àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe kánjúkánjú. Àwọn ọmọ rẹ̀ méjì tí ó dàgbà jù lọ ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Wọ́n rí i pé alaalẹ́ yẹn ni àkókò dídára jù fún ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé, wọ́n ti yí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn padà. Paul ṣàlàyé pé: “Nígbà mìíràn, a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wa gbàrà tí a bá ti jẹun alẹ́ tán.”
Bí àwọn òbí tilẹ̀ ń fi ọgbọ́n hàn nípa ṣíṣàì rinkinkin mọ́ àkókò tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, wọ́n ń gbìyànjú láti rí sí i pé ó ń lọ déédéé. Clare, ọmọ wọn obìnrin ṣàlàyé pé: “Bí ó bá pọndandan láti yí àkókò tí a ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ padà, Dádì sábà máa ń lẹ àkókò tuntun mọ́ ara ilẹ̀kùn fíríìjì, kí gbogbo wa lè mọ àkókò tí yóò jẹ́.”
Kíkórajọpọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tí a ń ṣe déédéé tún máa ń pèsè àǹfààní rere fún àwọn ọmọdé nínú ìdílé láti bá òbí wọn sọ̀rọ̀ nípa àníyàn àti ìṣòro wọn. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú ìyọrísí rere wá nígbà tí kò bá le tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ṣe ni àwọn èwe kàn ń ka ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a ń béèrè láti inú ìwé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Martin tí ó ní ọmọkùnrin méjì ṣàlàyé pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa jẹ́ àkókò àpérò.” Ó tún sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ láti jíròrò kókó kan láti inú Ìwé Mímọ́, ìwọ yóò mọ bí ìdílé rẹ ti ń ṣe sí nípa tẹ̀mí. Onírúurú nǹkan ni ó ń jẹ jáde nínú ìjíròrò. Ìwọ yóò mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́, ohun tí ó sì túbọ̀ gba àfiyèsí ni pé ìwọ yóò mọ irú ẹ̀mí tí àwọn ọmọ rẹ ń mú dàgbà.” Sandra, aya rẹ̀, fohùn ṣọ̀kan, òun náà ń rí ohun púpọ̀ kọ́ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ó ní: “Bí ọkọ mi ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ nípa fífetísí ọ̀nà tí àwọn ọmọ mi gbà ń dáhùn ìbéèrè.” Sandra yóò wá gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà tí yóò fi ran àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Ó ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an nítorí pé ó ń kópa nínú rẹ̀ dáadáa. Bẹ́ẹ̀ ni, sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé máa ń fún àwọn òbí ní àǹfààní láti fòye mọ ìrònú àwọn ọmọ wọn.—Òwe 16:23; 20:5.
Jẹ́ Ẹni Tí Ó Mọwọ́ Yí Padà, sì Ní Ìforítì
Nígbà tí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín bá tó, ẹ lè rí i pé ọmọ kan wà lójúfò, ó sì ń fọkàn bá a lọ, ṣùgbọ́n ó lè di dandan kí ẹ rọ ọmọ mìíràn kí ó tó lè pọkàn pọ̀, kí ó sì jàǹfààní. Kristẹni ìyá kan ṣàlàyé pé: “Bí ìgbésí ayé ìdílé ti rí nìyẹn! O mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí òbí. Nítorí náà nígbà tí o bá tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe é, Jèhófà yóò ṣèrànwọ́ yóò sì mú ìyọrísí rere wá.”
