Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé olójú ìwé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà tó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1992.
◼ Ẹ tètè máa fún àwọn akéde láwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde gbàrà tó bá ti tẹ̀ yín lọ́wọ́. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè dojúlùmọ̀ àwọn ìwé ìròyìn ọ̀hún kí wọ́n tó lò wọ́n lóde ẹ̀rí.