Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
“Inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.”—SÁÀMÙ 26:12.
1. Yàtọ̀ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ àti gbígbàdúrà nínú ilé, apá wo ló tún ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́?
ÌJỌSÌN Jèhófà kò mọ sórí gbígbàdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé nìkan, ìgbòkègbodò gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọ Ọlọ́run tún wà níbẹ̀. A pàṣẹ fún Ísírẹ́lì ìgbàanì láti “pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké,” láti wá kọ́ òfin Ọlọ́run, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀. (Diutarónómì 31:12; Jóṣúà 8:35) Àtarúgbó àti ‘ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá’ la rọ̀ láti nípìn-ín nínú yíyin orúkọ Jèhófà. (Sáàmù 148:12, 13) Irú ètò kan náà ló wà nínú ìjọ Kristẹni. Nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ayé, àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé máa ń kópa fàlàlà nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àwùjọ lè lóhùn sí, tayọ̀tayọ̀ lọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fi ń ṣe é.—Hébérù 10:23-25.
2. (a) Èé ṣe tí ìmúrasílẹ̀ fi jẹ́ kókó pàtàkì nínú ríran àwọn èwe lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìpàdé? (b) Àpẹẹrẹ ta ló ṣe pàtàkì jù?
2 Àmọ́ ṣá o, ríran àwọn èwe lọ́wọ́ láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ tó gbámúṣe lè jẹ́ ìpèníjà. Táwọn ọmọ kan tó ń bá àwọn òbí wọn wá sípàdé kì í bá gbádùn ìpàdé náà ńkọ́, kí lò lè jẹ́ ìṣòro wọn? Ká sòótọ́, àwọn ọmọdé tó pọ̀ jù lọ ló jẹ́ pé wọn kò lè pọkàn pọ̀ lọ títí, nǹkan kì í sì í pẹ́ sú wọn. Ṣùgbọ́n, ìmúrasílẹ̀ lè mú kí ìṣòro yìí ṣeé yanjú. Bí a kò bá múra ìpàdé sílẹ̀, àwọn ọmọ kò ní lè kópa nínú ẹ̀ lọ́nà tó nítumọ̀. (Òwe 15:23) Bí kò bá sì sí ìmúrasílẹ̀, yóò ṣòro fún wọn láti ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí lọ́nà tí yóò fi tẹ́ wa lọ́rùn. (1 Tímótì 4:12, 15) Kí la wá lè ṣe? Èkíní, káwọn òbí bi ara wọn léèrè bóyá àwọn pàápàá ń múra ìpàdé sílẹ̀. Àpẹẹrẹ wọn lè nípa tó lágbára gan-an lórí àwọn ọmọ. (Lúùkù 6:40) Ṣíṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé dáadáa tún jẹ́ kókó pàtàkì tó lè ṣèrànwọ́.
Sísọ Ọkàn-Àyà Ẹni Di Alágbára
3. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, èé ṣe tó fi yẹ ká sapá gidigidi láti sọ ọkàn-àyà di alágbára, kí sì ni èyí ń béèrè?
3 Kò yẹ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ àkókò tí a óò wulẹ̀ máa rọ́ ìmọ̀ síni lórí ṣùgbọ́n ó yẹ kó jẹ́ àkókò tí a óò fi sọ ọkàn-àyà ẹni di alágbára. Èyí ń béèrè pé ká mọ ìṣòro táwọn mẹ́ńbà ìdílé dojú kọ, ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ olúkúlùkù wọn. Jèhófà ni “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà.”—1 Kíróníkà 29:17.
4. (a) Kí ló túmọ̀ sí táa bá sọ pé ‘ọkàn-àyà kù fún ẹnì kan’? (b) Kí ló wé mọ́ ‘jíjèrè ọkàn-àyà’?
