Ija-ogun Bibeli Ledee Spanish fun Lilaaja
NI ỌJỌ kan ninu oṣu October 1559, awọn Katoliki ara Spain bii 200,000 rọ́ lọ si ìhà ariwa ilu-nla Valladolid. Ohun ti o fà wọn mọra naa ni ayẹyẹ ìdẹ́bi ikú funni nipasẹ Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀, nibi ti “a ti jó awọn ojiya ipalara meji láàyè ninu iná, ti a sì lọ́ awọn mẹwaa lọ́rùn pa.” Wọn jẹ́ “aládàámọ̀.”
Gbajúmọ̀ ọ̀dọ́ ọba Philip II fúnraarẹ̀ ni ó ṣe alága lori iṣẹlẹ naa. Nigba ti ọkunrin kan ti a dẹ́bi fun bẹbẹ fun aanu, ọba naa fi ibinu dahun pe: “Bi ó bá jẹ́ pe ọmọkunrin temi funraami ni ó jẹ́ abòṣì eniyan bii tirẹ, emi funraami ni yoo dáná sun ún.” Ki ni ẹṣẹ ojiya ipalara alairinnakore naa? Oun wulẹ ti ń ka Bibeli ni.
Ni akoko kan naa, eto-ajọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ ti Katoliki ni ọwọ rẹ̀ dí ni ilu-nla Andalusia ti Seville. Nibẹ, awujọ awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ni ilé awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti San Isidro del Campo, ṣẹṣẹ gba awọn ẹrù Bibeli ni èdè Spanish ti a fi ṣọwọ si wọn ni ìdákọ́ńkọ́ ni. Awọn atanilólobó yoo ha táṣìírí wọn bi? Awọn kan ti wọn mọ daju pe awọn wà ninu ewu ńláǹlà sá kuro ni orilẹ-ede naa. Ṣugbọn 40 ninu awọn wọnni ti wọn duro sẹhin ni wọn kò fi bẹẹ rìnnàkore a sì jó wọn níná ni orí òpó, ninu wọn ni ọkunrin naa gan-an ti ó ti ṣe fàyàwọ́ awọn Bibeli naa wọnu orilẹ-ede naa wà. Ilu Spain ti ọrundun 16 jẹ́ ibi ti ó léwu fun awọn onkawe Bibeli—awọn diẹ bọ́ lọwọ Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ naa.
Lara awọn diẹ naa ni ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tẹlẹri kan, Casiodoro de Reina (nǹkan bii 1520 si 1594) wà. Ó sá lọ si London, ṣugbọn nibẹ paapaa kò lè rí aabo. Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ naa gbé ẹ̀bùn owo kalẹ fun mímú rẹ̀, ikọ̀ Spain sì ile-ẹjọ England sì di rìkíṣí lati tàn án pada si ipinlẹ tí Spain ń dari ni gbogbo ọ̀nà bíi fífà bíi wíwọ́. Ni akoko kukuru, awọn ẹ̀sùn èké nipa panṣaga ati ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ti a fi kàn án fipá mu un lati lọ si England.
Pẹlu awọn ohun àgbójúlé tí kò tó nǹkan ati idile tí ń pọ̀ sii lati ṣetilẹhin fún, ó kọ́kọ́ wá ibi ìsádi ni Frankfurt. Lẹhin naa, iwakiri rẹ̀ fun ibi ìsádi onisin darí rẹ̀ lọ si France, Holland, ati nikẹhin Switzerland. Sibẹ ni gbogbo akoko yii, ọwọ rẹ̀ dí. ‘Àyàfi ni akoko ti ara mi kò dá tabi ti mo ririn-ajo, . . . kálàmù kò kuro lọwọ mi,’ ni ó ṣalaye. Ó lo ọpọlọpọ ọdun ni titumọ Bibeli si èdè Spanish. Títẹ 2,600 ẹ̀dà Bibeli ti Reina ni a bẹrẹ ni ìgbẹ̀hìn-gbẹ́hín ni 1568 ni Switzerland ti a sì pari ni 1569. Ìhà titayọ kan ninu itumọ Reina ni pe ó lo Iehoua (Jehová) dipo Señor (Oluwa) fun Tetragrammaton, ọrọ Heberu onilẹta mẹrin naa fun orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun.
