Apá Kejìlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Bẹ̀rẹ̀ sí Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1 Bí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n tí wọ́n bá rántí pé ó yẹ káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo la ṣe lè mú kí wọ́n ní ìgboyà tí wọ́n á fi lè máa kópa nínú apá tó ṣe pàtàkì lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yìí?—Mát. 24:14; 28:19, 20.
2 Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá yẹ lẹ́ni tó lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, á ti ní láti máa ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ nípa bó ṣe lè máa múra iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ àti bó ṣe lè máa ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ á ti jẹ́ kó mọ bó ṣe yẹ kó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, gẹ́gẹ́ bí “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.
3 Jẹ́ Kó Rí Ẹ̀kọ Kọ́ Lára Rẹ: Bí Jésù ṣe fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nígbà tó ń kọ́ wọn ló jẹ́ kí wọ́n lè rí ẹ̀kọ́ tó jíire kọ́ lára rẹ̀. Ó ní: “Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 6:40) Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ káwọn èèyàn bàa lè máa rí ẹ̀kọ́ tó dáa kọ́ lára rẹ. Bẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ṣe ń wo bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ ọ̀hún láá máa yé e pé torí àtibẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò.
4 Ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ náà pé nígbà tá a bá ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan, kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan pé ká ṣàlàyé lẹ́sẹẹsẹ bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sábà máa ń dáa jù pé ká fi ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàpèjúwe fún un. Àwọn àbá tó wúlò nípa bá a ṣe lè ṣe é wà lójú ìwé 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí àti lójú ìwé 6 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002.
5 Nígbà tó bá yẹ, ní kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tẹ̀ lé ọ lọ síbi ìpadàbẹ̀wò tàbí kó o ní kó tẹ̀ lé akéde kan tó dáńgájíá lọ ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì. O lè ní kóun náà sọ òye rẹ̀ lórí ìpínrọ̀ kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí ìpínrọ̀ náà dá lé lórí. Bí akẹ́kọ̀ọ́ yìí bá ṣe ń fọkàn sí i, á rọrùn fún un láti mọ bóun náà ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú. (Òwe 27:17; 2 Tím. 2:2) Yìn ín, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ibi tó bá yẹ kó ti ṣàtúnṣe.
6 Bá a bá ń kọ́ àwọn akéde tuntun láti di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á mú kí wọ́n gbára dì pátápátá fún “iṣẹ́ rere,” bíi bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì máa darí rẹ̀ nìṣó. (2 Tím. 3:17) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó bá a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn láti máa kéde pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”!—Ìṣí. 22:17.