4 Kí ni Jèhófà lè rí bó bá yẹ ọkàn-àyà àwọn ọmọ wa wò? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni yóò wí pé, àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ohun tó dára nìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ̀nba ni ìrírí tí ọ̀dọ́mọdé tàbí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ní nípa ọ̀nà Jèhófà. Nítorí pé kò nírìírí, ‘ọkàn-àyà lè kù fún un,’ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ ọ́. Lóòótọ́, gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ lè máà burú, ṣùgbọ́n kí ẹnì kan tó lè mú ọkàn-àyà rẹ̀ wá sí ipò tí yóò wu Ọlọ́run, yóò ná onítọ̀hún lákòókò. Èyí ń béèrè pé kí onítọ̀hún mú ìrònú rẹ̀, ohun tó wù ú, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, ìmọ̀lára rẹ̀, àti àwọn góńgó rẹ̀ bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu, dé àyè tó ṣeé ṣe fún èèyàn aláìpé. Nígbà tẹ́nìkan bá ṣe ẹni ti inú rẹ̀ bẹ́ẹ̀, lọ́nà tí ó wu Ọlọ́run, ó “ń jèrè ọkàn-àyà” nìyẹn.—Òwe 9:4; 19:8.
5, 6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”?
5 Ǹjẹ́ àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”? Lóòótọ́, kò séèyàn tó lè fi ipò ọkàn-àyà tó dáa sínú ẹlòmíràn. Olúkúlùkù wa la fi òmìnira ìfẹ́-inú jíǹkí, ọ̀pọ̀ nǹkan tí à ń ṣe ló sì sinmi lé ohun tí a bá fàyè gba ara wa láti ronú lé lórí. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn òbí lè lo ìfòyemọ̀ láti mú kí ọmọ kan sọ̀rọ̀ jáde, kí wọ́n fi lè mọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ àti ibi tó ti nílò ìrànlọ́wọ́. Lo àwọn ìbéèrè bí ‘Kí lèrò rẹ nípa èyí?’ àti ‘Kí ló tiẹ̀ wù ẹ́ láti ṣe?’ Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀, jẹ́ kó sọ̀rọ̀. Máà jẹ́ kí ara rẹ gbóná jù. (Òwe 20:5) Ipò tí ó fi inú rere, òye, àti ìfẹ́ hàn ṣe pàtàkì bóo bá fẹ́ dé inú ọkàn-àyà ènìyàn.
6 Kóo lè sọ èrò-ọkàn wọn di èyí tó gbámúṣé, máa jíròrò àwọn èso tẹ̀mí déédéé pẹ̀lú wọn—mú un lọ́kọ̀ọ̀kan—kí ẹ sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti lè mú un dàgbà. (Gálátíà 5:22, 23) Gbé ìfẹ́ fún Jèhófà àti Jésù Kristi ró nínú wọn, kì í ṣe nípa wíwulẹ̀ sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ wọn ṣùgbọ́n nípa jíjíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ wọn àti ọ̀nà táa lè gbà fi ìfẹ́ yẹn hàn. (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Mú kí ìfẹ́ wọn láti ṣe ohun tó tọ́ lágbára sí i nípa ríronú lórí àǹfààní tí yóò tibẹ̀ jáde. Mú kí ìfẹ́ láti kórìíra èrò búburú, ọ̀rọ̀ burúkú, àti ìwà abèṣe dàgbà nínú wọn nípa jíjíròrò àwọn jàǹbá tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fà. (Ámósì 5:15; 3 Jòhánù 11) Fi hàn bí ìrònú, ọ̀rọ̀ ẹnu, àti ìwà—ì báà jẹ́ rere tàbí búburú—ṣe lè nípa lórí ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà.
7. Kí la lè ṣe láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro àti láti ṣe ìpinnu lọ́nà tí wọn kò fi ní jìnnà sí Jèhófà?
7 Nígbà tí ọmọ kan bá níṣòro tàbí bá ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan, a lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ojú wo lo rò pé Jèhófà yóò fi wò ó? Kí lo mọ̀ nípa Jèhófà tóo fi sọ bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà sí i nípa rẹ̀?’ Tí o kò bá jẹ́ kó dìgbà táwọn ọmọ ti di géńdé kóo tó ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò jẹ́ kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé kan tí wọn yóò fi tètè sapá láti mọ ìfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n a sì ṣe é. Bí wọ́n ti ń di ẹni tó ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, inú wọn yóò máa dùn láti máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀. (Sáàmù 119:34, 35) Èyí yóò mú kí wọ́n mú ìmọrírì dàgbà fún àǹfààní tí wọ́n ní láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́run tòótọ́.
Mímúra Àwọn Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀
8. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi gbogbo ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí kún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa? (b) Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe pàtàkì tó?
