ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/11 ojú ìwé 3-6
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjọsìn Ìdílé—Ǹjẹ́ O Lè Mú Kó Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Ní Ìmúratán”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 1/11 ojú ìwé 3-6

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé

1. Báwo ni Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe ṣàǹfààní fún àwọn ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

1 Jèhófà ló fìfẹ́ ṣètò pé kí àwọn ìdílé ní Ísírẹ́lì máa pa Sábáàtì mọ́, kó lè ṣe wọ́n láǹfààní. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ yìí, ńṣe ni wọn máa ń sinmi, ó sì máa ń fún wọn láyè láti ronú lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wọn àti àjọṣe wọn pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n tún lè fi àkókò yẹn gbin Òfin Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. (Diu. 6:6, 7) Ọjọ́ Sábáàtì máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn Jèhófà gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

2. Ẹ̀kọ́ wo ni Sábáàtì kọ́ wa nípa Jèhófà?

2 Lóòótọ́ o, Jèhófà kò rétí pé kí àwọn ìdílé lóde òní máa pa Sábáàtì mọ́ o. Àmọ́, òfin yẹn kọ́ wa ní ohun kan nípa Ọlọ́run. Gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ máa ń jẹ́ ẹ lógún, ó sì nífẹ̀ẹ́ sí ire wọn nípa tẹ̀mí. (Aísá. 48:17, 18) Ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn òun lóde òní jẹ́ òun lógún jẹ́ nípasẹ̀ Ìjọsìn Ìdílé.

3. Kí nìdí tá a fi ṣètò Ìjọsìn Ìdílé ìrọ̀lẹ́?

3 Kí Nìdí Tá A Fi Ṣètò Ìjọsìn Ìdílé Ìrọ̀lẹ́? Ní oṣù January ọdún 2009, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ lọ́jọ́ kan náà tá à ń ṣe ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ṣe àtúnṣe yìí ni láti fún àwọn ìdílé láǹfààní láti mú kí ipò tẹ̀mí wọn lágbára sí i nípa ṣíṣètò ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé. A fún ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ìṣírí láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tẹ́lẹ̀, tó bá ṣeé ṣe, kí wọ́n sì lo àkókò yìí láti fi jíròrò Bíbélì láìjẹ́ pé wọ́n á máa kánjú, kí wọ́n sì ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tó máa bá ohun tí ìdílé wọn nílò mu.

4. Ṣé dandan ni pé wákàtí kan làwọn ìdílé fi gbọ́dọ̀ ṣe Ìjọsìn Ìdílé wọn? Ṣàlàyé.

4 Kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti pésẹ̀ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, á nílò àkókò láti múra, ó sì tún máa ń gba àkókò ká tó dé ibi tá a ti máa ṣe é. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló jẹ́ pé, àtilọ-àtibọ̀ wa sí ìpàdé tá a máa ṣe fún wákàtí kan yìí máa ń gba àkókò tó pọ̀ lọ́wọ́ wa. Àmọ́, ní báyìí tá a ti ṣàtúnṣe sí ọ̀nà tá à ń gbà ṣèpàdé, ó ṣeé ṣe fún wa láti lo àkókò yẹn fún jíjọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Torí náà, kò pọn dandan pé wákàtí kan péré la gbọ́dọ̀ fi ṣe Ìjọsìn Ìdílé wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ronú lórí ohun tí ìdílé wa nílò àti ibi tí agbára wọn bá lè gbé e dé láti fi pinnu iye àkókò tí a ó máa fi ṣe Ìjọsìn Ìdílé wa.

5. Ǹjẹ́ ó pọn dandan pé ìjíròrò nìkan la gbọ́dọ̀ lo gbogbo àkókò Ìjọsìn Ìdílé wa fún? Ṣàlàyé.

5 Ǹjẹ́ Ìjíròrò Nìkan La Gbọ́dọ̀ Lo Gbogbo Àkókò Ìjọsìn Ìdílé Wa Fún? Bí àwọn tọkọtaya tí kò lọ́mọ àti àwọn ìdílé tó lọ́mọ bá jíròrò àwọn kókó kan pa pọ̀ látinú Ìwé Mímọ́, wọ́n á fún ara wọn ní ìṣírí. (Róòmù 1:12) Ìdílé náà á sì sún mọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí. Torí náà, jíjíròrò Ìwé Mímọ́ ló yẹ kó gba ipò àkọ́kọ́ nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Àmọ́ ṣá o, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lè dá kẹ́kọ̀ọ́ fúnra rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ìdílé bá ti parí ìjíròrò, wọ́n ṣì lè jókòó pa pọ̀ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ láyè ara rẹ̀, bóyá kó parí ìmúrasílẹ̀ fún ìpàdé tàbí kó ka àwọn ìwé ìròyìn wa. Kódà, àwọn ìdílé kan kì í tan tẹlifíṣọ̀n rárá lálẹ́ ọjọ́ náà.

