Ẹẹ̀ Rí Agbára Tí Bíbélì Ní!
Báwo lá ṣe lè rí i? Nípa wíwo fídíò náà, The Bible—Its Power in Your Life (Agbára Tí Bíbélì Ní Lórí Ìgbésí Ayé Rẹ) Ó jẹ́ apá kẹta nínú ọ̀wọ́ kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí a pe àkọlé rẹ̀ ní The Bible—A Book of Fact and Prophecy.
Ṣé o fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ kẹ́sẹ járí? Ǹjẹ́ o nílò ìrànwọ́ láti kojú àwọn àkókò líle koko? Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè dàgbà dẹni tó ní láárí? Bíbélì lè ṣèrànwọ́ gẹ́gẹ́ bí fídíò yìí ṣe fi hàn. Wá gbọ́ àwọn èèyàn tí ń ròyìn ipa rere tí Bíbélì ti ní lórí ìgbésí ayé wọn. Jẹ́ kí wọ́n ṣàlàyé fún ọ bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro òde òní.
Fídíò yìí jẹ́ irinṣẹ́ tó wúlò gidigidi fún ríran àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ láti rí àwọn àǹfààní tó wà nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà ní ìgbésí ayé wọn. Society ní fídíò The Bible—Its Power in Your Life lọ́wọ́. O lè béèrè fún ọ̀kan nípasẹ̀ ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ.