Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 30
Orin 217
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 3 ìpínrọ̀ 8 sí 15, àti àpótí tó wà lójú ìwé 30
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 1-6
No. 1: Ẹ́kísódù 1:1-19
No. 2: Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà (lr orí 12)
No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Kọ Gbogbo Onírúurú Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀? (td-YR 13D)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 128
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Ṣe àwọn ìfilọ̀ tó bá ní í ṣe pẹ̀lú Ìrántí Ikú Kristi. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn ìparí oṣù March sílẹ̀.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Ran Àwọn Ẹni Tuntun Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ àsọyé yìí. Kó rán àwọn akéde létí ojúṣe wọn láti ṣèrànwọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn akéde tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ àtàwọn míì, irú bíi ojúlùmọ̀ àti mọ̀lẹ́bí, tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2008, ojú ìwé 4.) Ṣe àṣefihàn ṣókí kan tó dá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn kan tó wá síbí Ìrántí Ikú Kristi. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣètò fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní Sunday, April 5. O lè dábàá bí wọ́n ṣe lè ṣe é.
15 min: “Fídíò Tó Dá Lórí Bíbélì, ìyẹn The Bible—A Book of Fact and Prophecy.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí ìjíròrò náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ jíròrò orí 3, ìpínrọ̀ 8 sí 17 nínú ìwé náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Orin 213