Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 23
Orin 76
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 7 àti àpótí tó wà lójú ìwé 29
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 47-50
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 48:1-16
No. 2: Ṣó Yẹ Ká Máa Bẹ̀rù Èṣù?
No. 3: Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run (lr orí 11)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 118
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Múra sílẹ̀ láti lo Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! April–June. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní káwọn ará sọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ lò ó. Ní kí wọ́n sọ ìbéèrè tí wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa fẹ́ kà. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà. Kí ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà dá lórí béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìpadàbẹ̀wò.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Fọ̀wọ̀ Hàn Nípa Títẹ́tí Bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí Èrò Tí Onílé Ní Kó O sì Gbé Èrò Rẹ̀ Yẹ̀ Wò. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ó dá lérí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 186 àti 187. Jẹ́ kí akéde kan ṣàṣefihàn bá a ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò nígbà tá a bá ń bá onílé sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, ní kí àwùjọ sọ ìdí tí ọ̀nà tí akéde náà gbà bá onílé náà sọ̀rọ̀ fi gbéṣẹ́.
Orin 89