Bíbélì Máa Ń Mú Kí Ayé Ẹni Dára
Bíbélì ti yí ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn pa dà sí rere. Àwọn ìlànà wo nínú Bíbélì la lè fi sílò, tó máa jẹ́ ká lè borí àwọn ìṣòro òde òní? Ó dájú pé inú rẹ máa dùn láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, tó o bá wo fídíò tó dá lórí bí Bíbélì ṣe ń mú kí ayé ẹni dára , ìyẹn The Bible—Its Power in Your Life. Fídíò yìí ni èkejì lórí àwo DVD tá a pe àkọlé rẹ̀ ní The Bible—A Book of Fact and Prophecy. Ṣé wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lẹ́yìn tó o bá wo fídíò náà?
(1) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Bíbélì kì í kàn ṣe ìwé àròkọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀? (Héb. 4:12) (2) Bó bá jẹ́ pé Bíbélì lè mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dára sí i, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ìṣòro fi ń bá aráyé fínra? (3) Kókó pàtàkì wo ni Bíbélì dá lé? (4) Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo la tọ́ka sí nínú fídíò náà tó lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè (a) mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn túbọ̀ dán mọ́rán, kí wọ́n sì lè máa (b) ṣèkáwọ́ ìbínú wọn? (5) Báwo ni ojú tí àwa Kristẹni fi ń wo ìgbéyàwó ṣe ń mú kí ìgbésí ayé ìdílé sunwọ̀n sí i? (Éfé. 5:28, 29) (6) Báwo ni Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún àwọn òbí? (Máàkù 1:9-11) (7) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè máa mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùn mọ́ni? (8) Yàtọ̀ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí tún ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí àwọn òbí ṣe fún àwọn ọmọ wọn? (9) Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́, kí wọ́n lè kojú ìṣòro ìṣúnná owó? (10) Tá a bá fẹ́ dín ìṣòro ìlera kù, àwọn ìlànà Bíbélì wo la lè tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, lílo oògùn olóró, mímu ọtí àmujù àti ìdààmú ọkàn? (11) Àwọn ìlérí wo nínú Bíbélì ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀? (Jóòbù 33:25; Sm. 145:16) (12) Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i? (13) Báwo lo ṣe lè fi fídíò yìí ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?