Ìjà Tí Casiodoro de Reina Jà fún Bibeli Èdè Spanish
SPAIN ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún jẹ́ ibi eléwu láti ka Bibeli. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti fún àwọn Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ nítọ̀ọ́ni láti fòpin sí ìwà àìtẹ̀lé ohun tí gbogbogbòò tẹ́wọ́ gbà tí ó bá ṣèèṣì fara hàn. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin kan ń bẹ ní gúúsù Spain tí kì í ṣe pé ó ka Ìwé Mímọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́jẹ̀ẹ́ láti túmọ̀ rẹ̀ sí èdè àbínibí, kí àwọn ará Spain baà lè kà wọ́n. Casiodoro de Reina ni orúkọ rẹ̀.
A ru ìfẹ́ ọkàn Reina nínú Bibeli sókè ní àwọn ọdún tí ó lò ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti San Isidro del Campo, ní ẹ̀yìn odi Seville, Spain. Ní àwọn ọdún 1550, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí lo wákàtí púpọ̀ jù fún kíka Ìwé Mímọ́ ju bíbójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ àlùfáà wọn lọ. Ìhìn iṣẹ́ Bibeli sì yí ìrònú wọn padà. Wọ́n kọ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kátólíìkì sílẹ̀ ní ti lílo ère àti ìgbàgbọ́ nínú pọ́gátórì. Láìṣeéyẹ̀sílẹ̀, ojú ìwòye wọn di mímọ̀ ní agbègbè náà, bí wọ́n sì ṣe ń bẹ̀rù kí àwọn Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní ilẹ̀ Spain má fàṣẹ ọba mú wọn, wọ́n pinnu láti sá lọ sí òkè òkun. Reina wà lára ọ̀kan nínú àwọn ẹni 12 tí wọ́n kẹ́sẹ járí nínú sísá àsálà lọ sí Geneva, Switzerland.
Lẹ́yìn jíjàjàbọ́ yẹn, ó rin ìrìn àjò láti ìlú Europe kan lọ sí òmíràn, ó ṣáà ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti lè yẹra fún àwọn tí ń ṣenúnibíni sí i. Ní 1562, àwọn aṣèwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ tí inú ń bí dáná sun àwòrán rẹ̀ tí ó wà ní Seville, ṣùgbọ́n ìhàlẹ̀ oníwà òǹrorò yẹn kò mú kí Reina dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó ń ṣe. Láìka pé àwọn onínúnibíni ti pinnu láti fún ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i ní iye owó kan àti ìbẹ̀rù ìgbà gbogbo pé a lè fàṣẹ ọba mú un sí, ó ṣiṣẹ́ láìsinmi lórí ìtumọ̀ rẹ̀ sí èdè Spanish. Ó ṣàlàyé pé: “Yàtọ̀ sí àkókò tí ara mi kò dá tàbí tí mo ń rin ìrìn àjò, . . . kálàmù kò kúrò lọ́wọ́ mi.”
Láàárín ọdún mẹ́wàá Reina parí iṣẹ́ náà. Ní 1569, a tẹ ìtumọ̀ Bibeli rẹ̀ lódindi jáde ní Basel, Switzerland. Iṣẹ́ títayọ lọ́lá yìí ni àkọ́kọ́ odindi ìtumọ̀ èdè Spanish tí a ṣe láti inú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bibeli èdè Latin ti wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ṣùgbọ́n èdè Latin ní èdè àwọn ọ̀tọ̀kùlú. Reina gbà gbọ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó yẹ kí ó lóye Bibeli, ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ góńgó náà.
Nínú ìfáárà ìtumọ̀ rẹ̀, ó ṣàlàyé àwọn ìdí rẹ̀. “Kò sí iyè méjì pé, kíka Ìwé Mímọ́ léèwọ̀ ní èdè tí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbọ́ mú àbùkù ńláǹlà wá bá Ọlọrun, ó sì ṣèpalára fún ire ènìyàn. Ó hàn gbangba pé iṣẹ́ Satani àti àwọn tí ó ń darí nìyí. . . . Ní rírí i pé Ọlọrun fún àwọn ènìyàn ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí ó sì ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn lóye rẹ̀, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e, ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á léèwọ̀ ní èdè èyíkéyìí kò lè ní ète rere.”
Gbólóhùn onígboyà ni èyí jẹ́, níwọ̀n bí a ti tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọdún 18 lẹ́yìn tí Àkọsílẹ̀ Àwọn Ìwé Àkàléèwọ̀ tí Àwọn Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní ilẹ̀ Spain ṣe, ti fòfin de Bibeli “ní èdè ìbílẹ̀ Castile [èdè Spanish] tàbí ní èdè àbínibí mìíràn.” Ó ṣe kedere pé, Reina kò fàyè gba ìbẹ̀rù ènìyàn láti dènà ìfẹ́ rẹ̀ fún òtítọ́.
Yàtọ̀ sí níní ìfẹ́ ọkàn jíjinlẹ̀ láti mú kí Bibeli wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tí ń sọ èdè Spanish, Reina tún fẹ́ mú ìtumọ̀ tí ó péye jù lọ jáde. Nínú ìfáárà rẹ̀, ó làdí àwọn àǹfààní títúmọ̀ tààràtà láti inú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Reina ṣàlàyé pé, àwọn àṣìṣe kan ti yọ́ wọnú ẹsẹ ìwé mímọ́ ní èdè Latin ti Vulgate. Ọ̀kan nínú àwọn tí ó hàn gbangba jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni yíyọ orúkọ àtọ̀runwá kúrò.
Orúkọ Àtọ̀runwá ní Àwọn Ìtumọ̀ Èdè Spanish
Reina rí i pé orúkọ Ọlọrun, Jehofa, yẹ kí ó wà nínú ìtumọ̀ Bibeli tí a bá fara balẹ̀ ṣe, gẹ́gẹ́ bí o ti wà nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣà fífi àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọrun” tàbí “Oluwa” rọ́pò orúkọ àtọ̀runwá náà. Nínú ìfáárà ìtumọ̀ rẹ̀, ó ṣàlàyé àwọn ìdí rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe tààràtà.
“A tọ́jú orúkọ náà (Iehoua), nítorí tí a ní àwọn ìdí pàtàkì. Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé ohunkóhun tí a bá lè rí nínú ìtumọ̀ wa, ó ṣeé ṣe kí a rí i nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ èdè Heberu, èrò tiwa sì ni pé, a kò lè fò ó tàbí kí a yí i padà láìhùwà àìṣòtítọ́ àti àìbọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọrun, èyí tí ó pàṣẹ pé, kí a má ṣe yọ ohunkóhun kúrò tàbí kí a fi kún un. . . . Àṣà [fífo orúkọ náà], èyí tí Eṣu dá sílẹ̀, wá láti inú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti àwọn rábì òde òní, àwọn tí ó jẹ́ pé bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn ń bọ̀wọ̀ fún un, ní ti gàsíkíá wọn bo orúkọ mímọ́ Rẹ̀ mọ́lẹ̀, ní mímú kí àwọn ènìyàn Ọlọrun gbàgbé ohun tí ó fẹ́ kí ó fi òun hàn yàtọ̀ sí àwọn . . . ọlọrun mìíràn.”
Ìfẹ́ ọkàn tí ó yẹ́ ní gbígbóríyìn fún, tí Reina ní láti gbé orúkọ Ọlọrun ga, ní àbájáde gíga lọ́lá. Títí di ọjọ́ wa, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìtumọ̀ èdè Spanish—ti Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì—ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìṣáájú yìí, ní lílo orúkọ àtọ̀runwá náà jálẹ̀jálẹ̀. Ọpẹ́ ńlá yẹ Reina, àwọn òǹkàwé ìtumọ̀ Bibeli ní èdè Spanish lè tètè lóye pé Ọlọrun ní orúkọ kan tí ó ń fi í hàn yàtọ̀ sí àwọn ọlọrun mìíràn.
Ohun tí ó yẹ fún àfiyèsí jù lọ ni òkodoro òtítọ́ náà pé orúkọ Jehofa ní èdè Heberu hàn kedere lórí ojú ìwé Bibeli Reina. Reina fi ìgbésí ayé rẹ̀ fún ète wíwúni lórí ti títọ́jú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ní mímú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè kan tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lè kà.