8 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ ká fún láfiyèsí nígbà táa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Báwo lo ṣe lè mọ gbogbo wọn? Kò ṣeé ṣe láti ṣe ohun gbogbo lọ́wọ́ kan náà. Ṣùgbọ́n ó lè rọrùn díẹ̀ tóo bá lè ní àkọọ́lẹ̀ kékeré kan. (Òwe 21:5) Máa yẹ̀ ẹ́ wò lóòrèkóòrè, kóo sì ronú lórí ohun tó yẹ ká pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí. Nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ nínú ìtẹ̀síwájú mẹ́ńbà ìdílé kọ̀ọ̀kan. Ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń jíròrò yìí jẹ́ apá pàtàkì nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà fáwọn Kristẹni, èyí tó ń mú wa gbára dì fún ìgbésí ayé ìsinsìnyí, tó tún ń múra wa sílẹ̀ fún ìyè ayérayé tí ń bọ̀.—1 Tímótì 4:8.
9. Àwọn góńgó wo tó ní í ṣe pẹ̀lú mímúra ìpàdé sílẹ̀ ni a lè ṣiṣẹ́ lé lórí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa?
9 Ǹjẹ́ o fi mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀ kún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ? Bí ẹ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè ṣiṣẹ́ lé lórí ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Àwọn kan lára wọn lè gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, oṣù, kódà ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá kẹ́ẹ tó parí ẹ̀. Gbé àwọn góńgó wọ̀nyí yẹ̀ wò: (1) kí olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé múra láti dáhùn nínú ìpàdé ìjọ; (2) kí olúkúlùkù rí i pé òun dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara òun; (3) kí olúkúlùkù lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìdáhùn rẹ̀; àti (4) kí olúkúlùkù lè fọ́ ọ̀rọ̀ sí wẹ́wẹ́ láti jẹ́ ká mọ bí a óò ṣe fi sílò. Gbogbo èyí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ó sọ òtítọ́ di tara rẹ̀.—Sáàmù 25:4, 5.
10. (a) Báwo la ṣe lè fún gbogbo ìpàdé ìjọ wa ní àfiyèsí? (b) Èé ṣe tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fi tọ́?
10 Kódà bó bá jẹ́ pé orí ẹ̀kọ́ tí a óò kọ́ láàárín ọ̀sẹ̀, èyí tí ń bẹ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni ẹ ń gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín kà, ẹ má ṣe fojú kéré mímúra sílẹ̀ fún Ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, yálà lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú jẹ́ apá pàtàkì nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táa ṣe fún wa, ká lè máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà. O lè ṣeé ṣe fún yín láti máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ìdílé lóòrèkóòrè. Èé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ẹ óò túbọ̀ jáfáfá sí i lọ́nà tí ẹ gbà ń kẹ́kọ̀ọ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ẹ óò jèrè ọ̀pọ̀ àǹfààní láti inú àwọn ìpàdé náà. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ jíròrò àwọn àǹfààní tó wà nínú mímúra ìpàdé sílẹ̀ déédéé àti ìjẹ́pàtàkì níní àkókò pàtó tí a yà sọ́tọ̀ fún un.—Éfésù 5:15-17.
11, 12. Báwo ni mímúra sílẹ̀ fún orin tí a óò kọ nínú ìjọ ṣe lè ṣe wá láǹfààní, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí?
11 Nínú àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” a rọ̀ wá láti máa múra apá mìíràn nínú àwọn ìpàdé wa sílẹ̀—ìyẹn ni orin kíkọ. Ǹjẹ́ o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ òtítọ́ Bíbélì mọ́ wa lọ́kàn, kí a sì túbọ̀ gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ.
12 Ìmúrasílẹ̀ tó wé mọ́ kíka ọ̀rọ̀ orin táa fẹ́ kọ nípàdé jáde àti jíjíròrò ìtumọ̀ wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti kọrin jáde láti inú ọkàn-àyà wa. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n ń lo àwọn ohun èlò orin dáadáa nínú ìjọsìn. (1 Kíróníkà 25:1; Sáàmù 28:7) Ǹjẹ́ ẹ lẹ́nìkan nínú ìdílé yín tó mọ ohun èlò orin kan lò? Kí ló de ti ẹ̀ ò lo ohun èlò orin yẹn láti fi àwọn orin Ìjọba tí ẹ óò kọ lọ́sẹ̀ náà dánra wò, kí ẹ sì wá jùmọ̀ kọrin náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ohun mìíràn tẹ́ẹ tún lè ṣe ni pé kí ẹ lo ohùn orin táa ti gbà sílẹ̀. Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn ara wa ń kọ orin lọ́nà tó dùn jọjọ tí wọn ò sì ní lo ohun èlò ìkọrin èyíkéyìí. Bí wọ́n bá ń rìn lójú ọ̀nà tàbí tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ nínú oko, wọ́n sábà máa ń gbádùn kíkọ àwọn orin tí a óò kọ nípàdé ìjọ lọ́sẹ̀ yẹn.—Éfésù 5:19.