Àkókò tí ọ̀dọ́mọdé lè fi pọkàn pọ̀ lè yàtọ̀ gan-an ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀. Òbí tí ó ní ìfòyemọ̀ máa ń gba èyí rò. Tọkọtaya kan ní ọmọ márùn-ún, tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ láàárín ọmọ ọdún 6 sí 20. Michael, bàbá wọn, sọ pé: “Fún èyí àbúrò pátápátá ní àǹfààní láti kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ṣe àfikún àlàyé kí wọ́n sì sọ àwọn ohun tí wọ́n ti múra rẹ̀ sílẹ̀.” Fífi ìfòyemọ̀ bá àwọn ọmọ wọn lò lọ́nà yìí yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àwọn òbí láti kọ́ wọn ní ìjẹ́pàtàkì gbígba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Martin ṣàlàyé pé: “Ó lè yé ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa, ṣùgbọ́n ọmọ mìíràn lè nílò ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ kí ó tó lóye kókó náà. Mo ṣàkíyèsí pé ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ wá di ìgbà tí a ń kọ́ni ní sùúrù Kristẹni àti àwọn èso ti ẹ̀mí mìíràn.”—Gálátíà 5:22, 23; Fílípì 2:4.
Múra tán láti mọwọ́ yí padà bí agbára àti ipele ìdàgbà ọmọ rẹ ti ń yí padà. Simon àti Mark, tí í ṣe ọ̀dọ́langba nísinsìnyí, rí i pé nígbà tí wọ́n kéré, ní ti gidi wọ́n gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Wọ́n rántí pé: “Bàbá wa yóò mú kí a fi àwọn ìtàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe eré àwòkẹ́kọ̀ọ́.” Bàbá wọn rántí bí ó ti dawọ́ délẹ̀ tí ó sì tẹ eékún ba nígbà tí ó ń fi ìtàn ará Samáríà aládùúgbò rere ṣe eré àwòkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 10:30-35) “Ó wá jọ òótọ́ gan-an, ó sì ń mórí yá.”
Ọ̀pọ̀ ọmọ ni kì í jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣeé ṣe déédéé. Ó ha yẹ kí àwọn òbí tìtorí èyí dá ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí dúró nígbà tí wọ́n ń ṣe é? Rárá, bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Òwe 22:15 gbà pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin [tàbí, ọmọdébìnrin] ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” Ìyá kan tí í ṣe òbí ẹlẹ́nìkan-ṣoṣo rò pé òun ti kùnà gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nígbà tí ó jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà ni ìpínyà ọkàn máa ń da ìkẹ́kọ̀ọ́ rú. Ṣùgbọ́n ó forí tì í. Nísinsìnyí àwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, wọ́n sì wá mọrírì ìfẹ́ àti àníyàn tí ó fi hàn nípa títẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé.
Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwọn Ọmọdékùnrin àti Ọmọdébìnrin “Aláìníbaba”
Àwọn Kristẹni alàgbà ní láti máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:2, 3) Ṣíṣèbẹ̀wò látìgbàdégbà sọ́dọ̀ àwọn ìdílé tí ń bẹ nínú ìjọ wọn ń fún wọn ní àǹfààní láti gbóríyìn fún àwọn òbí tí ń ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Èjìká ta ni ẹrù iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọ tí ó jẹ́ ti òbí ẹlẹ́nìkan-ṣoṣo wà? Má gbàgbé láé pé ẹrù iṣẹ́ fífún àwọn ọmọ náà ní ìtọ́ni jẹ́ ti òbí náà.
Ọgbọ́n Kristẹni yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ipò tí ó lè fi àwọn ìlànà Kristẹni sínú ewu bí wọ́n bá tẹ́rí gba ipa òbí kejì tí kò sí mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin méjì lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Kristẹni arábìnrin tí ó jẹ́ òbí ẹlẹ́nìkan-ṣoṣo, wọn yóò máa kíyè sára nígbà gbogbo nínú ètò ìtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kíkésí àwọn ọmọ (àti, ní tòótọ́, òbí ẹlẹ́nìkan-ṣoṣo) láti dara pọ̀ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé alàgbà náà lè gbéni ró kí ó sì wúlò. Ṣùgbọ́n, má gbàgbé láé pé Jèhófà ni Bàbá wa ọ̀run gíga. Ó dájú pé ó wà nítòsí láti ṣamọ̀nà kí ó sì ṣèrànlọ́wọ́ fún ìyá náà nígbà tí ó bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ń dá ṣe é.
