ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 7/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 12

Orin 108

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! August 8 lọni. (Àbá kẹta ni kó o lò láti fi Jí! August 8 lọni.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, jẹ́ káwọn ará rí bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọ ẹnì kan tó ń lọ ní òpópónà tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè yín.

18 min: “Fi Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ṣe Àwòkọ́ṣe.”a Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

15 min: Bíbélì—Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 27 sí 29. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a sábà máa ń pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Bíbélì sọ àwọn ohun tó ṣeé gbára lé, tó jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tó wà fún àwọn tó bá ṣègbọràn. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó lè jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la túbọ̀ lágbára sí i. Ṣètò pé kí akéde kan ṣàṣefihàn ṣókí nípa bá a ṣe lè lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì láti fi ran olùfìfẹ́hàn kan lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Bíbélì.

Orin 16 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 19

Orin 83

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí bó ti ṣe pàtàkì tó láti rí i pé ètò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ wa ń lọ déédéé, kódà nígbà tá a bá rìnrìn àjò tí àyípadà sì bá àwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2000, ojú ìwé 32.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kìíní.” Àsọyé tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò bójú tó. Jẹ́ kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Proclaimers, ojú ìwé 572 sí 574, èyí tó ṣàlàyé bí iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lóde òní ti ṣe ń bá a bọ̀. Sọ̀rọ̀ tó máa ta àwọn ará jí kí wọ́n lè máa wọ̀nà fún àwọn àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀ lórí kókó yìí. Lára àwọn kókó tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí ni bá a ṣe lè múra sílẹ̀ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bá a ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti máa múra sílẹ̀, bí ohun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ á ṣe pọ̀ tó, bá a ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó múná dóko, bá a ṣe lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí akẹ́kọ̀ọ́ bá béèrè, bá a ṣe lè mú àdúrà wọnú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà àti bá a ṣe lè darí akẹ́kọ̀ọ́ náà sí ètò àjọ Ọlọ́run. Rọ gbogbo àwọn ará láti fi àwọn ìmọ̀ràn tá a pèsè sílò, kí wọ́n sì tọ́jú àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí kí wọ́n lè rí wọn lò lọ́jọ́ iwájú.

Orin 10 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 26

Orin 216

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù July sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! August 8 lọni. (Àbá kẹrin ni kó o lò láti fi Jí! August 8 lọni.) Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará mọ bá a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Èéṣe tí ẹ̀yin ènìyàn yìí fi ń wá lemọ́lemọ́.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.

8 min: Àpótí Ìbéèrè. Kí alàgbà bójú tó o. Ka gbogbo àpilẹ̀kọ náà, kó o sì sọ̀rọ̀ lórí wọn.

25 min: “Bí A Ṣe Lè Wàásù Ní Ìpínlẹ̀ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé.”b Sọ àwọn ètò tí ìjọ ṣe fún wíwàásù láwọn ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ méjì tó wà ní ìpínrọ̀ 4 àti 5 tàbí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn táwọn ará ń lò tó sì ń méso jáde ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń wàásù ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé.

Orin 173 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 2

Orin 60

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

22 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣàlàyé Ìdí Ọ̀rọ̀? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 254, ìpínrọ̀ 1 àti 2. Nígbà tá a bá ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ tá a sì ń sọ báwọn olùgbọ́ ṣe lè fi wọ́n sílò, bóyá nígbà tá a wà lóde ẹ̀rí tàbí lórí pèpéle, a óò túbọ̀ kọ́ni lọ́nà tó múná dóko bá a bá ṣàlàyé ìdí tá a fi sọ ohun tá a sọ dípò tí a ó kàn fi máa tẹnu mọ́ ohun tá a sọ ṣáá pé òun ló tọ̀nà. Lo àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú ìwé Reasoning tàbí nínú àwọn ìwé mìíràn, èyí tó ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, láti fi jẹ́ káwọn ará mọ bá a ṣe lè (1) fa àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yọ ká sì ṣàlàyé wọn, (2) fi ẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ wa nídìí nípa fífa irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ yọ látinú ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ká tàbí látinú ẹsẹ mìíràn tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn, (3) lo àpèjúwe kan láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ tá à ń sọ bọ́gbọ́n mu, (4) lo ìbéèrè láti fi ran àwọn olùgbọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ. Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣàlàyé ìdí ọ̀rọ̀ wa.

15 min: Àwọn ìrírí táwọn akéde ní. Sọ pé káwọn ará sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n ti ní lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yìí, bóyá nígbà tí wọ́n lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí nígbà tí wọ́n ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí mìíràn.

Orin 32 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́