Bí Ìdílé Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Sílẹ̀
13, 14. Èé ṣe tí ìjíròrò ìdílé tó múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fi ṣe pàtàkì?
13 Jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà àti ète rẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì mìíràn nínú ìgbésí ayé wa. (Aísáyà 43:10-12; Mátíù 24:14) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, báa bá múra ìgbòkègbodò yìí sílẹ̀, a óò gbádùn rẹ̀ dáadáa, a óò sì lè kẹ́sẹ járí. Báwo la ṣe lè ṣe èyí nínú ìdílé?
14 Gẹ́gẹ́ bó ti máa ń rí nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, ó ṣe pàtàkì láti múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀. Kì í ṣe ohun táa fẹ́ ṣe nìkan ló yẹ ká jíròrò ṣùgbọ́n ó tún yẹ ká jíròrò ìdí táa fi fẹ́ ṣe é. Lọ́jọ́ Jèhóṣáfátì Ọba, a fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́ni láti inú òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé wọn “kò . . . tíì múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀.” Èyí mú kí àwọn ohun tó lè fà wọ́n kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ tètè fà wọ́n lọ. (2 Kíróníkà 20:33; 21:11) Góńgó wa kì í ṣe ká kàn ròyìn wákàtí táa lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, tàbí ká kàn fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbọ́dọ̀ jẹ́ fífi ìfẹ́ hàn sí Jèhófà àti sí àwọn èèyàn tí wọ́n láǹfààní láti yan ìyè. (Hébérù 13:15) Ó jẹ́ ìgbòkègbodò kan táa ti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 3:9) Àǹfààní ńláǹlà mà lèyí jẹ́ o! Báa ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́. (Ìṣípayá 14:6, 7) Àkókò wo ni a tún lè ní láti gbé ìmọrírì wa ró fún èyí bí kò ṣe ìgbà tí a bá ń jíròrò nínú ìdílé, yálà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí nígbà táa bá ń jíròrò ẹsẹ tó jẹ mọ́ ọn láti inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́!
15. Nígbà wo la lè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
15 Nígbà mìíràn, ǹjẹ́ ẹ máa ń lo àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín láti ran àwọn mẹ́ńbà ìdílé yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá tọ̀sẹ̀ náà? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní púpọ̀. (2 Tímótì 2:15) Ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìsìn wọn nítumọ̀, kó sì méso jáde. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ya odidi àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sọ́tọ̀ fún irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé o lè sọ̀rọ̀ ṣókí lórí apá tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá tàbí kóo sọ ọ́ ní àwọn àkókò mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀.
16. Jíròrò ìjẹ́pàtàkì ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí.
16 Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lè dá lórí onírúurú ìgbésẹ̀, irú bí àwọn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: (1) Múra ọ̀rọ̀ kan táa gbé kalẹ̀ dáadáa sílẹ̀, kí o sì fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú Bíbélì tí a óò kà kún un bí àyè bá yọ̀ǹda. (2) Rí i dájú pé tó bá ṣeé ṣe, olúkúlùkù ní àpò òde ẹ̀rí, Bíbélì, ìwé ìkọ-nǹkan-sí, kálàmù tàbí pẹ́ńsù, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó bójú mu. Kò pọndandan kí àpò òde ẹ̀rí jẹ́ olówó ńlá, àmọ́ o yẹ kó ṣeé rí mọ́ni. (3) Jíròrò ibi tẹ́ẹ ti lè jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti bí ẹ óò ṣe ṣe é. Tẹ̀ lé ìpele kọ̀ọ̀kan nínú ìtọ́ni yìí fún àkókò tí ẹ óò fi ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Fún wọn ní ìmọ̀ràn tó lè ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n máà jẹ́ kí ìmọ̀ràn rẹ pọ̀ jù.
