Apá Kìíní: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Kárí ayé, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ sí nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà làwọn èèyàn Ọlọ́run ń darí lóṣooṣù. Bá a bá ń lo àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko, a ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, tí wọ́n á sì “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:2) Ǹjẹ́ wàá fẹ́ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀? Bẹ̀rẹ̀ látorí ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí, àwọn àpilẹ̀kọ kan yóò máa jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, tí yóò máa ṣàlàyé àwọn ohun pàtàkì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú.
2 Ìgbà Tó Yẹ Ká Ròyìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Bó o bá ń bá ẹnì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí Bíbélì déédéé, tó ò ń lo Bíbélì pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn ìwé tá a dámọ̀ràn, kódà bí àkókò tó ò ń lò kò bá tiẹ̀ pọ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lò ń darí yẹn. Ì báà jẹ́ ẹnu ọ̀nà lẹ̀ ń dúró sí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí orí tẹlifóònù lẹ ti ń ṣe é, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ṣì ni. A lè ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tá a bá ti darí rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lẹ́yìn ìgbà tá a kọ́kọ́ ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún onílé, tá a sì ti wò ó pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè máa tẹ̀ síwájú.
3 Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ la sábà máa fi ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tá a bá ti parí àwọn ìwé wọ̀nyí, bó bá ṣe kedere pé ẹni náà ń tẹ̀ síwájú, kódà bí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ ò bá tiẹ̀ yá kánkán, tí ẹni náà sì ń fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ń kọ́, nígbà náà a lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run. A lè lo ìwé pẹlẹbẹ Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! láti bá àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé tàbí tí kò mọ̀wéé kà dáadáa ṣèkẹ́kọ̀ọ́.
4 Iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti sèso rere gan-an, nítorí pé ó ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti di ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. (Mát. 28:19, 20) Bó o bá ń fi àwọn ohun tá a dábàá nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀ lórí kókó yìí sílò, á ṣeé ṣe fún ọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú.