Àpótí Ìbéèrè
◼ Àwọn ìtẹ̀jáde méjì wo la gbọ́dọ̀ fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tá a bá ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ìwé Bíbélì fi kọ́ni ni olórí ìwé tá à ń lò láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú tá a bá fi àwọn ìwé míì, irú bíi àṣàrò kúkúrú tó bá bá ohun tá a jíròrò mu, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ sapá láti tètè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì fi kọ́ni pẹ̀lú wọn. Ọ̀pọ̀ àbájáde tó ta yọ la ti rí látàrí lílo ìwé Bíbélì fi kọ́ni láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bẹ́ ẹ bá ti parí ìwé Bíbélì fi kọ́ni, tí ẹni tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà sì ń tẹ̀ síwájú, kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Kól. 2:7) Ojú ìwé kejì ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run ṣàlàyé ìdí tá a fi tẹ ìwé náà pé: “Bíbélì rọ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láti fi ‘èrò orí mòye . . . ohun tí . . . gíga àti jíjìn’ àwọn òtítọ́ Ọlọ́run tó ṣeyebíye jẹ́. (Éfésù 3:18) Ìdí yìí gan-an la fi ṣe ìwé yìí. Ìrètí wa ni pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí, tí wàá sì túbọ̀ di ẹni tá a mú gbára dì láti rìn lójú ọ̀nà tóóró náà tó lọ sí ìyè nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.”
Bí ẹni tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá tóótun fún ìrìbọmi kó tó parí àwọn ìwé méjèèjì yìí, ẹ gbọ́dọ̀ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó lẹ́yìn tó bá ti ṣèrìbọmi títí tí ìwé kejì fi máa parí. Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣì lè máa ròyìn wákàtí tó bá ń lò, ó sì lè ròyìn ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀hún. Akéde tó bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹni tó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, tó sì lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún lè ròyìn wákàtí rẹ̀.