Bí ó bá ṣẹlẹ̀ ńkọ́, pé nǹkan tẹ̀mí ń jẹ ọ̀dọ́ kan lọ́kàn, ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ bìkítà tàbí tí wọn kò tilẹ̀ bìkítà rárá fún ẹrù iṣẹ́ wọn nípa tẹ̀mí? Kò yẹ kí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà sorí kodò. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ìwọ [Jèhófà Ọlọ́run] ni aláìrìnnàkore, ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́. Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 10:14) Ẹ̀wẹ̀, àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ yóò sa gbogbo ipá wọn láti fún àwọn òbí náà ní ìṣírí bí wọ́n ti ń bójú tó àwọn ọmọ wọn. Wọ́n lè dábàá ìjíròrò ìdílé kí wọ́n sì wà níbẹ̀ láti pèsè àwọn àbá tí ó ṣeé mú lò nípa bí a ṣe ń jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ṣá o, wọn kò ní gba ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí kúrò lọ́wọ́ wọn, nítorí èjìká àwọn òbí ọ̀hún ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó wà.
Àwọn ọmọ tí òbí wọn kò tẹ́wọ́ gba òtítọ́ nílò ọ̀pọ̀ ìtìlẹyìn. Pípè wọ́n sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ lè ṣàǹfààní bí àwọn òbí wọn bá gbà. Robert, tí ó ti dàgbà nísinsìnyí, tí ó sì ní ìdílé tirẹ̀, ń bá àwọn òbí rẹ̀ lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta péré. Inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tí ó bá rántí ìpàdé wọ̀nyẹn, àní lẹ́yìn tí àwọn òbí rẹ̀ ṣíwọ́ dídarapọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó pàdé ọmọdékùnrin kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ẹni tí ó mú un dání lọ sí àwọn ìpàdé náà. Àwọn òbí ọmọdékùnrin náà tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi tayọ̀tayọ̀ mú Robert wá sábẹ́ àbójútó wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ òrukàn nípa tẹ̀mí, wọ́n sì bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn náà. Ọpẹ́lọpẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ yìí, ó tẹ̀ síwájú ní kíákíá, nísinsìnyí ó ń gbádùn sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ.
Kódà nígbà tí àwọn òbí bá tako ìtẹ̀síwájú àwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà kò dá wà. Jèhófà ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ olóòótọ́ Baba ọ̀run. Sáàmù 68:5 polongo pé: “Baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba . . . ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.” Àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin aláìníbaba nípa tẹ̀mí mọ̀ pé àwọn lè yíjú sí i nínú àdúrà wọn, òun yóò sì gbé wọn ró. (Sáàmù 55:22; 146:9) Ètò-àjọ Jèhófà tí ó rí bí ìyá ń fi taratara ṣe ojúṣe rẹ̀ láti pèsè àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí ó gbádùn mọ́ni, èyí tí a ń gbé wá nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde rẹ̀ àti nínú àwọn ìpàdé tí a ń ṣe nínú àwọn ìjọ Kristẹni tí ó ju 85,000 kárí ayé. Nípa báyìí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, Baba wa, àti ètò àjọ rẹ̀ tí ó rí bí ìyá, àwọn “aláìníbaba” pàápàá yóò gbádùn àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ó yẹ kí a gbóríyìn fún àwọn Kristẹni òbí tí ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Àwọn òbí ẹlẹ́nìkan-ṣoṣo tí ń forí tì í nínú títọ́ àwọn èwe wọn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà yẹ fún àkànṣe àfiyèsí àti ìyìn nítorí àwọn ìsapá wọn. (Òwe 22:6) Gbogbo àwọn tí ń bìkítà fún àwọn ọmọ aláìníbaba nípa tẹ̀mí mọ̀ pé èyí dùn mọ́ Jèhófà, Baba wa ọ̀run nínú. Bíbójútó àwọn àìní ìdílé nípa tẹ̀mí jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wíwúwo. Ṣùgbọ́n ‘ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.’—Gálátíà 6:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ń pèsè àǹfààní rere fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ìdílé láti bá òbí wọn sọ̀rọ̀ nípa ìdàníyàn wọn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Harper’s