Bibeli Ledee Spanish Lẹ́nu Ṣíṣe
Lọna ti ó takora, ni akoko kan nigba ti, Bibeli gbèrú di pupọ ni Europe, nitori ìhùmọ̀ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, wọn ń di ohun ti ó ṣọ̀wọ́n ni Spain. Kò ti ń fi ìgbà gbogbo rí bayii. Fun ọpọ ọrundun Bibeli ni iwe ti a pínkiri lọna gbigbooro julọ ni Spain. Awọn ẹ̀dà ti a fi ọwọ́ kọ wà larọọwọto ni èdè Latin, ati fun awọn ọrundun melookan, ni èdè Gothic paapaa. Opitan kan ṣalaye pe ni Sanmani Agbedemeji, “Bibeli—gẹgẹ bi orisun isunniṣe ati ọla-aṣẹ, gẹgẹ bi ọ̀pá idiwọn fun igbagbọ ati ihuwa—tubọ yọri-ọla ni Spain ju Germany tabi England lọ.” Awọn oniruuru ìtàn Bibeli, Iwe-orin (tabi, awọn Psalmu), awọn ìwé-àlàyé, awọn ìtàn iwarere, ati awọn iwe ti o farajọra di eyi ti ó tà julọ ni sanmani naa.
Awọn akọ̀wé aláwòkọ ti a dálẹ́kọ̀ọ́ fi aápọn ṣe ìtúnmújáde awọn iwe àfọwọ́kọ kíkọyọyọ Bibeli. Bi o tilẹ jẹ pe ó gba 20 akọ̀wé ni odidi ọdun kan lati mú kìkì ẹ̀dà iwe àfọwọ́kọ kan jade ní taarata, ọpọlọpọ awọn Bibeli lede Latin ati ẹgbẹẹgbẹrun awọn iwe àlàyé lori Bibeli lede Latin ń tànkálẹ̀ ni Spain nigba ti o fi maa di ọrundun 15.
Siwaju sii pẹlu, nigba ti èdè Spanish bẹrẹ sii gbèrú, ọkàn-ìfẹ́ ru sókè ninu níní Bibeli ni èdè ibilẹ. Ni kutukutu lẹhin lọhun-un ni ọrundun 12, Bibeli ni a tumọsi èdè Romance, tabi èdè Spanish ti ijimiji, èdè ti awọn eniyan wiwọpọ ń sọ.
Ìtanijí Onígbà Kukuru
Ṣugbọn ìtanijí naa ni kò ní pẹ́. Nigba ti awọn ọmọlẹhin John Calvin, Wycliffe, ati John Huss lo Iwe Mimọ lati gbèjà igbagbọ wọn, iṣarasihuwa naa yára kánkán ó sì jẹ́ oníwà-ipá. Awọn alaṣẹ Katoliki wo Bibeli kíkà pẹlu ifura, awọn itumọ ti wọn sì ṣẹṣẹ ń lọ lọwọ ní awọn èdè wiwọpọ ni a bu ẹnu àtẹ́ lù patapata.
Igbimọ Katoliki ti Toulouse (France), eyi ti o padepọ ni 1229, polongo pe: “A kà á léèwọ̀ pe ọ̀gbẹ̀rì eyikeyii kò gbọdọ ni awọn iwe Majẹmu Laelae tabi Titun ti a tumọsi èdè ti gbogbo eniyan ń sọ. Bi awọn ẹlẹmii isin kan bá fẹ́, ó lè ni Iwe-orin kan tabi Iwe-adura [iwe akojọ awọn orin ati adura] . . . ṣugbọn kò sí ipo kankan ti oun gbọdọ fi ní awọn iwe ti a mẹnukan loke ti a tumọsi èdè Romance.” Ni ọdun mẹrin lẹhin naa, James I ti Aragon (ọba lori ẹkùn titobi ti omi fẹrẹẹ yika) fún gbogbo awọn wọnni ti wọn ní Bibeli ní èdè ti gbogbo eniyan ń sọ ní kìkì ọjọ mẹjọ lati fi wọn lé biṣọọbu adugbo lọwọ fun sísun. Ìkùnà lati ṣe bẹẹ, yala nipasẹ alufaa ṣọọṣi tabi nipasẹ ọ̀gbẹ̀rì, yoo mú ki ẹni ti ó ní i naa di ẹni ti a fura àdámọ̀ sí.
