Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 16
Orin 106
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 2 ìpínrọ̀ 12 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 24
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 43-46
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 44:1-17
No. 2: Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ (lr orí 10)
No. 3: Ipá Ìwàláàyè Èèyàn àti Ti Ẹranko Ló Ń Jẹ́ Ẹ̀mí (td-YR 13B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 130
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀.
10 min: A Fi Orúkọ Jèhófà Mọ̀ Ọ́n. Àsọyé tó ń tani jí, tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 274, ìpínrọ̀ 2 sí 5.
10 min: Àwọn ìrírí. Jẹ́ káwọn ará mọ bẹ́ ẹ ṣe kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sí nígbà tẹ́ ẹ̀ ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Ní káwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà tàbí nígbà tí wọ́n lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè ṣètò pé kí akéde kan tàbí méjì ṣàṣefihàn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
10 min: “Bá A Ṣe Máa fi Ìwé ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’ Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 97