ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kọ́ríńtì 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kọ́ríńtì

      • “Ẹ máa fara wé mi” (1)

      • Ipò orí àti bíbo orí (2-16)

      • Ṣíṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (17-34)

1 Kọ́ríńtì 11:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 3:17; 2Tẹ 3:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2010, ojú ìwé 12

1 Kọ́ríńtì 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/1/1995, ojú ìwé 3-4

1 Kọ́ríńtì 11:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 14:9; Ef 4:15; Kol 2:10
  • +Ef 5:23; 1Pe 3:1
  • +1Kọ 15:27, 28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2021, ojú ìwé 2-3

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2015, ojú ìwé 22-23

    5/15/2010, ojú ìwé 8-16

    5/15/2009, ojú ìwé 20

    2/15/2007, ojú ìwé 13-17

    1/15/2007, ojú ìwé 6

    8/1/1999, ojú ìwé 19-20

    9/1/1998, ojú ìwé 15

    6/1/1995, ojú ìwé 27

    7/1/1994, ojú ìwé 21

    Jí!,

    7/8/2004, ojú ìwé 22-23

    12/8/1996, ojú ìwé 15

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 153-154

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 31-32

    Ìmọ̀, ojú ìwé 134-136

1 Kọ́ríńtì 11:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:28; Iṣe 21:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 209-210

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2009, ojú ìwé 12-13

    7/15/2002, ojú ìwé 26-27

1 Kọ́ríńtì 11:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Yiyan, ojú ìwé 80

1 Kọ́ríńtì 11:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:22, 23

1 Kọ́ríńtì 11:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:18

1 Kọ́ríńtì 11:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 4:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 211-212

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2009, ojú ìwé 24

    7/15/2002, ojú ìwé 27

1 Kọ́ríńtì 11:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:21, 22
  • +1Kọ 8:6

1 Kọ́ríńtì 11:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:29, 30; 1Kọ 1:12; 1Ti 4:1; 2Pe 2:1

1 Kọ́ríńtì 11:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 22:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 28

1 Kọ́ríńtì 11:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:20; Lk 22:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 4

    2/15/2003, ojú ìwé 12-13

    3/15/1993, ojú ìwé 4

1 Kọ́ríńtì 11:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:26; Mk 14:22; Ro 7:4; 1Kọ 10:17
  • +Lk 22:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2013, ojú ìwé 24-25

    3/15/2004, ojú ìwé 4

    3/15/1994, ojú ìwé 3-4

    3/15/1993, ojú ìwé 5-6

1 Kọ́ríńtì 11:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí a dá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:27; Mk 14:23; 1Kọ 10:16
  • +Jer 31:31; Heb 8:8; 9:15
  • +Lk 22:20; Heb 9:13, 14; 1Pe 1:18, 19
  • +Ẹk 12:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2013, ojú ìwé 25

    1/1/2003, ojú ìwé 31

    3/15/1994, ojú ìwé 3-4

    3/15/1993, ojú ìwé 6

1 Kọ́ríńtì 11:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 16

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 27

    7/15/2008, ojú ìwé 27

    3/15/2004, ojú ìwé 6-7

    4/1/2003, ojú ìwé 6

    2/15/2003, ojú ìwé 13

    1/1/2003, ojú ìwé 31

    3/15/1993, ojú ìwé 4-5

1 Kọ́ríńtì 11:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2020, ojú ìwé 27-28

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2016, ojú ìwé 21-22

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 15-16

    2/15/2003, ojú ìwé 17-19

    4/1/1996, ojú ìwé 6-8

1 Kọ́ríńtì 11:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 13:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 15

    3/15/1991, ojú ìwé 21-22

1 Kọ́ríńtì 11:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣe kedere pé ikú nípa tẹ̀mí ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 5:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 15

1 Kọ́ríńtì 11:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 12:5
  • +2Pe 2:20; 3:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2019, ojú ìwé 7

1 Kọ́ríńtì 11:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:29

Àwọn míì

1 Kọ́r. 11:1Flp 3:17; 2Tẹ 3:9
1 Kọ́r. 11:3Ro 14:9; Ef 4:15; Kol 2:10
1 Kọ́r. 11:3Ef 5:23; 1Pe 3:1
1 Kọ́r. 11:31Kọ 15:27, 28
1 Kọ́r. 11:5Joẹ 2:28; Iṣe 21:8, 9
1 Kọ́r. 11:7Jẹ 1:27
1 Kọ́r. 11:8Jẹ 2:22, 23
1 Kọ́r. 11:9Jẹ 2:18
1 Kọ́r. 11:101Kọ 4:9
1 Kọ́r. 11:12Jẹ 2:21, 22
1 Kọ́r. 11:121Kọ 8:6
1 Kọ́r. 11:19Iṣe 20:29, 30; 1Kọ 1:12; 1Ti 4:1; 2Pe 2:1
1 Kọ́r. 11:20Lk 22:19, 20
1 Kọ́r. 11:23Mt 26:20; Lk 22:14
1 Kọ́r. 11:24Mt 26:26; Mk 14:22; Ro 7:4; 1Kọ 10:17
1 Kọ́r. 11:24Lk 22:19
1 Kọ́r. 11:25Mt 26:27; Mk 14:23; 1Kọ 10:16
1 Kọ́r. 11:25Jer 31:31; Heb 8:8; 9:15
1 Kọ́r. 11:25Lk 22:20; Heb 9:13, 14; 1Pe 1:18, 19
1 Kọ́r. 11:25Ẹk 12:14
1 Kọ́r. 11:282Kọ 13:5
1 Kọ́r. 11:301Tẹ 5:6
1 Kọ́r. 11:32Heb 12:5
1 Kọ́r. 11:322Pe 2:20; 3:7
1 Kọ́r. 11:341Kọ 11:29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kọ́ríńtì 11:1-34

Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

11 Ẹ máa fara wé mi, bí èmi náà ṣe ń fara wé Kristi.+

2 Mo gbóríyìn fún yín nítorí nínú ohun gbogbo, ẹ̀ ń rántí mi, ẹ sì di àwọn àṣà tí mo fi lé yín lọ́wọ́ mú ṣinṣin. 3 Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; + bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin;+ bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.+ 4 Gbogbo ọkùnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, tó sì fi nǹkan borí ń dójú ti orí rẹ̀; 5 àmọ́ gbogbo obìnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ tẹ́lẹ̀+ láìborí ń dójú ti orí rẹ̀, nítorí bákan náà ló rí pẹ̀lú obìnrin tó fárí. 6 Nítorí tí obìnrin kò bá borí, kí ó gé irun rẹ̀; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun ìtìjú fún obìnrin láti gé irun tàbí kí ó fárí, ó yẹ kí ó borí.

7 Nítorí kò yẹ kí ọkùnrin borí, torí ó jẹ́ àwòrán+ àti ògo Ọlọ́run, àmọ́ obìnrin jẹ́ ògo ọkùnrin. 8 Torí ọkùnrin kò wá láti ara obìnrin, àmọ́ obìnrin wá láti ara ọkùnrin.+ 9 Àti pé, a kò dá ọkùnrin nítorí obìnrin, àmọ́ a dá obìnrin nítorí ọkùnrin.+ 10 Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí obìnrin ní àmì àṣẹ ní orí rẹ̀, nítorí àwọn áńgẹ́lì.+

11 Yàtọ̀ síyẹn, nínú Olúwa, kò sí obìnrin láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọkùnrin láìsí obìnrin. 12 Nítorí bí obìnrin ṣe wá láti ara ọkùnrin,+ bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ṣe wá nípasẹ̀ obìnrin; àmọ́ ohun gbogbo wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 13 Ẹ fúnra yín pinnu: Ṣé ó yẹ kí obìnrin gbàdúrà sí Ọlọ́run láìborí? 14 Ṣé ìwà ẹ̀dá fúnra rẹ̀ kò kọ́ yín pé àbùkù ni irun gígùn jẹ́ fún ọkùnrin, 15 àmọ́ tí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un? Nítorí irun rẹ̀ ni a fún un dípò ìbòrí. 16 Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni ò bá fara mọ́ àṣà yìí, a ò ní àṣà míì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ Ọlọ́run kò ní.

17 Àmọ́ bí mo ṣe ń fún yín ní àwọn ìtọ́ni yìí, mi ò gbóríyìn fún yín, nítorí kì í ṣe kí nǹkan lè dáa sí i lẹ ṣe ń pé jọ, kó lè burú sí i ni. 18 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá kóra jọ nínú ìjọ, ìpínyà máa ń wà láàárín yín; mo sì gbà á gbọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. 19 Ó dájú pé àwọn ẹ̀ya ìsìn tún máa wà láàárín yín,+ kí àwọn tí a tẹ́wọ́ gbà nínú yín lè fara hàn kedere.

20 Nígbà tí ẹ bá kóra jọ sí ibì kan, kì í wulẹ̀ ṣe láti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.+ 21 Torí nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́, kálukú á ti jẹ oúnjẹ alẹ́ tirẹ̀ ṣáájú, tó fi jẹ́ pé ebi á máa pa ẹnì kan, àmọ́ ọtí á máa pa ẹlòmíì. 22 Ṣé ẹ ò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ kí ẹ sì máa mu ni? Àbí ẹ̀ ń fojú pa ìjọ Ọlọ́run rẹ́, tí ẹ wá ń dójú ti àwọn tí kò ní nǹkan kan? Kí ni mo fẹ́ sọ fún yín? Ṣé kí n gbóríyìn fún yín ni? Lórí èyí, mi ò gbóríyìn fún yín.

23 Nítorí ọwọ́ Olúwa ni mo ti gba èyí tí mo fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú búrẹ́dì ní alẹ́ ọjọ́+ tí a ó dalẹ̀ rẹ̀, 24 lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 25 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 26 Nítorí nígbàkigbà tí ẹ bá ń jẹ búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Olúwa, títí á fi dé.

27 Nítorí náà, ẹni tó bá jẹ búrẹ́dì náà tàbí tó mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Kí èèyàn kọ́kọ́ dá ara rẹ̀ lójú lẹ́yìn tó bá ti yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa,+ ẹ̀yìn ìgbà yẹn nìkan ni kó jẹ nínú búrẹ́dì náà, kó sì mu nínú ife náà. 29 Nítorí ẹni tó bá ń jẹ, tó sì ń mu, láìfi òye mọ ohun tí ara náà jẹ́, ó ń jẹ, ó sì ń mu ìdájọ́ sórí ara rẹ̀. 30 Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ nínú yín fi jẹ́ aláìlera àti aláìsàn, tí àwọn díẹ̀ sì ń sùn nínú ikú.*+ 31 Àmọ́ tí a bá fi òye mọ ẹni tí àwa fúnra wa jẹ́, a ò ní dá wa lẹ́jọ́. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, Jèhófà* ló ń bá wa wí,+ kí a má bàa dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.+ 33 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá kóra jọ láti jẹ ẹ́, ẹ dúró de ara yín. 34 Tí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun nílé, kí ẹ má bàa kóra jọ fún ìdájọ́.+ Àmọ́ ní ti àwọn ọ̀ràn tó kù, màá bójú tó wọn nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́