Ṣíṣèrántí Ikú Kristi Jákèjádò Ayé
1 Jèhófà ti fún wa ní ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀bùn. A ṣàpèjúwe àpapọ̀ oore àti ìfẹ́ inú rere rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere bí “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” Òótọ́ ni, “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” jẹ́ àgbàyanu tó bẹ́ẹ̀ tó fi kọjá ohun táa lè ṣàpèjúwe.—2 Kọ́r. 9:14, 15.
2 Ẹ̀bùn Rẹ̀ Tó Tóbi Jù Lọ: Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà aráyé, ni ẹ̀bùn tó tóbi ju gbogbo ẹ̀bùn lọ. Láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí aráyé, Jèhófà fúnni ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo tó jẹ́ ààyò olùfẹ́. (Jòh. 3:16) Jákèjádò ayé, ó yẹ ká ṣèrántí irú ìbùkún tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbà wo ló yẹ ká ṣe é báwo ló sì ṣe yẹ ká ṣe é? Ní àṣálẹ́ ọjọ́ Thursday, April 1, 1999, àwọn Kristẹni yíká ayé yóò ṣèrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, wọn yóò ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ìrúbọ tó tóbi jù lọ yìí.—1 Kọ́r. 11:20, 23-26.
3 Kristi kú fún wa àní “nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀” pàápàá, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì lè fi ìmoore hàn nípa ṣíṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ àti nípa kíké sí àwọn ẹlòmíràn láti wá bá wa ṣe ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì gidigidi náà.—Róòmù 5:8.
4 Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ: Ṣíṣayẹyẹ ikú Kristi tẹnu mọ́ ọn ní pàtàkì pé ó dìrọ̀ mọ́ ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run láìlálèébù. Ó tún rán wa létí pé a lè gbádùn ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù kí ìgbàlà sì tipa bẹ́ẹ̀ dájú fún wa. (Ìṣe 4:12) Ní tòótọ́, èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún!
5 Kíké tí a ń ké sí àwọn aládùúgbò wa pé kí wọ́n wá bá wa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Àǹfààní ìràpadà náà ṣì wà fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìníyelórí rẹ̀ títayọ lọ́lá. (Fílí. 3:8) Àwọn tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Kristi lè jèrè ìrètí lílẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ti ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.
6 Àkókò Ìṣe Ìrántí ń pèsè àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ fún wa láti fi ìmọrírì hàn fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tó ju inú rere gbogbo lọ. Àkókò to dára jù lọ nìyí láti fi ìtara nípìn-ín nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àǹfààní púpọ̀ ń dúró de gbogbo àwọn tó bá ronú tàdúràtàdúrà nípa ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Jèhófà aláìṣeé-ṣàpèjúwe tí wọ́n sì ṣètò láti wà níbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tọdún yìí!