Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọ̀gá ìkórè, ń bá a nìṣó láti máa dáhùn àdúrà tá à ń gbà pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i sínú pápá ní Nàìjíríà. (Mát. 9:37, 38) A rí èyí látinú iye àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé tó ròyìn lóṣù October 2008. Iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé ọ̀rìn dín nírínwó ó dín méjì [28,318]. Iye yìí fi nn‵kan bí ìdá méwàá nínú ọgọ́rùn-ún ju àwọn tó ròyìn lóṣù October ọdún 2007 lọ. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí rẹ, ńjẹ́ ẹnì kan lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nínú ìdílé yín?