Bá A Ṣe Máa fi Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
1. Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
1 Inú wa dùn gan-an nígbà tá a gba ìwé náà ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa”! Bá a ṣe sọ nínú ìfilọ̀, a ṣe ìwé yìí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìlànà ìwà rere Jèhófà ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé a ò ṣe ìwé yìí láti kọ́ni láwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. A ò ní máa lo ìwé yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
2. Báwo lá ṣe máa lo ìwé yìí, àwọn wo la sì lè fi kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?
2 Ìwé yìí ló máa jẹ́ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì tá a ó máa fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn tó bá ti ka ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tán. Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé bí òye òtítọ́ ṣe tètè ń yé àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Torí náà, bí òye akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ṣe tó ló máa pinnu bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á ṣe yára tó. Kẹ́ ẹ máa rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ lóye ibi tẹ́ ẹ kà dáadáa. Ẹ má ṣe lo ìwé yìí láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi oríṣiríṣi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ, tó sì hàn kedere pé wọn ò fẹ́ mú ìgbé ayé wọn bá ohun tí Bíbélì kọ́ni mu.
3. Kí la máa ṣe tó bá jẹ́ pé ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run la fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹnì kan?
3 Tó bá jẹ́ pé ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run lo fi ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, tẹ́ ẹ sì ti fẹ́ẹ̀ parí ẹ̀, o lè pinnu pé kẹ́ ẹ kúkú parí ìwé náà, kó o wá rọ akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kó ka ìwé“Ìfẹ́ Ọlọ́run” láyè ara ẹ̀. Tí ẹ ò bá tíì rìn jìnnà, á dáa kẹ́ ẹ kúkú mú ìwé tuntun náà, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ láti orí kìíní. Bíi ti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, fúnra yín lẹ máa pinnu bóyá ẹ máa ka àfikún ẹ̀yìn ìwé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
4. Kí la máa ṣe tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá ti ṣèrìbọmi kó tó parí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni àti ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
4 Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti ṣèrìbọmi kó tó ka ìwé méjèèjì tán, ó gbọ́dọ̀ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ títí tó fi máa ka ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” tán. Ẹ ṣì lè máa ròyìn àkókò tẹ́ ẹ fi ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítọ̀hún àní lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi. Bí akéde kan bá wà pẹ̀lú yín nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, tó sì kópa nínú rẹ̀, òun náà lè ròyìn àkókò tẹ́ ẹ lò.
5. Báwo la ṣe lè lo ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” láti ran àwọn akéde tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?
5 Bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ bá ní kó o darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, wọ́n lè ní kó o jíròrò àwọn orí kan pàtó nínú ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” pẹ̀lú ẹni náà. Kò pọn dandan ká pẹ́ lẹ́nu irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn pàtàkì ni ìwé tuntun tá a dìídì ṣe kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú “Ìfẹ́ Ọlọ́run” yìí jẹ́ fún wa!—Júúdà 21.