Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni La Óò Máa Fi Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1 Ẹ ò rí bó ṣe mọ́kàn wa yọ̀ tó nígbà tá a rí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? gbà ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run!” Àwọn tó wà ní àpéjọ yẹn láyọ̀ nígbà tí olúkúlùkù wọn gba ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé náà lẹ́yìn tí ìpàdé parí lọ́jọ́ Sátidé. Báwo la ṣe wá fẹ́ máa lo irin iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tuntun yìí? Ṣe la dìídì ṣe é fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a óò kọ́kọ́ lo ìwé tuntun yìí nínú iṣẹ́ ìwàásù lóṣù March, a rọ àwọn akéde láti bẹ̀rẹ̀ sí í fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
2 Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tá À Ń Darí Lọ́wọ́lọ́wọ́: Kí àwọn akéde tó bá ń fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lo ìfòyemọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń pinnu ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà bẹ̀rẹ̀ sí lo ìtẹ̀jáde tuntun yìí láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìgbà tó yẹ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Bó bá jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ ìwé tuntun yìí. Bẹ́ ẹ bá sì ti lọ jìnnà nínú ìwé Ìmọ̀, ẹ lè tẹ̀ síwájú nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ní orí tó bá kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò lọ́wọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ mu. Bó bá sì jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kẹ́ ẹ parí ìwé Ìmọ̀, ẹ lè pinnu láti kúkú parí ìwé Ìmọ̀ yẹn.
3 Kò síyè méjì pé gbogbo wa la mọ ọ̀pọ̀ èèyàn tí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni yìí máa ṣe láǹfààní. O ò ṣe wá bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan nínú ìwé tó ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé yìí? Bí àpẹẹrẹ, àwọn tá a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ ṣùgbọ́n tí wọn ò tíì ya ara wọn sí mímọ́ kí wọ́n sì ṣèrìbọmi lè fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ padà nínú ìwé tuntun yìí. Àwọn òbí sì lè fẹ́ máa fi ìwé yìí gbin ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wọn.—Kól. 1:9, 10.
4 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kejì: Ṣó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kẹ́kọ̀ọ́ ìwé kejì tó bá ti parí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó yẹ o. Bó bá ṣe kedere pé akẹ́kọ̀ọ́ kan ń tẹ̀ síwájú tó sì fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tó ń kọ́ àmọ́ tó jẹ́ pé kò kàn yára tó bó ṣe yẹ ni, ẹ lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìṣó nípa lílo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. A ní ìgbọ́kànlé pé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni yóò jẹ́ irin iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyọrí, ìyẹn iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20.