17, 18. (a) Irú ìmúrasílẹ̀ wo ló lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wa túbọ̀ méso jáde? (b) Apá wo nínú ìmúrasílẹ̀ yìí la lè máa ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
17 Apá pàtàkì nínú iṣẹ́ tí Jésù Kristi yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Ohun tó wé mọ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ju wíwàásù lọ. Ó ń béèrè kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbéṣẹ́ nínú ṣíṣe èyí?
18 Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ jíròrò ẹni tí ó dáa kí ẹ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn kan lára wọn ti lè gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́; ó sì lè jẹ́ pé àwọn kan kàn tẹ́tí sílẹ̀ ni. Ó lè jẹ́ pé ẹnu iṣẹ́ ilé dé ilé lẹ ti bá wọn pàdé tàbí kó jẹ́ lẹ́nu ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà nínú ọjà tàbí nílé ẹ̀kọ́. Ẹ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà yín. (Sáàmù 25:9; Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ẹ pinnu ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín fẹ́ lọ bẹ̀ wò lọ́sẹ̀ yẹn. Kí lẹ óò jọ sọ? Ìjíròrò ìdílé lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀. Ẹ kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn sílẹ̀ àti àwọn kókó yíyẹ láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Má gbìyànjú àtisọ̀rọ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Béèrè ìbéèrè tí onílé yóò máa ronú lé lórí di ìgbà mí-ìn lọ́wọ́ rẹ̀. Èé ṣe tí ẹ kò fi ìpadàbẹ̀wò tí olúkúlùkù yóò ṣe kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìgbà tí ẹ óò lọ síbẹ̀, àti ohun tí ẹ retí láti ṣe níbẹ̀. Ṣíṣe èyí lè jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ti ìdílé lápapọ̀ túbọ̀ méso jáde.
Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Fífi Ọ̀nà Jèhófà Kọ́ni
19. Bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá fẹ́ máa bá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà Jèhófà, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ nírìírí rẹ̀, kí ló sì ń pa kún èyí?
19 Ìpèníjà ńlá ló jẹ́ láti jẹ́ olórí ìdílé nínú ayé búburú yìí. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò sinmi láti rí i pé àwọn ba ipò tẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́. (1 Pétérù 5:8) Ìyẹn nìkan kọ́, àní lónìí, wàhálà pọ̀ lọ́rùn ẹ̀yin òbí, pàápàá ẹ̀yin òbí anìkàntọ́mọ. Ó ṣòro fún yín láti ráyè ṣe gbogbo ohun tẹ́ẹ fẹ́ ṣe. Àmọ́ gbogbo akitiyan wọ̀nyẹn yẹ ní ṣíṣe, kódà bó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn kan péré lẹ lè lò lẹ́ẹ̀kan, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yóò mú kí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín sunwọ̀n sí i. Rírí i pé àwọn tó sún mọ́ ọ ń fi tòótọ́tòótọ́ rìn ní ọ̀nà Jèhófà jẹ́ èrè tí ń mọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Láti lè kẹ́sẹ járí ní ọ̀nà Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé rí ayọ̀ nínú wíwà nínú àwọn ìpàdé ìjọ àti nínú kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí ìyẹn yóò bá ṣẹlẹ̀, ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì—ìmúrasílẹ̀ tí ń sọ ọkàn-àyà wa di alágbára, tó sì ń mú wa gbára dì láti kópa tó nítumọ̀.
20. Kí ló lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní irú ayọ̀ tí a sọ nínú 3 Jòhánù 4?
20 Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti ràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé táa ṣe pẹ̀lú àwọn ète tó ṣe kedere lọ́kàn àti àwọn olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣèrànwọ́ láti yanjú ìṣòro olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé lè ṣe bẹbẹ láti ran ìdílé lọ́wọ́ láti nípìn-ín nínú irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Nípa mímú ìmọrírì dàgbà fún ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, àwọn òbí lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti gbádùn ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ.—Sáàmù 19:7-11.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
◻ Èé ṣe tí ìmúrasílẹ̀ fún ìpàdé fi ṣe pàtàkì fáwọn ọmọ wa?
◻ Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”?
◻ Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún gbogbo ìpàdé?
◻ Báwo ni mímúra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá gẹ́gẹ́ bí ìdílé ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ lè ní ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ nínú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àǹfààní ń bẹ nínú fífi orin tí a óò kọ nínú ìpàdé dánra wò