6. Báwo la ṣe lè máa darí Ìjọsìn Ìdílé?

6 Báwo La Ṣe Lè Máa Darí Ìjọsìn Ìdílé? Kò pọn dandan kó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn lẹ ó máa ṣe ní gbogbo ìgbà. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti ṣe ètò tó fẹ́ jọ ti ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀, kí wọ́n bàa lè mú kí Ìjọsìn Ìdílé gbádùn mọ́ni, kó sì tura. Wọ́n máa ń pín ìjíròrò wọn sí apá bíi mélòó kan, wọ́n sì máa ń bójú tó o láwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ka Bíbélì pa pọ̀, wọ́n lè múra àwọn apá ìpàdé kan sílẹ̀, kí wọ́n sì múra ohun tí wọ́n máa sọ lóde ẹ̀rí sílẹ̀. Àwọn àbá díẹ̀ wà lójú ìwé 6.

7. Kí ló yẹ káwọn òbí fi sọ́kàn nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan máa rí nígbà Ìjọsìn Ìdílé?

7 Kí Ló Yẹ Káwọn Òbí Fi Sọ́kàn Nípa Bó Ṣe Yẹ Kí Nǹkan Rí Nígbà Ìjọsìn Ìdílé? Ìdílé rẹ á kẹ́kọ̀ọ́ tó jíire bí o bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tó o sì jẹ́ kára tù wọ́n. Kódà, ẹ lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìta bí ojú ọjọ́ bá dára. Kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àwọn ìdílé kan tiẹ̀ máa ń jẹ́ ìpápánu lẹ́yìn Ìjọsìn Ìdílé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí ní láti yẹra fún lílo àkókò Ìjọsìn Ìdílé láti fi bá àwọn ọmọ wí, síbẹ̀ ó lè gba pé kí wọ́n ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti fi sọ̀rọ̀ lórí àṣà kan tàbí ìṣòrò kan tó wá sí àfiyèsí wọn. Àmọ́ ohun tó dára jù lọ ni pé kẹ́ ẹ jíròrò ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ tara ẹni pẹ̀lú ọmọ tọ́rọ̀ kàn ní ìdákọ́ńkọ́ ní àkókò míì láàárín ọ̀sẹ̀, kí ẹ má bàa dójú tì í lójú àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀. Kò yẹ kí Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ohun tó ń súni tàbí èyí tó le koko, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run aláyọ̀ là ń jọ́sìn.—1 Tím. 1:11.

8, 9. Ìmúrasílẹ̀ wo ló yẹ káwọn olórí ìdílé máa ṣe?

8 Báwo Ni Olórí Ìdílé Ṣe Lè Múra Sílẹ̀? Ìdílé á jàǹfààní gan-an bí olórí ìdílé bá ń múra sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé, kó ti pinnu ohun tí wọ́n máa jíròrò àti ọ̀nà tó dára jù lọ tí wọ́n máa gbà jíròrò rẹ̀. (Òwe 21:5) Ó máa dára gan-an kí ọkọ béèrè lọ́wọ́ ìyàwó rẹ̀ bóyá ó ní ohun kan lọ́kàn tó máa fẹ́ kí àwọn jíròrò. (Òwe 15:22) Àwọn olórí ìdílé lè sọ pé kí àwọn ọmọ wọn dábàá ohun tí wọ́n máa fẹ́ kẹ́ ẹ jíròrò. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ṣeé ṣe fún ẹ láti mọ ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn.

9 Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè má pọn dandan fún olórí ìdílé láti lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi múra sílẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìdílé gbádùn ohun kan tí wọ́n máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ kò ní pọn dandan kí olórí ìdílé máa ṣe ètò tuntun ní gbogbo ìgbà. Ó lè rí i pé ó máa ṣàǹfààní kí òun múra sílẹ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ní gbàrà tí wọ́n bá parí Ìjọsìn Ìdílé wọn, torí pé ohun tí ìdílé wọn nílò nípa tẹ̀mí á ṣì wà lọ́kàn rẹ̀. Àwọn olórí ìdílé kan máa ń kọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tí wọ́n máa jíròrò, wọ́n á sì fi sí ibi tí gbogbo ìdílé ti lè rí i, irú bíi kí wọ́n lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara fìríìjì. Èyí máa ń jẹ́ kí ara àwọn tó wà nínú ìdílé yá gágá, kí wọ́n sì máa fojú sọ́nà, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè múra sílẹ̀ tó bá pọn dandan.

