ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 5
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 8/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 8

Orin 125

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì lára ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá lórí bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá gba ìwé pẹlẹbẹ, bó ṣe wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2005.

15 min: Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Fífi Káàdì Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ Ránṣẹ́ Túbọ̀ Yá. Àsọyé tá a gbé karí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 87 sí 88. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n rí i pé àwọn kọ ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìjọ tí wọ́n ti kúrò fún ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́. Káwọn alàgbà sì rí i pé àwọn ń fi káàdì akéde tó bá kúrò nínú ìjọ àwọn ránṣẹ́ sí ìjọ tó bá ń dara pọ̀ mọ́ láìfi àkókò falẹ̀ tàbí ní gbàrà tí ìjọ tẹ́ni náà ń dara pọ̀ mọ́ bá béèrè fún un. Bẹ́ ẹ bá ní láti fi káàdì náà ránṣẹ́ nítorí ọ̀nà tó jìn, ṣe ni kẹ́ ẹ kúkú fi ṣọwọ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa mímú un lọ sí ibi tí ọkọ̀ ń já ẹrù sí. A ó sì bá yín fi ránṣẹ́ sí ìjọ náà.—Tún wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1991, ojú ìwé 3.

20 min: Fi Ìfẹ́ Hàn Sáwọn Aláìlera. (Ìṣe 20:35) Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò gbọ́dọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, fi ìbéèrè àti ìdáhùn darí Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 17 sí 18 ìpínrọ̀ 12 sí 16, bá a ṣe máa ń ṣe nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ní kí arákùnrin kan tó mọ̀wé kà dáadáa ka àwọn ìpínrọ̀ yẹn.

Orin 166 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 15

Orin 11

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù August sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu), láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 15.

15 min: Ǹjẹ́ O Rántí? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2005 ojú ìwé 30. Ké sí àwọn ará láti lóhùn sí gbogbo ìbéèrè náà níkọ̀ọ̀kan. Tẹnu mọ́ bí ìjíròrò náà ṣe wúlò tó. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti máa ka ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kọ̀ọ̀kan tó bá ń jáde.

20 min: “Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Orí Ìdúró àti Ti Orí Tẹlifóònù.”a Fi àṣefihàn ṣókí kan kún un, èyí tó ń fi hàn bá a ṣe lè fi ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni tá a bá bá pàdé fúngbà àkọ́kọ́.

Orin 30 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 22

Orin 161

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó, kó o sì tún ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Àǹfààní Ṣíṣeyebíye Ni Wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run.”b Bó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ṣàtúnyẹ̀wò ìṣètò àkànṣe tó fún àwọn arúgbó tàbí àwọn tó ní ìṣòro àìlera láǹfààní láti máa ròyìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n bá lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, October 2002, ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 6.

Orin 204 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 29

Orin 45

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù August sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! September 8. Nínú ọ̀kan nínú àwọn àṣefihàn náà, ṣàṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tá a máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé.

15 min: Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ń Sọ Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ọ̀rọ̀ àkọ́sọ nínú ìwé Good News for People of All Nations. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn apá tó ṣe kókó nínú ìwé náà. Jíròrò ìgbésẹ̀ mẹ́ta tá a lè gbé láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè tá ò gbọ́. Fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2003, ojú ìwé 8. Sọ pé kí àwọn ará rí i pé àwọn ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43), kódà bí onítọ̀hún kò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

20 min: Máa Lo Bíbélì Látìbẹ̀rẹ̀. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá lórí bá a ṣe lè máa kọ́ àwọn èèyàn láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, látìgbà tó o bá ti kọ́kọ́ bá wọn pàdé, èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù September 2004, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 2. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ẹyọ kan tàbí méjì lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá fún lílo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lóṣù September. O tún lè jíròrò àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 tàbí bí àkókò bá wà kó o ṣàṣefihàn wọn.

Orin 71 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 5

Orin 98

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kejìlá.”c Ní kí akéde kan tàbí méjì múra sílẹ̀ láti sọ ohun tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè máa tẹ̀ síwájú nínú bíbẹ̀rẹ̀ àti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

20 min: Ṣíṣètò Láti Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́. Àsọyé ti alàgbà kan yóò sọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ August 15, 1993, ojú ìwé 28 sí 29 lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ṣiṣeto Ṣeyebiye.” Sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti lè máa ran àwọn aláìlera àtàwọn àgbàlagbà lọ́wọ́.

Orin 164 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́