Laika awọn ìfòfindè wọnyi si—eyi ti a kìí figba gbogbo tẹle lọna pipe perepere—awọn ará Spain kan lè fọ́nnu níní Bibeli kan lede Romance nikaawọ ni apá ti ó gbẹhin ninu Sanmani Agbedemeji. Eyi wá si opin lojiji pẹlu idasilẹ Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ ti Spain labẹ Ọbabinrin Isabella ati Ọba Ferdinand ni 1478. Ni 1492, ninu ilu-nla ti Salamanca nikan, 20 ẹ̀dà Bibeli afọwọkọ ti kò ṣee diyele ni wọn sun níná. Kìkì awọn iwe àfọwọ́kọ Bibeli ledee Romance ti ó là á já ni awọn wọnni ti a kó sinu ibi ìkówèésí àdáni ti ọba tabi awọn ọ̀tọ̀kùlú alagbara diẹ ti wọn kọja ẹni ti a lè fura si.
Fun ọgọrun-un ọdun meji ti o tẹle e, kìkì Bibeli Katoliki ti a faṣẹ si ti a tẹ̀ ni Spain—yatọ si Latin Vulgate—ni Complutensian Polyglott, Bibeli elédè pupọ akọkọ, ti Biṣọọbu Àgbà Cisneros ṣonígbọ̀wọ́ fun. Ó jẹ́ iṣẹ ti o fi ijinlẹ ẹkọ hàn niti gidi, ó sì daju pe kò wà fun eniyan kan ṣáá loju pópó. Kìkì ẹ̀dà 600 ni a ṣe, awọn eniyan diẹ ni wọn sì lè loye rẹ̀ nitori pe awọn ẹsẹ Bibeli naa ni a kọ ní èdè Heberu, Aramaiki, Griki, ati Latin—kì í ṣe ni èdè Spanish. Siwaju sii pẹlu, iye-owo rẹ̀ ti ga ju. Iye rẹ̀ jẹ́ owó góòlù ducat mẹta (ti o ṣe deedee pẹlu owó iṣẹ́ oṣu mẹfa fun lebira kan lásán-làsàn).
Bibeli Ledee Spanish Ń Lọ Lábẹ́lẹ̀
Ni kutukutu ọrundun 16, “Tyndale” ti Spain ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Francisco de Enzinas dide. Ọmọkunrin fun onílé ọlọ́nà kan ti o jẹ́ ọlọ́rọ̀ ni Spain, ó bẹrẹ sii tumọ Iwe Mimọ Kristian lede Griki si èdè Spanish nigba ti o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ akẹkọọ. Lẹhin naa ni o mu ki a tẹ itumọ naa ni Netherlands, ati ni 1544 o fi igboya gbiyanju lati gba iyọnda ọlọba fun ipinkiri rẹ̀ ni Spain. Olu-ọba Spain, Charles I, wà ni Brussels ni akoko naa, Enzinas sì lo akoko anfaani yii lati beere fun ilohunsi ọba fun iwewee dawọle rẹ̀.
Ijumọsọrọpọ ti ó ṣàrà-ọ̀tọ̀ laaarin awọn ọkunrin mejeeji ni a ti rohin bayii: “Iru iwe wo niyii?” ni olu-ọba naa beere. Enzinas fesi pada pe: “Eyi ni apakan Iwe Mimọ ti a ń pe ni Majẹmu Titun.” “Ta ni onṣewe iwe naa?” ni ó beere lọwọ rẹ̀. Ó fesi pada pe, “Ẹmi mimọ ni.”
Olu-ọba naa faṣẹ si itẹwejade ṣugbọn lori ipo àfilélẹ̀ kan—pe ki alufaa ti ń gbọ́ ìjẹ́wọ́ rẹ̀, ti o jẹ́ ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ara Spain kan, pẹlu fi edidi itẹwọgba rẹ̀ sí i. Laijasi bi o ti yẹ fun Enzinas, iru itẹwọgba bẹẹ ni a kò mú wà larọọwọto nigba ti o nilo rẹ̀, ó sì bá araarẹ̀ ninu atimọle nipasẹ Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ laipẹ. Lẹhin ọdun meji ó dọgbọn lati sálà.