10. Kí ni àwọn tó ń dá gbé lè máa ṣe ní àkókò Ìjọsìn Ìdílé?

10 Àwọn Tó Ń Dá Gbé Tàbí Tó Jẹ́ Pé Àwọn Nìkan Ni Kristẹni Nínú Ilé Wọn Ń Kọ́? Àwọn tó ń dá gbé tàbí tó jẹ́ pé àwọn nìkan ni Kristẹni nínú ilé wọn lè lo àkókò Ìjọsìn Ìdílé wọn láti ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Lára ètò tí wọ́n lè ṣe fún irú ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jíire bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n ka Bíbélì, kí wọ́n múra ìpàdé sílẹ̀ àti kí wọ́n ka ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Láfikún sí èyí, àwọn àkéde kan tún máa ń lo àkókò ìdákẹ́kọ̀ọ́ yìí láti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ dáadáa. Láwọn ìgbà míì, wọ́n lè pe akéde tàbí ìdílé míì wá sílé wọn fún ìjíròrò tó ń gbéni ró látinú Ìwé Mímọ́.

11, 12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé?

11 Àwọn Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé Déédéé? Àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ tọkàntọkàn máa ń sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí. Láfikún sí i, àwọn ìdílé tó ń jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀ máa ń sún mọ́ra gan-an. Tọkọtaya kan sọ nípa àwọn ìbùkún tí wọ́n rí látàrí Ìjọsìn Ìdílé wọn pé: “Aṣáájú-ọ̀nà ni wá, a ò sì lọ́mọ, ńṣe ni a máa ń fojú sọ́nà fún àkókò Ìjọsìn Ìdílé wa tá a máa ń ṣe lálẹ́. A ti wá sún mọ́ ara wa àti Baba wa ọrùn gan-an. Tá a bá ti jí láàárọ̀ ọjọ́ tá a máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé wa, ohun tá a máa ń sọ fún ara wa ni pé: ‘Ṣó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lálẹ́ yìí? Òní la máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé wa!’”

12 Ètò Ìjọsìn Ìdílé tún ṣèrànwọ́ fún àwọn ìdílé tí ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an. Ìyá kan tó ń dá tọ́ àwọn ọmọkùnrin méjì, tó sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé kọ̀wé pé: “Nígbà kan, a kì í ráyè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa. A kì í ṣe é déédéé torí pé ó máa ń rẹ̀ mí gan-an. Ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣe gbogbo ohun tí mó fẹ́ ṣe pa pọ̀ pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Torí náà, mo kọ ìwé yìí láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ètò tẹ́ ẹ ṣe pé ká ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé. A ti wá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa déédéé báyìí, a sì ń rí àǹfààní rẹ̀.”

13. Kí ló máa pinnu bí ìdílé rẹ ṣe máa jàǹfààní tó nínú ètò yìí?

13 Bíi ti Sábáàtì, Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run láti ran àwọn ìdílé lọ́wọ́. (Ják. 1:17) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe lo ọjọ́ Sábáàtì wọn ló máa pinnu bó ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní sí nípa tẹ̀mí. Bákan náà, bá a bá ṣe lo ìrọ̀lẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti yà sọ́tọ̀ pé ká máa fi ṣe Ìjọsìn Ìdílé ló máa pinnu bó ṣe máa ṣe ìdílé wa láǹfààní tó. (2 Kọ́r. 9:6; Gál. 6:7, 8; Kól. 3:23, 24) Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìṣètò yìí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ìdílé yín á lè tún ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí sọ, o ní: “Ṣùgbọ́n ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”—Sm. 73:28.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Kò yẹ kí Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ohun tó ń súni tàbí èyí tó le koko, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run aláyọ̀ là ń jọ́sìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

TỌ́JÚ RẸ̀

Àwọn Nǹkan Tẹ́ Ẹ Lè Máa Ṣe Nígbà Ìjọsìn Ìdílé

Bíbélì:

• Ẹ ka apá kan lára Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pa pọ̀. Bó bá jẹ́ pé ìtàn kan ni Bíbélì kíkà náà dá lé, ẹnì kan lè ka apá tó jẹ́ ti asọ̀tàn, kí àwọn tó kù sì ka ọ̀rọ̀ táwọn tó wà nínú ìtàn náà sọ.

