Fídíò Tó Dá Lórí Bíbélì, Ìyẹn The Bible—A Book of Fact and Prophecy
Apá àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ fídíò mẹ́ta tó dá lórí Bíbélì tá a ṣe sórí àwo DVD èyí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní The Bible—A Book of Fact and Prophecy sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ìwé tó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, àkòrí rẹ̀ ni Mankind’s Oldest Modern Book. Lẹ́yìn tó o bá ti wo fídíò náà tán, dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
(1) Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu? (2) Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Bíbélì tá a ní lóde òní ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí wọ́n kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀? (3) Àwọn ohun wo ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ nígbàanì? (4) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọkùnrin yìí gbà kópa nínú mímú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn dé ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, John Wycliffe, Johannes Gutenberg, William Tyndale, John Hus, Martin Luther, Casiodoro de Reina àti Charles Taze Russell? Báwo ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe gbéjà ko Bíbélì? (5) Báwo làwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tó wà nínú Bíbélì ṣe ran àwọn èèyàn kan lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro bí, àìsàn (Sm. 34:8), sísọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú (1 Tím. 6:9, 10), ìpínyà láàárín tọkọtaya, àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó (1 Kọ́r. 13:4, 5; Éfé. 5:28-33), àti mímú kí kíkó ọrọ̀ jọ gbani lọ́kàn (Mát. 16:26)? (6) Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé téèyàn bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó lè ràn án lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà (Lúùkù 10:27)? (7) Àwọn ọ̀nà wo ni títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ti gbà fún ẹ láyọ̀ gan-an? (8) Báwo lo ṣe lè lo fídíò yìí láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2006, ojú ìwé 8.