Ni ọdun diẹ lẹhin naa, ẹ̀dà itẹjade itumọ yii ti a tunṣe ni a tẹ̀ ni Venice, Italy, ẹ̀dà itẹjade Iwe Mimọ yii sì ni Julián Hernández gbé ní bòókẹ́lẹ́ wọnu Seville, Spain. Ṣugbọn a mú un, ati lẹhin ọdun meji idaloro ati ifisẹwọn, a fiya iku jẹ ẹ́ pẹlu awọn akẹkọọ Bibeli ẹlẹgbẹ rẹ̀ yooku.a
Ni Ijokoo Igbimọ ti Trent (1545-63), Sọọṣi Katoliki tún idẹbi rẹ̀ fun titumọ Bibeli si èdè ibilẹ sọ. Ó tẹ atọka awọn iwe ti a kàléèwọ̀, eyi ti ó ni gbogbo awọn itumọ Bibeli wọnni ti a ti mujade laisi itẹwọgba ṣọọṣi naa ninu. Lẹnu kan eyi tumọ si pe gbogbo awọn Bibeli èdè ibilẹ ti Spain ni a fi ofin kàléèwọ̀ ati pe wiwulẹ ni ọ̀kan ní ìní lè pari si iwe aṣẹ iku ẹni naa.
Ni ọdun diẹ lẹhin itẹjade itumọ ti Reina, Cipriano de Valera, ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tẹlẹri miiran ẹni ti ó bọ́ lọwọ ibinu Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ ni Seville, tún un ṣe. Ẹ̀dà itumọ yii ni a tẹ̀ ni Amsterdam ni 1602 C.E., a sì gbé awọn ẹ̀dà diẹ wọnu Spain. Ninu awọn ẹ̀dà itumọ rẹ̀ ipilẹṣẹ ati ti àtúnṣe, Bibeli Reina-oun-Valera ni ó ṣì jẹ́ itumọ ti a lo lọna gbigbooro julọ laaarin awọn Protẹstanti ti ń sọ èdè Spanish.
Ibode Ibu-Omi Ṣí Silẹ
Nikẹhin, ni 1782 igbimọ-ìgbẹ́jọ́ Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀ paṣẹ pe Bibeli ni a lè tẹjade niwọn bi ó bá ti fi awọn àlàyé kukuru lori ìtàn ati ẹ̀kọ́ igbagbọ ṣọọṣi kun un. Ni 1790 biṣọọbu Katoliki ti Segovia, Felipe Scio de San Miguel, ni lilo Latin Vulgate, tumọ Bibeli kan si èdè Spanish. Laijasi bi o ti yẹ, ó wọ́nwó—1,300 reals (owó ẹyọ Spain igbaani) iye-owo akánilọ́wọ́kò kan ni ìgbà yẹn—awọn ọrọ rẹ̀ sì rújú, pupọpupọ to bẹẹ ti opitan ará Spain kan fi ṣapejuwe rẹ̀ bii “alaijasi bi o ti yẹ gbáà.”
Ni ọdun diẹ lẹhin naa, ọba Spain Fernando VII paṣẹ fun biṣọọbu ti Astorga, Félix Torres Amat, lati ṣe itumọ ti a mú sunwọn sii, ti a gbekari Latin Vulgate bakan naa. Itumọ yii jade ni 1823 ó sì ni ipinkiri gbigbooro ju itumọ ti Scio lọ. Bi o ti wu ki o ri, bí wọn kò ti gbé e kari Heberu ati Griki ipilẹṣẹ, ó ní iṣoro idiwọ deedee ti titumọ lati inu ohun ti a ti tumọ.
