Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 6
Orin 37
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 7-10
No. 1: Ẹ́kísódù 9:1-19
No. 2: Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù (lr orí 13)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé Gálátíà 6:2 àti Gálátíà 6:5 Kò Ta Kora?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 52
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bó O Ṣe Lè Fúnni Ní Ẹ̀rí Tó Yè Kooro. Àsọyé tó ń tani jí àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 255 sí 257.
20 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? Kí alàgbà kan jíròrò ìwé àṣàrò kúkúrú náà pẹ̀lú àwùjọ. Gbóríyìn fáwọn ọ̀dọ́ tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì ń sapá láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún látìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́. ‘Kí ló mú kó o ṣe ìpinnu yìí? Àwọn ìbùkún wo lo sì ti rí látibẹ̀?’
Orin 72