Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 24
Orin 53 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 16 ìpínrọ̀ 15 sí 20, àti àpótí tó wà lójú ìwé 171 (25 min)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́sírà 6-10 (10 min)
No. 1: Ẹ́sírà 7:1-17 (ìṣẹ́jú 4 tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bí Jésù Ṣe Fi Hàn Pé Òun Kúnjú Ìwọ̀n Láti Jẹ́ Ọba (5 min)
No. 3: Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí sí Àwọn Àmì Ọjọ́ Ìkẹyìn—td 39B (5 min)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Sọ ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù February, kó o sì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan.
20 min: “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé.”—Apá Kìíní. (Ìpínrọ̀ 1 sí 6 àti àpótí tó wà lójú ìwé 6.) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwọn ará ní ìṣírí pé kí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 6 nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn tó ń bọ̀. Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, wọ́n máa láǹfààní láti sọ bó ṣe ṣe ìdílé wọn láǹfààní nígbà tá a bá ń jíròrò apá tó kù nínú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn ní Oṣù February. Ìjíròrò. Láàárín ìṣẹ́jú kan sí méjì, mẹ́nu ba ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn tá a máa lò. Lẹ́yìn náà kó o yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìròyìn náà, kó o wá ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
Orin 32 àti Àdúrà