Múra Sílẹ̀ Dáadáa fún Ìrántí Ikú Kristi
Inú wa dùn gan-an fún àǹfààní láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù Kristi táwa ọmọlẹ́yìn Kristi ní! (Lúùkù 22:19) Kí làwọn ohun tó yẹ ká ṣe ní ìmúrasílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
◼ Àkókò àti Ibi Tá A Máa Lò: Ó yẹ kí gbogbo èèyàn mọ ìgbà tá a máa bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àti ibi tá a ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá jẹ́ pé ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó máa kọ́kọ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tètè dé, kí wọ́n má sì pẹ́ jù kí wọ́n tó kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n bàa lè fún àwọn tó kàn láyè láti wọlé lásìkò. Bákan náà, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ò dúró sẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé, ojú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ àti ibi ìgbọ́kọ̀sí, kí èrò má bàa pọ̀ jù níbẹ̀.
◼ Ìwé Ìkésíni: Ṣé gbogbo àwọn akéde ló ti ní ìwé ìkésíni lọ́wọ́, ṣé wọ́n sì mọ ohun tó wa níbẹ̀? Ṣó o ti fi bó o ṣe máa fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà dánra wò? Àwọn wo lo máa fún ní ìwé ìkésíni? A gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé a pín gbogbo ìwé ìkésíni náà tán.
◼ Ètò Ìrìnnà: Àwọn kan lára àwọn tó fẹ́ wá, títí kan àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè nílò ìrànlọ́wọ́ lórí bí wọ́n ṣe máa dé ibi tá a máa lò tàbí ìrànlọ́wọ́ míì. Kí làwọn ètò tá a ti ṣe láti ṣèrànwọ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀?
◼ Àwọn Ohun Ìṣàpẹẹrẹ: Kẹ́ ẹ rí i dájú pé ẹ ò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kí oòrùn tó wọ̀. A gbọ́dọ̀ ṣètò bá a ṣe máa gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ sọ́dọ̀ ẹni àmì òróró tó jẹ́ aláìlera tí kò lè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ lẹ gbọ́dọ̀ wá, kẹ́ ẹ sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003, ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 14 àti 17.
◼ Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ẹ rí i pé inú gbọ̀ngàn tẹ́ ẹ máa lò wà ní mímọ́ tónítóní ṣáájú àkókò. Àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu ni kẹ́ ẹ lò, ẹ sì ti gbọ́dọ̀ tò wọ́n sílẹ̀ ṣáájú àkókò. Tó bá jẹ́ gbọ̀ngàn mìíràn lẹ fẹ́ lò, ẹ rí i dájú pé àwọn ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó dáa lẹ lò káwọn tó wà níkàlẹ̀ bàa lè gbọ́ ohun tí alásọyé ń sọ. Kó tó di ọjọ́ náà ni kẹ́ ẹ ti yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tó máa gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kẹ́ ẹ sì fún wọn nítọ̀ọ́ni nípa ojúṣe wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é. Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ àti ìmúra wọn gbọ́dọ̀ bójú mu.
Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti ìjọ lápapọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí, ìyẹn Ìrántí Ikú Jésù Kristi. Ó dájú pé Jèhófà á rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí gbogbo àwọn tó fìmọrírì àtọkànwá hàn fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún aráyé nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, Jésù Kristi.