• Ẹ ṣe àṣefihàn apá kan lára ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn Bíbélì náà.

• Ẹ ni kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lọ ka àwọn orí kan sílẹ̀, kó sì ṣàkọsílẹ̀ ìbéèrè kan tàbí méjì tó ní látinú ibi tó kà náà. Kẹ́ ẹ jọ wá ṣèwádìí lórí ìbéèrè tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ní.

• Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, máa ṣètò káàdì pélébé kan tí wàá kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì sí, kó o sapá láti há wọn sorí, kó o sì tún lè ṣàlàyé wọn. Bí àwọn káàdì náà bá ti pọ̀, kó o máa ṣàyẹ̀wò wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kó o sì wo mélòó lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà lo lè rántí.

• Máa gbọ́ ẹsẹ Bíbélì tá a kà sorí àwo CD tàbí sórí kásẹ́ẹ̀tì, kó o sì máa fojú bá a lọ nínú Bíbélì rẹ.

Àwọn Ìpàdé:

• Ẹ jọ múra àwọn apá kan lára àwọn ìpàdé sílẹ̀.

• Ẹ kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tá a máa kọ ní ìpàdé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.

• Bí ẹnì kan bá ní iṣẹ́ ní Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí tó ní àṣefihàn ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ẹ jọ jíròrò ọ̀nà tó lè gbà gbé e kalẹ̀ tàbí kó ṣe ìfidánrawò rẹ̀ lójú ìdílé.

Àwọn Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìdílé:

• Ẹ lo àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé tàbí Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.

• Ẹ ṣe ìfidánrawò bí àwọn ọmọ rẹ á ṣe yanjú àwọn ọ̀ràn tó ṣeé ṣe kó jẹyọ níléèwé.

• Ẹ ṣe ìfidánrawò ibi tí àwọn ọmọ ti ń ṣe bí òbí, kí àwọn òbí sì ṣe bí àwọn ọmọ. Kí àwọn ọmọ ṣe ìwádìí lórí kókó kan, kí wọ́n sì fèròwérò pẹ̀lú àwọn òbí wọn.

Iṣẹ́ Ìsìn Pápá:

• Ẹ ṣe ìfidánrawò bẹ́ ẹ ṣe máa wàásù fún àwọn èèyàn lópin ọ̀sẹ̀.

• Ẹ jíròrò àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ìdílé lè bá nípa bẹ́ẹ̀ ṣe máa mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín gbòòrò sí i nígbà Ìrántí Ikú Kristi tàbí lákòókò ìsinmi.

• Ẹ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láǹfààní láti ṣe ìwádìí bó ṣe máa dáhùn onírúurú ìbéèrè tó ṣeé ṣe kó jẹyọ lóde ẹ̀rí, lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ wá ṣe ìfidánrawò.

Àwọn Àbá Míì:

• Ẹ jọ ka àpilẹ̀kọ kan pa pọ̀ látinú àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé.

• Ẹ jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan ka àpilẹ̀kọ kan tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn sílẹ̀ látinú àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, kẹ́ ẹ wá jẹ́ kó sọ̀rọ̀ lé e lórí nígbà Ìjọsìn Ìdílé.

• Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ pé àwọn akéde tàbí àwọn tọkọtaya pé kí wọ́n wá bá a yín ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ sì lè fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.

• Ẹ wo ọkàn lára àwọn fídíò tí ètò Ọlọ́run ṣe jáde, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

• Ẹ jíròrò “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tàbí “Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé” tó máa ń wà nínú ìtẹ̀jáde Jí!

• Ẹ jíròrò àwọn àpilẹ̀kọ bíi “Kọ́ Ọmọ Rẹ” tàbí “Abala Àwọn Ọ̀dọ́” tó máa ń wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́.

• Ẹ ka ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ tàbí ìwé tó jáde ní àpéjọ àgbègbè tó kẹ́yìn.

• Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá dé láti àpéjọ àyíká, àkànṣe tàbí àgbègbè, kẹ́ ẹ jíròrò àwọn kókó pàtàkì tẹ́ ẹ gbọ́ níbẹ̀.

• Ẹ wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni nípa Jèhófà.

• Ẹ ṣiṣẹ́ lórí ohun kan, irú bíi wíwo ohun kan yà, yíya máàpù tàbí àwòrán atọ́ka.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́