Laika itẹsiwaju yii si, ṣọọṣi ati awọn oluṣakoso orilẹ-ede naa ni a kò yileropada sibẹ pe Iwe Mimọ ni awọn eniyan lásán gbọdọ kà. Nigba ti George Borrow, aṣoju Ẹgbẹ́ Awujọ Bibeli Britain ati Ti Ìdálẹ̀, beere fun iyọnda ni awọn ọdun 1830 lati tẹ Bibeli ni Spain, a sọ fun un nipasẹ minista ijọba Mendizábal pe: “Ọgbẹni mi àtàtà, kì í ṣe Bibeli ni a ń fẹ́, ṣugbọn ìbọn ati ẹ̀tù, lati fi bá awọn ọlọtọ kanlẹ, ati leke gbogbo rẹ̀, owó, ki a baa lè sanwo fun ọ̀wọ́ awọn ọmọ ogun.” Borrow ń baa lọ lati tumọ Ihinrere ti Luku si èdè awọn Gypsy ará Spain, ati ni 1837 a fi í sẹwọn fun awọn isapa rẹ̀!
Nikẹhin, ìgbì naa ni a kò lè dá duro mọ́. Ni 1944 ṣọọṣi Spain tẹ itumọ Iwe Mimọ rẹ̀ akọkọ ti a gbekari awọn èdè ipilẹṣẹ—ni iwọn ọdun 375 lẹhin itumọ ti Casiodoro de Reina. Eyi ni itumọ ti awọn ọmọwe Katoliki, Nácar ati Colunga. Eyi ni itumọ Bover ati Cantera tẹle ni 1947. Lati ìgbà naa wá àkúnya awọn itumọ Bibeli lede Spain ni wọn ti wà.
Iṣẹgun Ti A Mudaniloju
Bi o tilẹ jẹ pe Bibeli lede Spanish nilati jijakadi lati là á já fun ọpọ ọrundun, ija-ogun naa ni a bori ni ikẹhin. Irubọ ńlá ti awọn olutumọ onigboya bii Reina ni ó daju pe kò jasi asán. Ẹni meloo ti ó ra Bibeli lonii ni o duro ti ó sì ronu nipa akoko ti a ka níní Bibeli ni ìkáwọ́ léèwọ̀?
Lonii, Bibeli ni iwe ti ó tà julọ ni Spain ati ni awọn orilẹ-ede ti ń sọ èdè Spain, ọpọlọpọ itumọ ni wọn sì wà larọọwọto. Awọn ti iwọnyi ní ninu ni Versión Moderna (Ẹ̀dà Itumọ Ode-oni, 1893), eyi ti o lo orukọ Ọlọrun, Jehová, lọna ti ó ṣe deede délẹ̀; ẹ̀dà Itẹjade Bibeli ti Pauline (1964), eyi ti o lo orukọ naa Yavé ninu Iwe Mimọ lede Heberu; Nueva Biblia Española (Bibeli Titun Lede Spanish, 1975), eyi ti ó jẹ́ pe laija si bi o ti yẹ kò lo yala Jehová tabi Yavé; ati Traducción del Nuevo Mundo (Itumọ Ayé Titun, 1967), ti a tẹjade lati ọwọ Watch Tower Society, eyi ti o lo Jehová.
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣebẹwo sinu ile araadọta-ọkẹ awọn eniyan ti ń sọ èdè Spanish lọsọọsẹ ki wọn baa lè ràn wọn lọwọ lati mọriri iniyelori Bibeli Mimọ—iwe kan ti o yẹ ni kíkú fún, iwe kan ti o yẹ ni gbígbé ni ibamu pẹlu rẹ̀. Niti tootọ, ìtàn ija-ogun Bibeli ledee Spanish lati là á já jẹ́ ẹ̀rí kan siwaju sii pe “ọrọ Ọlọrun wa yoo duro laelae.”—Isaiah 40:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni akoko yẹn kò sí iwe yoowu ti a lè kó wọle laisi iwe aṣẹ akanṣe, kò sì sí olutọju ibi ikoweesi eyikeyii ti ó lè tú ẹrù awọn iwe ti a kó ranṣẹ laisi ifọwọsi tí Ọfisi Mimọ naa (Àjọ Ìwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀) faṣẹ si.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Iwe Bibeli Complutensian Polyglott ni a ti tún mujade ó sì lè tipa bayii di eyi ti a fi tirọruntirọrun ṣayẹwo. (Wo oju-ewe 8)
[Credit Line]
Nipasẹ ifọwọsowọpọ ọlọlawọ ti Biblioteca Nacional, Madrid, Spain